Man puts Himself Up for Sale: Hisbah kéde ìdí tó fí mú ọkùnrin tó lù ará rẹ ní gbanjo ₦20m

Aliyu Na idris to n polowo ara rẹ fun tita

Oríṣun àwòrán, SANI IDRIS/ FACEBOOK

Njẹ ẹ ranti arakunrin ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn to ni oun fẹ lu ara oun ni gbanjo ogun miliọnu naira?

Ikọ ọlọpaa ẹsin Hisbah ni Kano ti mu .

Wọn ni ni idi tawọn fi mu ni pe ẹsin Isilaamu tapa si ki eeyan ni oun fẹ ta ara oun.

Laipẹ yi ni iroyin gba oju opo ayelujara nigba ti Aliyu Na Idris le ara rẹ sori igba, to si ni ẹni ba ni ogun miliọnu naira lanfaani lati ra oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori ikọ Hisbah Haruna Inb Sina fidi ọrọ mulẹ pe, awọn ti mu arakunrin naa ati pe ọdọ awọn lo sun mọjumọ.

''Bẹẹ ni lalẹ ana la mu, o si sun lọdọ wa mọjumọ ṣugbọn mi o ti ba sọrọ''

Ọga Hisbah naa sọ fun BBC pe lowurọ Ọjọru ni oun yoo lọ ba arakunrin naa ti awọn yoo si jọ fọrọ jomi toro ọrọ.

Àkọlé fídíò, Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé

"Ninu ẹsin Isilammu, eewọ ni ki eeyan gbe ara rẹ kalẹ fun tita labẹ eyikeyi idi to le wu. Mo maa ṣe alaye si nipa ọrọ yii ta ba ri arakunrin naa''

Aliyu to n ṣiṣẹ aransọ ko to gbe ara rẹ sita fun tita sọ fun awọn akọroyin pe iya ohun iṣẹ lo fa sababi toun fi fẹ ta ara oun.

Aliyu kọ si ori patako pe ki awọn eeyan wa ra oun ni miliọnu lọna ogun Naira.

O ṣalape pe ''Awọn mọlẹbi mi mọ si nkan to n ṣẹlẹ to si jẹ pe nitori aisowo ni.Mo kọkọ gbiyanju ni Kaduna ṣugbọn mi o ri eeyan ra mi ki n to wa lọ si Kano''

"Awọn kan ti gbe owo lori mi ṣugbọn iye ti wọn da le mi lori ko ti to ogun miliọnu ti mo fẹ''

"Afojusun mi ni pe bi mo ba fi ri eeyan ra mi, mo maa fun ijọba ni miliọnu marun un gẹgẹ bi owo ori ninu rẹ''

O tẹsiwaju pe ''maa fun awọn obi mi ni miliọnu mẹwaa,miliọnu meji fun ẹni to ba mi polowo,maa si fi miliọnu mẹta to ku si ọdọ ẹni to ba ra mi lati maa fi ṣe itọju mi''

Onwoye kan lawujọ Nura Isah to n gbe ni Kano sọ fun BBC pe o se pataki ki Hisbah mu Aliyu lootọ.

Amọ ọpọ eeyan lo ri gẹgẹ bi ere ohun ẹfẹ to si yẹ ki Hisbah ma ṣe da si ọrọ naa.

"Hisbah ko ba kan pe joko ki wọn si gba nimọran ni dipo bi wọn ṣe mu''

''Awọn ara Kano kuku ka ọrọ rẹ kun. Amọ bayi ti wọn mu, nkan to n wa pe ki awọn eeyan foju si ọrọ rẹ lo ti wa ri bayii''

Amin iyasọtọ kan

"Gbàǹjo! Ta ni yóò rà mí ní ₦20m, mo wà fún títà"

Aliyu Na idris to n polowo ara rẹ fun tita

Oríṣun àwòrán, SANI IDRIS/ FACEBOOK

Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, ti eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọkunrin kan, Aliyu Na Idris, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn lati ipinlẹ Kaduna, to n polowo ara rẹ fun tita fun ẹnikẹni to ba fẹ lati ra a nilu Kano.

Idris to ni isẹ aransẹ ni oun n se lo ti n rin gbere gbere kiri awọn opopona nilu Kano pẹlu akọle kan lọwọ rẹ to ni "Ọkunrin yii wa fun tita pẹlu ogun miliọnu naira."

Iroyin naa ni o ti to ọjọ marun bayii ti Aliyu ri n polowo ara rẹ kiri oju popo, to n wa onibara ti yoo ra a bii ẹru.

Nigba to n bawọn akọroyin to se alabapade rẹ sọrọ, Aliyu ni isoro ile aye, airijẹ, airimu lo mu ki oun pinnu lati ta ara oun, bi apap ko ba sa se san, a n ka lori ni.

Àkọlé fídíò, Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

O ni awọn mọlẹbi oun gan ti mọ pe oun ti n polowo ara oun fun tita, koda, oun ti polowo ara oun ni Kaduna.

Amọ o ni nigba ti oun ko ri onibara gidi ti yoo ra oun, ni oun wa si Kano pẹlu ireti pe oun yoo ri onibara gidi ti yoo san owo ti oun n beere.

"Lootọ ni ọpọ eeyan fẹ san miliọnu mẹwa, marun ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira lati ra mi amọ awọn owo yii kere si iye ti mo fẹ ta ara mi."

Aliyu ni isẹ aransọ ti oun n se lo kuna tori ọda owo, ti oun si padanu ọpọlọpọ awọn onibara oun, eyi to mu ki aye le lati gbe, ti owo si ta oun lọwọ.

O ni oun ko ni owo lọwọ lati se ile aye, ka to wa sọ pe oun yoo dokowo, idi si ree ti oun se n lu gbanjo le ara oun lori fun tita.

Bi maa se na ogun milinu naira ti mo ba ta ara mi ree:

Nigba ti wọn bi pe ki lo fẹ fi ogun miliọnu naira se to ba ta ara rẹ, Aliyu ni "Maa fun awọn obi mi ni miliọnu mẹwa ninu owo naa.

Maa tun san miliọnu marun bii owo ori fun ipinlẹ ti wọn ba ti ra mi, maa fun ẹni to seranwọ lati polowo mi fun tita ni miliọnu meji naira.

Miliọnu mẹta naira to ku ni ẹni to ta mi yoo ba mi fi pamọ fun itọju ara mi lojoojumọ."

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

O wa salaye pe oun mọ pe oun ko ni ni ominira mọ lẹyin ti wọn ba ra oun amọ eyi ko da omi tutu si oun lọkan rara.

Aliyu ni oun ti pinnu lati maa se ifẹ ọkan ẹni to ra oun nitori ibi to ba wu ẹfuufu lẹlẹ nii dari igbẹ si, ibi to ba wu olowo ẹni, nii ran ni lọ.

Bakan naa lo leri leka pe bi onibara kankan ko ba yọju lati ra oun nilu Kano, oun yoo tun morile ipinlẹ miran lati polowo ara oun fun tita.