Ilé ẹ̀kọ́ kan rèé l’Osun tí ọ̀pọ̀ yàrá ìkẹ̀kọ̀ọ́ rẹ̀ ti di àlàpà tó sì tún pààlá pẹ̀lú ibi ìsìnkú
Ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ree niluu Ilesa nipinlẹ Osun nibi ti atẹkun ti ṣi orule yara igbẹkọ ti ọpọ yara igbẹkọ si ti di ogiri alapa.
Arabinrin Mary Foluke Ajijola to jẹ ọga ile ẹkọ alakọbẹrẹ ijọ Methodist lagbegbe Oke Ese niluu Ilesa sọ fun BBC Yoruba wi pe bi oun ṣe ba ile ẹkọ naa nigba toun de ibẹ ko tẹ oun lọrun.
Arabinrin Ajijola sọ pe ‘’ni gbogbo ile ẹkọ yii, ko si nnkan igbẹkọ.
A o ni iyara igbẹkọ to bojumu ti awọn ọmọ le duro si.
Gbogbo iyara igbẹkọ lo ti di ogiri alapa tan. Ko si ferese, ko si ilẹkun, bakan naa ni afẹfẹ ti gbe gbogbo orule naa lọ.
Wọn tiẹ ti sin oku de ẹgbẹ ile ẹkọ gan an, ko si iyatọ laarin ile ẹkọ ati itẹ isinku.
Awọn akẹkọọ gan an ki lee duro sile ẹkọ tori ẹru maa n bawọn pẹlu bi wọn ti sin oku de ẹgbẹ ile ẹkọ naa.’’
Aṣoju ijọ Methodist, Alufaa Ajayi Oludare, sọ pe o jẹ ọkan ninu awọn nnkan ti ijọ naa n jiroro le lori ninu ipade wọn.
Alufaa Oludare ni ijọ Methodist ti n gbero lati mọ odi yi awọn ibi isinku to wa lẹgbẹ ile ẹkọ naa ka ki ọkan awọn akẹkọọ le balẹ.
Ọkan lara awọn obi awọn akẹkọọ, Arabinrin Funmilayo Olaifa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn akẹkọọ pọ tẹlẹ nile ẹkọ naa, amọ o sọ pe ọmọ o pọ bii ti tẹlẹ mọ.
Olalere Victoria to jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ to ti jade nile ẹkọ naa sọ pe ile ẹkọ naa dara pupọ lasiko toun atawọn akẹgbẹ oun fi wa nibẹ.
Ṣugbọn o kọminu lori bi ile ẹkọ naa ṣe da bayii.
Alaga ẹgbẹ obi ati olukọ, Ọgbẹni Stephen Audu sọ pe awọn obi maa n dawo jọ tẹlẹ lati ṣe atunṣe awọn iyara igbẹkọ ti atẹkun ba ti gbe.
Ọgbẹni Audu ṣalaye pe nigba ti ijọba kan de nipinlẹ Osun eyi to ni kawọn obi ma dawo mọ lawọn obi ko le ṣe nnkan kan mọ.
Ọga ile ẹkọ naa wa kepe ijọba lati ṣe iranwọ pẹlu atunṣe ile ẹkọ yii ki awọn le baa pọ si nibẹ.
Alaga ajọ SUBEB to n ri si ọrọ eto ẹkọ kari-aye nipinlẹ Osun, Fadipe Ibukun Isola, sọ pe agbegbe ti ile ẹkọ yii wa ni oun gan an gbe dagba niluu Ilesa.
Alaga SUBEB ni ajọ naa ni ilana ati ofin pẹlu gbogbo nnkan tawọn n ṣe.
O ni ajọ SUBEB yoo kọ iyara igbẹkọ si ile ẹkọ Methodist yii loṣu Kẹwaa to n bọ, ati pe ajọ naa yoo tun kan aga fawọn akẹkọọ nibẹ.
Ọgbẹni Isola ni iyatọ gidi yoo ba ile ẹkọ yii titi oṣu kọkanla si oṣu kejila ọdun 2024 yii.
Alaga SUBEB ni oun gbagbọ pe ijọba ipinlẹ Osun naa yoo ṣe nnkan lori ile ẹkọ yii laipẹ.






