Èyin alága ìjọba ìbílẹ̀ Oyo tí ẹ tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ torí Makinde, ẹ má jẹ́ kí gómìnà ran yín lẹ́wọ̀n - APC

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Tó bá wu àwón alága ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Oyo kí wọ́n dá ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ sílẹ̀, wọn ò lè yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ padà

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Lori awuywuye ibi to yẹ ki ijọba apapọ maa san owo idagbasoke ijọba ibilẹ si to n ja rainrain nipinlẹ Oyo, agbẹjọro kan ti sọ pe o lodi si ofin ki ijọba Oyo tako idajọ ile ẹjọ.
Nigba to n gba BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ naa, Monday Ubani (SAN) sọ pe ko si ohun ti ijọba Oyo tabi awọn alaga ijọba ibilẹ rẹ le ṣe lẹyin idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naiiria.
O ni lati nnkan bii ọgbọn ọdun o le ti oun ti ṣiṣẹ agbẹjọro, oun ko tii gbọ ri pe ijọba ipinlẹ tabi ibilẹ kankan gbena woju idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lai ki ṣe pe wọn pe ẹjọ kotẹmilọrun.
Ubani sọ pe “o jẹ apẹrẹ to lewu gidi nigba ti ijọba ibilẹ ba sọ pe oun kop ni tẹle idajọ ile ẹjọ.
“Nitori, nigba ti adajọ agba patapata niluu ba gba ile ẹjọ lọ, to si gba idajọ ti ẹnikẹni ko pe ẹjọ mii takoo, ti awọn alaga ijọba ibilẹ wa sọ pe awọn ko faramọ idajọ naa ẹ o ri pe alaimọkan ni awọn alaga bẹẹ, wọn ko si ni ironu.
“Ṣe wọn fẹ sọ pe awọn kii ṣe ara orilẹede yii mọ ni nitori itumọ ohun ti wọn n ṣe niyẹn.
“Ti wọn ba sọ pe awọn ko ni tẹle aṣẹ ile ẹjọ, o n tumọ si pe wọn ni orilẹdẹ mii to jẹ tiwọn.
Agbẹjọro agba naa sọ siwaju si pe oloṣelu to ba kọ aṣẹ ile ẹjọ ti n lu ilu ogun si Naijiria, kii si i ṣe ohun to tọna.
Lori rẹ pe awọn alaga naa fẹ fi ẹgbẹ ALGON silẹ, Ubani sọ pe iyẹn ko difa.
O ni “To ba wu wọn ki wọn fi ALGON silẹ ki wọn lọ da ẹgbẹrun ẹgbẹ mii silẹ, igbesẹ wọn ko le yi idajọ ile ẹjọ pada.
Àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, wọ́n ní kí owó àwọn wà lápò ìjọba ìpínlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun ko faramọ idajọ ile ẹjọ giga kan to paṣẹ pe ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ ko gbọdọ maa lo apo iṣuna kan naa mọ.
Ṣaaju ni gomina Seyi Makinde ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu idajọ ọhun, to si sọ pe kii ṣe ijọba apapọ ni yoo maa la le awọn ipinlẹ lọwọ lori bi wọn ṣe maa na owo wọn.
Eyi lo n waye lẹyin ti adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN) pe ẹjọ lori ọrọ ọhun lọna ati fun awọn alaga ijọba ibilẹ lominira lati maa na owo wọn bo ba ṣe wu wọn.
Idajọ ile ẹjọ to ga julọ naa sọ pe ijọba ipinlẹ ko lagbara labẹ ofin lati maa ṣakoso owo ti ijọba ibilẹ yoo maa na fun atunṣe ilu.
O ni iwa naa ko ba ofin mu rara.
Wayi o, iroyin to n tẹ wa lọwọ ti sọ pe gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Oyo ti fẹ yapa kuro ninu ALGON, lọna ati ṣatilẹyin fun Makinde.
Ninu atẹjade kan ti adari awọn alaga ijọba ibilẹ Oyo, Sikiru Sanda fi lede, o ni gbogbo wọn fọwọ si ohun ti Makinde ba sọ ati igbesẹ to ba gbe lori ọrọ naa.
Eredi igbesẹ awọn alaga ọhun, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ni pe Makinde jẹ adari rere to fi apẹrẹ rere silẹ, o si ti ṣe ọpọ aṣeyọri lati igba to ti gori alefa gomina.
Awọn alaga naa tun ti fẹnuko lati da ẹgbẹ tuntun mii silẹ, eyii ti kii ṣe ara ALGON, lọna ati tẹsiwaju iṣẹ wọn ni sinsin araalu.















