Kí ló fàá tí Mpox ń tàn káàkiri ìlà-oòrùn àti àárín gbùngbùn Áfríkà?

Aworan ọwọ eeyan to ni Mpox,

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Makuochi Okafor & Chigozie Ohaka
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Lagos, Nigeria
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orilẹede Democratic Republic of Congo (DRC) n rii ilosoke aarun Mpox, eyi to n fa awọn igbese ilera to jẹ oni kiakia ti ijọba n gbe lati dena itankalẹ aarun naa.

Awọn agbegbe kan ti wa lara awọn ibi ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii awọn ibi to lewu pupọ, ti wọn si gbe igbesẹ lati pese aabo fun awọn eeyan to wa ni agbegbe naa.

Orilẹede Uganda ti fidi iṣẹlẹ aarun meji to jẹ ti Mpox mulẹ, to si darapọ mọ Kenya, Rwanda, ati Burundi to jẹ orilẹede ti aarun yii ti n ja ni Ila-oorun Afirika.

Gẹgẹ bi Afrika CDC ṣe ṣalaye, iye iṣẹlẹ aarun Mpox ti lekun si, ti ọpọ eeyan si ti padanu ẹmi wọn ju ti ọdun to kọja.

Ajọ Afirika CDC ti fọwọsi owo to to $10.4m lati inu owo Covid ti wọn ya sọtọ lati ṣe atilẹyin fun CDC Afirika lati fi koju aarun Mpox kaakiri ilẹ adulawọ.

Pupọ ninu awọn iṣẹlẹ to ti waye ni o waye ni orilẹede Democratic Republic of Congo.

Ni ọdun yii nikan, o le ni eeyan 8,000 to ti lugbadi aarun naa, ti eeyan 300 si padanu ẹmi wọn.

Dokita Fiona Braka, Oluṣakoso idahun Pajawiri ti ajo ilera agbaye ni Congo Brazzaville, sọ pe “orilẹede mọkanla ni iroyin ti gbe sita pe wọn ti lugbadi aarun naa lati ibẹrẹ ọdun 2024.”

“A n ri itankalẹ nla lọwọ yii ni DRC ti o jẹ ida 96% ninu gbogbo awọn aarun ti a ti rii.”

Meji ninu awọn aarun naa to jẹ eyi to ni agbara ni wọn sẹsẹ ri laipẹ yii ni Rwanda ati CAR, lẹyin ọjọ diẹ ti Burundi tun kede nipa awọn aarun ọhun.

Laipẹ yii naa, Kenya kede pe aarun naa ti de si ọdọ oun.

South Africa naa kede pe aarun naa ti de si ọdọ oun, ti eyan mẹta si ti padanu ẹmi wọn.

Awọn onimọ nipa ilera sọ pe aarun na wọnpọ laarin awọn eeyan to n sisẹ ibalopọ.

Aarun wo ni Mpox?

Mpox, ti a mọ si igboona lo jẹ aarun to ni agbara lati fa ọpọ ewu si aago ara ọmọ eeyan.

Aarun maa n mu awọn aisan bii iba, ori fifo, ara riro dani.

Eeyan ko le ko aisan naa nipasẹ fifi ara kan ẹni to ni aisan naa lara gẹgẹ bi awọn amoye se ṣalaye.

Aworan Dokita Kitwanda

Oríṣun àwòrán, Steeven Kitwanda

Ki ni ọna abayọ?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Steeven Kitwanda

Awọn igbese ilera gbogbogbo bi ibaraẹnisọrọ, ayẹwo, itọju, wiwa orisun, ati biba awọn eeyan sọrọ lori bi wọn se le dena de aarun Mpox ni awọn onimọ ilera ti la kalẹ.

Leandre Murhula Masirika, oluṣakoso iwadii MPox ni DRC, sọ pe ṣiṣe ayẹwo ni ẹnu ibode jẹ ọkan ninu ọna lati to koju aarun naa.

Alakoso iwadii sọ pe ilanilọyẹ nipa aarun naa ati pipese idanilẹkọ le dena itankalẹ rẹ.

Awọn alaboyun ati ọmọde ti aarun yii n koju si julọ.

Ni DRC, ọpọlọpọ awọn ọmọde, pẹlu awọn ọmọ tuntun, ni wọn ti ko aarun naa, ti awọn alaboyun kan si ti padanu ẹmi wọn.