Kí ló fàá táwọn eléré ìdárayá kìí fí fẹ́ padà sí orílẹ́èdè abínibí wọn lẹ́yìn ìdíje lókè òkun?

Aworan Krystsina Tsimanouskaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Suneth Perera
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

"Ni idije Olympic ni Tokyo, Mo jẹ ọkan ninu ọmọ ẹgbẹ orilẹ-ede Belarus," Krystsina Tsimanouskaya sọ. "Ni bayii, ni idije Olympic ni Paris, Mo n ṣe aṣoju Poland."

Ni ọdun 2021, elere idaraya to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn di ilumọka lẹyin bẹrẹ fun aabo lẹyin ti iṣẹlẹ kan waye ni orilẹede rẹ, ti awọn Ọlọpaa n wa ni orilẹ-ede abinibi rẹ, ti ẹru si n ba.

Ni ọjọ Ọgbọnjọ Oṣu Keje ọdun 2021, Tsimanouskaya fi fidio kan sori Instagram nibi ti o ti n bu ẹnu atẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba Belarus fun fifi orukọ rẹ kun orukọ awọn elere idaraya to nsare 400m lia gba aṣẹ lẹnu rẹ.

Elere idaraya naa fihan pe wọn fi tipatipa mu oun lọ si papa ọkọ ofurufu Tokyo lati le fi ransẹ pada si Belarus, eyi to lodi si ifẹ ọkan rẹ lẹyin to gbe fọnran naa sita.

O ni oun ni lati kesi awọn ọlọpaa fun ni ebute lati ma le wọ inu ọkọ ofurufu lọ orilẹede Abinibi rẹ

Lẹyin iṣẹlẹ naa, awọn oṣiṣẹ Belarus sọ pe awọn ti yọ Timanovskaya kuro ni ẹgbẹ orilẹ-ede nitori ihuwasi rẹ ti ko dara eyi to ni ọrọ ko ri bẹ

Ni Oṣu Keji ọdun yii, olukọni Olympic ti Belarus Yury Moisevich ni wọn ni ko lọ rọkun nile fun ọdun marun un nitori ipa to ko bi Timanovskaya se n soju orilẹede ni airotẹlẹ.

Elere idaraya Olympic naa sọ pe wiwa ibi aabo jẹ ohun to nira fun pupọ nitori pe o tumọ si fifi idile ati awọn ọrẹ rẹ silẹ, to si le fa ewu opin si iṣẹ ere-idaraya rẹ - ṣugbọn o ni ko si ọna miiran.

Wiwa aabo

Aworan Krystsina Tsimanouskaya ni paapa ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Lori foonu, iya agba mi sọ fun mi lati ṣe ohunkohun ṣugbọn ki n ri pe mo pada wa si Belarus,” o sọ fun BBC.

"Ko ki n se pe o le fa opin iṣẹ mi nikan; o le fa ifi opin si igbesi aye deede nitori n ko mọ ohun ti o n le ma duro de mi rara."

Tsimanouskaya sọ pe, ṣaaju idije Olympic, o kopa ninu ifẹhonuhan to lodi si eto idibo 2020 to fa ariyanjiyan ni Belarus.

Lẹyin ti Aare Alexander Lukashenko, alabaṣepọ ti Russia, jawe olubori , ifẹhonuhan bẹ, ti ọgọọgọrun eeyan ti dero atimọle, paapa awọn ọrẹ Tsimanouskaya.

Tsimanouskaya sọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba Belarus ti mọ tẹlẹ nipa ilowosi ninu ifẹhonuhan ṣaaju idije Olympic.

“Nitorin eyi, Mo mọ atunbọtan ti n mo ba pada yoo le gan,” o sọ.

Tsimanouskaya kan si Igbimọ Olympic lagbaye (IOC) fun iranlọwọ lẹyin ti o kan si ọlọpaa ni papa ọkọ ofurufu Tokyo to si wa ibi aabo lọ si Poland.

Itan rẹ jẹ ọkan ninu ọpọlọpọ awọn itan ti awọn elere idaraya ti ko pada si awọn orilẹ-ede wọn lẹyin awọn iṣẹlẹ ere idaraya pataki to fa ẹru si aabo wọn.

Pipora fun igbeaye to dara

Aworan Julius Ssekitoleko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lasiko Olympic Tokyo 2020 (ti wọn sun siwaju si 2021 nitori ajakaye-arun Covid-19), Tsimanouskaya kii ṣe elere idaraya nikan to di ilumọka loju opo iwe iroyin.

