Arsenal na Bayern Leverkusen 4-1

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbo ewuro soju Bayern Leverkusen pẹlu goolu mẹrin si ẹyọ kan ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti wọn gba lalẹ Ọjọru ni papa iṣire Emirates ni ilu London.
Zinchenko lo gba goolu akọkọ wọle fun Arsenal ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹjọ.
Lẹyin rẹ ni Trossard mi awọn nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de iṣẹju kẹsan an.
Atamatase Arsenal Gabriel Jesus pa oju rẹ de si mẹta ki wọn to pari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa.
Nigba ti saa keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, Havert mi awọn wo lẹyin ti akọnimọọgba Arsenal, Mikel Arteta ko awọn eekan agbabọọlu bi Saka wọle, to si ṣe eto goolu kẹrin fun Havertz lati gba a wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọṣa o, awọn agbabọọlu Bayern Leverkusen ati akọnimọọgba wọn Xavi Alonso naa o simi. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa si wọ iṣẹju karundinlọgọrin ni agbabọọlu wọn, Hlozek ja ọra oju awọn Arsenal lati mu ifẹsẹwọnsẹ naa wa si goolu mẹrin si ẹyọkan.
Agbabọọlu ọmọ Naijiria, Victor Boniface wọle fun ifẹsẹwọnsẹ naa nigba to wọ iṣẹju kẹtalelọgọta, amọṣa ko le ṣe ohunkohun lati doola ikọ rẹ.
Ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ ara ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti wọn fi ọ ori Emirate Cup. Arsenal, Lyon ati Bayer Leverkusen lo n kopa ninu idije naa.
Awọn agbabọọlu to kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbabọọlu to gba bọọlu fun Arsenal:
Raya, White, Saliba, Gabriel, Zinchenko, Jorginho, Havertz, Odegard, Viera, Trossard, Jesus
Awọn to wa ni ipo arọpo : Ramsdale, Setford, Heaven. Lewis-Skelly,Nichols,Partey,
Nelson, Nwaneri, Saka, martinelli, Nketiah
Awọn agbabọọlu to gba bọọlu Bayern 04 Leverkusen:
















