Èyin ọmọ Nàìjíríà tí ẹ fẹ́ lọ sí UK lásìkò yìí ẹ ṣọ́ra o torí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, ìjọba Tinubu kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kilọ fun awọn eeyan to ba fẹẹ lọ si orilẹede UK lati Naijiria lasiko yii lati ṣọra, nitori rogbodiyan to bẹ silẹ lẹyin iku awọn ọdọbinrin mẹta kan.
Atẹjade ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ abele ni Naijiria, fi sita lọjọ Aje, ọjọ karun-un oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, ti aṣoju wọn, Ambasado Eche Abu-Obe, fọwọ si, kilọ pe rogbodiyan to bẹ silẹ naa ti gba ọna to buru yọ.
Wọn fi kun un pe bi ẹnikẹni yoo ba lọ si UK lasiko yii lati Naijiria, kẹni naa ri i pe oun yago fun iwọde, apejọ elero pupọ, ki wọn si maa ṣọra gidi nibikibi ti wọn ba wa.
Tẹ o ba gbagbe, lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni awọn kan ti n fi ẹhonu han lawọn ibi kan lorilẹede UK.
Awọn eeyan naa ti wọn gbagbọ ninu ilana atijọ ni UK, ni wọn kọkọ bẹrẹ iwọde to mu rogbodiyan dani, ko too di pe iku awọn ọdọbinrin mẹta naa wọ ọ, to si sọ wahala naa di nla si i.
Bawọn kan ṣe n sọ pe ajoji to gba ọna ẹburu wọ orilẹede UK ni awọn ọmọ naa, bẹẹ lawọn kan n sọ pe awọn ẹlẹsin Islam to wa niluu naa ni wọn da oju sọ, awọn mi-in si sọ pe awọn ti ki i ṣe alawọ funfun ni wọn n doju ija naa kọ.
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja, awọn eeyan kan ti wọn tako ẹsin Islam, wọde lapa Ariwa ilu naa, o si di ija laarin wọn ati awọn ọlọpaa.
Awọn ọmọbinrin mẹta ni wọn gun pa ninu ikọlu yii.
Lọjọ Aje, ọmọde marun-un mi-in farapa yanna-yanna nibi ikọlu to waye.
Bakan naa ni ikọlu to waye ni Southport, agbegbe etikun kan to maa n dakẹ rọrọ ṣi n ya gbogbo ilu naa lẹnu bayii, ṣugbọn awọn ọlọpaa ti ni awọn ko mọ nnkan kan nipa rẹ.
Yatọ si Naijiria to n kilọ fun awọn eeyan rẹ, awọn orilẹede mi-in ti wọn tun ti kede ikilọ tiwọn ni: Malaysia, Indonesia, United Arab Emirates, Australia. Pupọ ninu ilu yii lo jẹ pe ẹlẹsin Islam lo pọ ju nibẹ.
Wo àwọn agbegbe ti rogbodiyan ti n bẹ silẹ ni UK
O ti le ni agbegbe mejila ti rogbodiyan naa ti bẹ silẹ, diẹ lara wọn ni: London, Liverpool, Manchester, Bristol, ati Sunderland.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn oluwọde kan bẹrẹ si i doju ija kọ awọn mọṣalaaṣi lagbegbe yii.













