Wo ọmọ ilẹ̀ Afrika àkọ́kọ́ tí yóò gba góòlù ní ẹ̀ka àwọn obìnrin nínú ìdíje Olympics 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kaylia Nemour lo ti gbe ogo orileede Algeria ga lasiko yiiii, nibi idije Olympic 2024 to n lọ lọwọ ni Paris.
Nemour ni ọmọ ilẹ Afrika akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ goolu ni ti ẹka awọn obinrin ninu idije are lilo ẹya ara ti a mọ si gymnastics.
Ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa la gbọ pe o ti tayọ kọja afẹnusọ pẹlu aami ayo 15.700 lati ọdọ awọn onidajọ pẹlu bo ṣe jafafa, to si ṣe are naa lọna iwuri.
"O ba mi lẹru, ala ti mo ti n reti tipẹ ni igbesi aye mi ree. Mi o nigbagbọ pe o le wa si imuṣẹ bayii, mi o mọ ohun ti mo fẹẹ sọ," wọnyi lohun ti Nemour sọ.
Aṣeyọri Nemour yii lo tun jẹ igba kẹfa ti orileede Algeria yoo gba ife ẹyẹ goolu latigba ti wọn ti bẹrẹ idije yii niluu Tokyo lọdun 1964.
Ilẹ North African ni wọn gba ife ẹyẹ yii gbẹyin lọdun 2012 nigba ti Taoufik Makhloufi yege ni ẹka awọn ọkunrin pẹlu 1500m.
Lọdun to kọja, Nemour, ọmọ bibi ilu Saint-Benoit-la-Foret, lorileede France lo jẹ ọmọ ilẹ Afrika akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ agbaye ninu are gymnastics to kopa ninu ẹ ni Antwerp.
O si tun ti wa ṣe daradara ju ti tẹlẹ lọ ni gbagede Bercy Arena lọjọ Aiku to kọja pẹlu bi ọmọ ilẹ China nni, Qiu Qiyuan toun n di ipo akọkọ mu lagbaye ṣe ṣe ipo keji.
Ami ẹyẹ Olympic akọkọ fun Cape Verde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aami ayo 15.500 ni Qiyuan ni, nigba ti Sunisa Lee toun wa lati ilẹ Amẹrika ṣe ipo kẹta.
"Ni ipele lati yege, mo ni 15.600", Nemour lo sọ bẹẹ.
"Nigba ti mo rii pe Qiu ni 15.500, mo nilo lati ṣiṣẹ takuntakun sii, ki n si fi gbogbo agbara mi ja fitafita lati le ṣe daadaa.
"Iwuri nla lo jẹ fun mi lati gba aami ẹyẹ yii pẹlu gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin, ọkan mi balẹ bayii."
Nina Derwael, ọmọ ilẹ Belgium to jẹ ẹni to wa ni ipo akọkọ tẹlẹ ninu idije Olympic lo pari pẹlu ipo kẹrin.
Nemour, lo dide lati ṣoju orileede abinibi baba rẹ, lọdun to kọja ni aawọ waye laarin oun ati awọn alakoso are idaraya gymnastics orileede France lẹyin to fi ẹsẹ ṣeṣe.