Julius Ssekitoleko, ọmọ ilẹ Ugandan to n gbe irin naa saa kuro lasiko igbaradi idije Olympic ni Japan, to si pada sọ pe oun gba lero lati wa iṣẹ lati ṣe lati pese iranlọwọ fun mọlẹbi oun.

"N ko ni nkankan ni Uganda. Iyawo mi ti loyun, ati pe emi ko ni ọna lati ri owo," Ssekitoleko sọ fun BBC. "N ko ni anfani lati tọju ẹbi mi,"

Elere idaraya naa sọ pe lẹyin naa ni awọn ijọba Uganda ti fi ofin de lati ma le kopa ninu idije Olympic ati idije Commonwealth fn bi o ṣe doju ti orilẹeede rẹ.”.

“Ọpọlọ mi, ni pataki, ko ṣiṣẹ ni akoko yẹn,” Ssekitoleko ṣafikun.

Ẹni ọdun mẹrinleelogun sọ pe ọpọ elere idaraya to wa lati awọn orilẹede ti wọn ko fi bẹ ni owo, o ni fun ọpọ lati wa ounjẹ, ki wọn dẹ un gba ojumọ iṣẹ ti wọn ya laayo.

Aworan Julius Ssekitoleko

Oríṣun àwòrán, Julius Ssekitoleko

Ṣugbọn nigba ti o wa ni Tokyo, International Weightlifting Federation sọ fun u pe ko si ninu ọmọ ẹgbẹ Olympic, ati pe Igbimọ Olympic ti Uganda (UOC) ti ṣeto fun un lati pada si Uganda laipẹ.

Ninu alaye akọkọ wọn, UOC sọ pe Ssekitoleko de Japan ṣaaju ki o to ijẹrisi rẹ lati le kopa nini idije naa.

Sibẹsibẹ, Julius da awọn oṣiṣẹ lẹbi fun gbigbe lọ si Tokyo laisi idaniloju boya o ti peye.

Ssekitoleko sọ pe o ti ta alupupu rẹ, eyi ti o n lo lati ri owo nipasẹ gbigbe fun awọn eniyan lati gun, lati ri owo fun irin-ajo rẹ lọ si Tokyo ni ireti lati gba ami-eye ni awọn ere. Sibẹsibẹ, ni ipari, wọn ni ko kuro ni idije naa lai kopa ni Tokyo.

Lẹyin to pora, o sọ pe oun wa iṣẹ ni Japan, to si n run kiri fun ọjọ mẹta , to si n jẹ ounjẹ diẹ to gbe dani.

"Nigbati mo kuro ni yara mi, Mo fi diẹ ninu awọn akara oyinbo ati ogede sinu apo mi ki n le jẹun."

Pipora rẹ fa ki ọpọ ma wa kiri, o pari pẹlu idapada rẹ si Uganda.

Wọn mu Ssekitoleko lọ sí atimọle ọlọpaa nigba to de, wọn si dasilẹ lẹyinrọẹyin

Ofin to dẹrọ awọn eeyan to wa n aabo lọ oke okun

Aworan Krystsina Tsimanouskaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Tsimanouskaya poses with t-shirt with the lettering reading 'I just want to run'

Gẹgẹ bi ajọ agbaye (UN) se ṣalaye, awọn oluwa-ibi-isadi jẹ ẹni to sa fun rogbodiyan tabi eewu ati sisa lati wa aabo, ti ko si le pada si orilẹede lasi .

Ọrọ ti a n pe oluwa ibi asadi lo tọka si eeyan to pinnu latoi lọ si orilẹede mii lọ bẹrẹ igbesi aye tuntun tabi lati wa ọna lati jẹ.

“Awọn eeyan elere idaraya ko ni gbẹyin nibi sise ojuse wọn, ti wọn si saa kuro niu orilẹede abinibi wọn nitori aisi aabo to meye ,” Jana Favero ti Ile-iṣẹ Ohun elo ibi aabo ti Australia (ASRC) sọ fun BBC.

Australia, orilẹede ti yoo gba alejo Olympic 2032, ti rii ọpọ iye awọn elere idaraya ti o beere ibi aabo, paapaa lẹhin Awọn ere Agbaye 2018.

Ms Favero tẹnumọ pe gbogbo eniyan ni ẹtọ labẹ ofin lati wa aabo lọ si ibi kibi ti wọn de si

Ileeṣẹ Ms Favero ti ṣe iranlọwọ fun ọpọ awọn elere idaraya ti n wa aabo lati ọwọ idunkoko orilẹ-ede wọn ni ọpọ ọdun sẹyin.