Wo ìdí tí ọmọ Naijiria yìí ṣe gba ife ẹ̀yẹ Olympic fún ilẹ̀ Amẹrika dípò Naijiria

Annette Echikunwoke with an American flag

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Nigba ti Annette Echikunwoke gbe asia orilẹede Amẹrika leke ninu idije Olympics lẹyin to gba ife ẹyẹ idẹ tan, inu ọpọ eeyan lo dun si.

Amọ fun awọn to n wo idije naa ni Naijiria, inu ọpọ eeyan lo bajẹ.

Lọwọ yii, Naijiria ko tii gba ife ẹyẹ kankan ninu idije naa, aṣeyọri Annette Echikunwoke yii lo si yẹ ko jẹ ti Naijiria bi kii ba ṣe aṣiṣẹ ajọ Athletics Federation of Nigeria (AFN).

Kaka ko gba ife ẹyẹ naa fun Naijiria, Amẹrika ni ẹni ọdun mejidinlọgbọn ọhun gba ife ẹyẹ naa fun.

O ni “Inu mi dun fun iriri mi ninu idije Olympics yii to waye ni Paris ti mo si gba ami ẹyẹ.

“Latari pe mo wa pẹlu Amẹrika, wọn tọju mi daadaa, mo si ṣiṣẹ takuntakun lati gba ife ẹyẹ ọhun.”

Amọ ibere to wa nibẹ ni pe bawo ni Naijiria ṣe padanu ife ẹyẹ to yẹ ko gba yii?

Iṣẹlẹ to waye ni Tokyo 2020

Echikunwoke, ti wọn bi ni Ohio, nilẹ Amẹrika ni iwe ẹri gẹgẹ bii ọmọ ilẹ Amẹrika ati Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2020, orilẹede Naijiria lo mura lati ṣoju fun ninu idije Tokyo 2020.

Oun lo pegede julọ lasiko ti wọn n mura fun idije naa lọdun naa lọhun to jẹ igba akọkọ rẹ si Naijiria, amọ nigba ti yoo fi balẹ siluu Tokyo, ni Japan, wọn ni ko ni le kopa.

Wọn fofin de oun atawọn ọmọ Naijiria mẹwaa mii latari pe o yẹ ki wọn ṣayẹwo oogun oloro ṣaaju idije ọhun, eyii ti wọn ko ṣe.

Echikunwoke sọ pe “lọjọ ti mo pe ẹni ọdun marundinlọgbọn, wọn sọ fun mi pe mi o ni le dije ni Tokyo latari aibikita orilẹede ti mo fẹ dije fun.

“Inu mi bajẹ gidi.. o jẹ igba ti inu mi bajẹ julọ.”

Ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ni pe ajọ AFN kuna lati ṣayẹwo lilo oogun oloro fun nigba mẹta ọtọtọ, eyii to jẹ ara awọn amuyẹ igbaradi fun idije naa.

Echikunwoke ṣalaye pe oun sọ fun AFN ibi ti wọn ti le ri oun nilẹ Amẹrika fun ayẹwo naa amọ AFN kuna lati kan si oun bo tilẹ jẹ pe igba mẹfa ọtọtọ loun kan si ajọ ọhun lati wa ṣe ayẹwo oun.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ṣayẹwo awọn oludije kan lati ilẹ alawọ dudu fun idije naa, ajọ World Anti-Doping Agency sọ pe awọn ayẹwo naa ko ṣe itẹwọgba.

Lẹyinorẹyin, iṣẹlẹ naa wọgile anfani Echikunwoke lati dije fun Naijiria bo tilẹ jẹ pe afojusun rẹ ni lati ṣe bẹẹ.

Igbesẹ lati fije fun ilẹ Amẹrika

Annette Echikunwoke prepares to release the hammer during the Paris 2024 competition

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ijakulẹ yii, o gbe igbesẹ lati dije lorukọ ilẹ Amẹrika ti wọn bi si.

Ọdun 2022 lo kọkọ dije lorukọ ilẹ Amẹrika nibi ti to gbe ipo kejila ni aṣekagba idije Wold Championships ni Eugene.

Ninu idije ‘2024 US Olympic trials’ to jẹ igbaradi fun idije 2024 Olympics, oun lo gbegba oroke.

Lẹyin awọn aṣeyọri naa, o kuku tẹba ti ilẹ Amẹrika.

Amọ o ṣeni laanu pe awọn asẹyọri Echikunwoke ọhun ko tu irun kankan lara awọn alakoso ere idaraya ni Naijiria.

Nigba ti BBC kan si ijọba Naijiria lori ọrọ ọdọbinrin naa, agbenusọ ajọ ere idaraya sọ fun wa pe “awọn to n dije lorukọ wa la n bojuto lọwọ yii, kii ṣe awọn to ti lọ dije lorukọ orilẹede mii.”

Ajọ AFN si kọ lati sọrọ lori aṣeyọri obinrin naa lẹyin to gba ife ẹyẹ idẹ fun Amẹrika tan.

Oju ti awọn ọmọ Naijiria fi wo aṣeyọri Echikunwoke

USA's Annette Echikunwoke (L), gold medallist Canada's Camryn Rogers (C) and bronze medallist China's Zhao Jie pose as they celebrate on the podium during the victory ceremony for the women's hammer throw athletics event during the Paris 2024 Olympic Games

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo tilẹ pe ọpọ eeyan ni Naijiria lo ti bẹrẹ si n ki ọdọbinrin naa ku oriire, pupọ ninu wọn lo n bnu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria.

Lara awọn nnkan ti wọn n sọ ni pe ijọba Naijiria ko bikitia fun ọjọ ọla awọn ọdọ, ati pe o san ki Echikunwoke dije lorukọ Amẹrika ju Naijiria lọ.

Wayi o, ọpọ awon ọmọ Naijiria lo ṣi ni ireti pe awọn to lọ ṣoju orilẹede wọn ko ni pada wale lọwọ ofo.