Chidinmma Adetshina yọwọ́ kúrò nínú ìdíje omidan arẹwà Miss South Africa 2024 torí awuyewuye lórí ìlú tí wọ́n ti bí i

Aworan Chidimma Adetshina

Oríṣun àwòrán, Chichi Vanessa/ Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Chidinmma Adetshina to n dije fun idije omidan to rẹwa julọ ni South Afrika fun ọdun 2024 ti yọwọ lawo idije naa bayii.

Chidinmma yọ ara rẹ kuro ninu idije naa, bi o tilẹ jẹ wi pe o wa lara awọn to wọ ipele aṣekagba idije naa ti yoo waye lọjọ Abamẹta.

Igbesẹ rẹ naa waye lẹyin ti ajọ to n mojuto ọrọ abẹle lorilẹede South Africa gbe abajade iwadi kan ti wọn ni awọn ṣe jade eyi to sọ pe ọna ẹburu ni iya rẹ gba ṣe eto iforukọsilẹ fun un lasiko ti wọn bii ati pe o ji orukọ ati idanimọ rẹ ni.

Oniruuru ibeere lo ti n jade si Chidinmma lati igba to ti jade lati kopa ninu idije omidan arẹwa naa, paapaajulọ nipa ọrọ ilu ibinibi rẹ.

Chidinma fi atẹjade kan si oju opo Instagram rẹ pe, “Mo ti gbe igbesẹ to nira yii lati yọwọ kuro ninu idije naa nitori abo ati alaafia emi ati ẹbi mi.”

Ninu atẹjade to kọ sita ni Ọjọ, ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2024, o ni irinajo to dara pupọ lo jẹ fun oun lati kopa ninu idije omidan arẹwa orilẹede South Africa fun ọdun 2024. O ni ọpọ lo duro ti oun nigba ti oun bẹrẹ irinajo naa amọṣa oun ni lati gbe igbesẹ lati kuro ninu idije ọhun.

O fi kun un pe eyikeyi awọn oludije to ku to ba bori yoo jẹ aṣoju rere fun awọn oludije gbogbo to kopa ninu idije naa.

Aworan atẹjade ti Chidimma fi sita loju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ki ni ajọ ọrọ abẹle lorilẹede South Africa sọ?

Chidinmma Adetshina wa lara awọn oludije mẹwaa to yẹ ko kopa ni aṣekagba idije naa ti yoo waye lọjọ Abamẹta niu Pretoria lorilẹede South Africa.gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ to n ṣe kokari ọrọ ablẹle lorilẹede naa fi sita, lọjọ Aje, ọjọ karun un oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni awọn to gbe idije naa kalẹ kọwe ranṣẹ si ajọ naa lati bawọn ṣe ayẹwọ ibinibi kan lara awọn oludije naa ti orukọ rẹ n jẹ Chidimma Adetshina.

Wọn ni iya oludije naa pẹlu fi ọwọ si ayẹwo naa.

Nigba ti ajọ naa yoo fi jade pẹlu ipele akọkọ iwadii rẹ, ohun ti wọn sọ niwọnyii:

Idi to jinlẹ wa lati sọ pe ọna ẹburu ni ẹni ti wọn kọ silẹ gẹgẹ bi iya Chidimma Adetshina gba ṣe eto iforukọsilẹ fun un lasiko ti wọn bii ati pe o ji orukọ ati idanimọ rẹ ni.

Aworan Chidimma Adetshina

Oríṣun àwòrán, Chichi Vanessa/ Instagram

Adetshina ko lọwọ ninu iwa aibofinmu iya rẹ nitori pe majesin ṣi ni nigba ti iwa naa waye lọdun 2001;

Obinrin ara South Africa kan ti wọn ji idanimọ rẹ lo ninu iwa jibiti ti iya Chidimma Adetshina hu naa, padanu lọpọlọpọ nitori pe oun gan paapaa ko le ṣeto ifokusilẹ fun ọmọ tirẹ;

Ajọ naa ti wa fẹ iwadii rẹ loju sii lati le fi awọn oṣiṣẹ ajọ naa to ba lọwọninu iṣẹlẹ ọhun jofin, wọn si ti n beere fun amọran ofin nipa ipa ti iṣẹlẹ naa le ni lori ilana ijọmọonilu Adetshina.

Lẹyin ti iwadii ba parii, ajọ naa yoo pe awọn ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori lẹjọ.

Iya Chidimma Adetshina ati idile rẹ ko tii sọ ohunkohun lori abajade iwadii ajọ ọrọ abẹle orilẹede South Africa naa.