Oyo jail break: Ọ̀pọ̀ olùgbé Abolongo fara pa torí ìkọlù ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n ń sá kúrò nílé

An araalu fara pa lasiko ti ẹlẹwọn Abolongo kọlu wọn

Yoruba bọ, wọn ni ki oju ma ri ibi, gbogbo ara ni oogun rẹ.

Eyi lo difa fawọn olugbe agbegbe ọgba ẹwọn Abolongo niluu Oyo kan ti wọn ti fi adugbo naa silẹ bayii lẹyin ti ado oloro mii tun bu gbamu nibẹ lọjọ Iṣẹgun.

Ọjọ Ẹti ọsẹ to lọ lawọn agbebọn yabo ọgba ẹwọn naa nibi tawọn ẹlẹwọn kan ti salọ lẹyin ikọlu to waye pẹlu oriṣiiriṣii ohun ija oloro.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye fawọn olugbe adugbo pe awọn lo ṣee ti ado oloro tawọn agbebọn fi silẹ ninu ọgba ẹwọn bu gbamu ko o le ṣe akoba fawọn eeyan, awọn ara adugbo naa ni inu ibẹru-bojo lawọn wa.

BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe Abolongo lati mọ bi awọn olugbe agbegbe naa ṣe wa lẹyin ibugbami ado oloro ẹlẹẹkeji nibẹ.

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

Ọpọ olugbe adugbo Abolongo lo sa kuro nile nitori ikọlu ọgba ẹwọn:

Arakunrin Oladokun Quadri, to jẹ alaga awọn olugbe agbegbe Abolongo ati arabinrin Ola adua ti oun naa n gbe adugbo yii ṣalaye fun BBC Yoruba pe ọpọ eeyan lo ti fi adugbo naa silẹ lẹyin ti ado oloro tun bu gbamu fun igba keji.

Ọgbẹni Quadri ni ibẹru-bojo ni ọpọ fi fi ile wọn silẹ lẹyin ti ado oloro mii tun bu gbamu lọjọ Iṣẹgun tori iyalẹnu lo jẹ fun wọn.

Quadri ni ''ọpọlọpọ ayalegbe ni ko pada sile lẹyin ado oloro ẹlẹẹkeji to bu gbamu lọgba ẹwọn Abolongo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A rawọ ẹbẹ si ijọba lati gba wa tori ẹmi wa ṣe koko.

Iwadi ti a ṣe fihan pe ado oloro ti awon agbebọn ri mọlẹ nigba ti wọn kọlu ọgba ẹwọn Abolongo lọjọ Ẹti to lọ lawọn ọlọpaa yin ki o maa ba ṣe akoba fawọn eeyan.

Ṣugbọn ẹru si wa lara wa nitori bi ibugbamu alakọkọ ti ṣẹlẹ tẹlẹ."

Olugbe adugbo Abolongo mii, arabinrin Iya Adua ni ọkan awọn ko balẹ, tori awọn eeyan kan ba iṣẹlẹ ibugbamu akọkọ lọ.

Iya Adua ni ''mo pade ọga Amotekun ti ibọn ba ni alẹ ọjọ naa ti o si sọ fun wa pe awọn agbebọn le oun wọ inu igbo.

Eyi gan an lo jẹ ki ọpọ eeyan salọ lẹyin ibugbamu ẹlẹẹkeji ti ti ọjọ Iṣẹgun tori ọkan wa ko balẹ.

Àkọlé fídíò, Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé

Eeyan meji ni awa ọdẹ ibilẹ padanu lasiko ta n sa ẹlẹwọn kiri igboro Oyo:

Ọkan lara awọn ọlọdẹ ilu Oyo to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe o ṣe pataki ki ijọba ro awọn ẹṣọ eleto abo lagbara nitori iru ikọlu bayii.

O ni ọpọ awọn ẹlẹwọn ni awọn ọlọdẹ ibilẹ n ṣà kaakiri nilu Oyo, ti wọn si pa meji lara awọ, ti wọn si ba isẹlẹ naa lọ.

"A bẹ ijọba torí ogun naa le amọ a dupẹ pe a ja ajaṣẹgun bi o tilẹ jẹ pe meji ninu awa ọdẹ ibilẹ ba isẹlẹ naa lọ.

Awa ko mọ ohun to fa ikọlu naa amọ o jẹ eyi to taba ara ile ati ara oko, a si ti mu ọpọ awọn ẹlẹwọn yii pada si ọgba ẹwọn Abolongo.

Ogboju ọdẹ naa sọ pe oogun ko le ko ilu Oyo, amọ awa naa yoo fi aayan kun aayan wa lati daabo bo ilu wa sugbọn ijọba ni lati fun awa ẹṣọ eleto abo ni irinṣẹ ijagun lati koju iwa ọdaran."