Ọmọ Nàìjíríà, ẹ máa retí irè oko rẹpẹtẹ láìpẹ́ - Mínísítà ètò ọ̀gbìn ṣàlàyé

Aworan oja oko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fọrọ eto iṣẹ agbẹ ati aabo lori ounjẹ lorileede Naijiria, Abubakar Kyari ti sọ fawọn ọmọ Naijiria lati maa reti ire oko lọpọ yanturu ki ọdun yii to o pari.

Owo ounjẹ lo ti lọ soke si ida ogoji, gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ National Bureau of Statistics (NBS), eyi to sun owo ọja soke kọja ohun ti agbara ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Naijiria le ka.

Kyari jẹ ko di mimọ pe ijọba apapọ ti ni eto nilẹ lati yanju iṣoro ounjẹ to wa nilẹ, lara eyi ti iranwọ iṣẹ agbẹ wa ninu rẹ lati mu ki idagbasoke de ba ounjẹ ti wọn n ṣe jade.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ikore lọpọ yanturu yoo waye laarin oṣu kẹwaa si oṣu kọkanla, ọdun ti a wa yii. Igba naa la maa ko awọn ire oko. A n reti ikore rẹpẹtẹ ti yoo fopin si oniruuru iṣoro.”

Ori eto ‘Sunday Politics’ ti ileeṣẹ amohunmaworan Channel ni Kyari ti sọrọ yii lọjọ Aiku to kọja.

Kyari tẹsiwaju pe “mo kan jẹ ki ẹ mọ nipa idaniloju pe a maa ni ikore yanturu.”

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe lara awọn ohun to fa aisi ounjẹ lorileede Naijiria lasiko yii ni awọn idi pataki to nii ṣe pẹlu asiko.

“Asiko ti a ni nibi jẹ iṣoro pataki to n koju iṣẹ agbẹ. Eyi ni a n pe ni asiko riru, ati pe eyi maa n waye laarin oṣu kẹfa si oṣu keje, igba to kan lẹyin eyi ni ikore.”

Yatọ si eyi, Minisita Kyari tun sọ pe lara awọn ohun to tun fa iṣoro ni yi adinku ilẹ, omiyale ati awọn miran.

“Bi ko ṣe si ilẹ mọ fun oko dida, omiyale ati agbara, agbegbe ati aisi eti aabo lo fa iṣoro. Awọn arugbo ni wọn n da oko bayii, awọn ọdọ ko fẹẹ da oko mọ, bẹẹ si ni wọn ko fẹ ya sidi iṣẹ agbẹ mọ.”

O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba tun ti n gbe igbesẹ lati wọnu eto agbẹ igbalode nipa pinpin ajilẹ fun awọn agbẹ ati lati ra awọn katakata.

“A ti pe lati ra katakata. Ko dabi ipapanu; ko ṣee sare ra. Mo lọ si orileede Belarus lati ra katakata ti ko din ni igba ati awọn irinṣẹ mmiran.

“Irinṣẹ to ṣe koko fun iṣẹ agbẹ ni Naijiria ni ọkọ, idi ree ti a fi n sọ nipa igbalode.”