Oyo Jail Break: Ọ̀gá àgbà ọgbà ẹ̀wọ̀n fèsì lórí ìròyìn pé Wakili Iskilu wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ lọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo l'Oyo

Oríṣun àwòrán, BBC/others
Ọpọ lo ti n sọ pe afurasi olori awọn Fulani ajinigbe, Iskilu Wakili wa ni ọgba ẹwọn Abolongo niluu Oyo nibi tawọn afurasi agbebọn ṣe ikọlu si ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn silẹ.
Ajọ to n ṣe akoso ọgba ẹwọn ni Naijiria, NCS ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ṣe alaye wi pe awọn ẹlẹwọn ẹgbẹrin ati metadinlogoji, 837 to n reti igbẹjọ ni ọgba ẹwọn Abolongo to n bẹ nilu Ọyọ lo salọ.
Awọn ẹlẹwọn ọhun raye salọ lẹyin tawọn afurasi agbebọn yawọ ọgba ẹwọn naa ni alẹ ọjọ Ẹti.
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Iskilu Wakili, afurasí Balógun Fulani tí OPC mú ní Ayetẹ ìpínlẹ̀ Ọyọ
- A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa - Ooni Ife
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
- Sunday Igboho fún Abubakar Malami àti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà lési ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí wọ́n fi kàn án
- Nnkan ìtìjú gbàá ni bí wọ́n ṣe já ọgbà ẹ̀wọ̀n l'Oyo - Iba Gani Adams
- Amotekun àti Sọ́jà kú lásìkò tí wọn já ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo l‘Oyo - Makinde
- Ajínigbé jí ọmọ ìyá méjì gbè lákàtà ìyá wọn nílùú Akure
Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe Iskilu to wa lọgba ẹwọn naa lo ṣe okunfa bi awọn agbebọn sẹ kọlu ọgba ẹwọn naa.
Awọn eeyan naa ni Iskilu wa lara awọn ẹlẹwọn to salọ.
Ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, ọga agba ọgba ẹwọn ni Naijiria, Tukur Ahmed ti fidi rẹ mulẹ pe Iskilu ko si lọgba ẹwọn Abolongo debi pe yoo raye salọ lati ibẹ.
Ọdun to kọja ni awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples Congress (OPC) le Wakili kuro nilu Ayete nipinlẹ Oyo, ti wọn si fi le ọlọpaa lọwọ.
Awọn ara ilu naa fi ẹsun kan an pe oun ni balogun awọn Fulani to n ni araalu lara nibẹ.
Bakan ni o ṣalaye pe afurasi agbenipa, Sunday Shodipe ti ọwọ tẹ ni agbegbe Akinyele lọdun 2020, naa ko si ni ọgba ẹwọn Abolongo gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ kaakiri.

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government
Ọgbẹni Ahmed fidi ọrọ yii mulẹ nigba to n sọrọ lori ẹrọ Radio Nigeria lori iṣẹlẹ naa.
Ọga agba ọgba ẹwọn ni Naijiria ṣalaye pe ọgba ẹwọn to wa niluu Ibadan ni Iskilu ati Shodipe wa kii ṣe Abolongo niluu Oyo.
Ọpọ ninu awọn ẹlẹwọn to wa ni ọgba ẹwọn Abolongo lo ti pada fun ra wọn nigba tawọn agbofinro mu awọn mii.
Alukoro ileeṣẹ ọgba ẹwọn ti ẹka ilu Oyo naa, Olanrewaju Anjọrin, sọ fun BBC Yoruba pe Iskilu ati Shodipe ko si ni ọgba ẹwọn l'Oyo.
Amọ o fidi rẹ mulẹ pe Ọgbẹni Olaniyan Amos ti ajọ EFCC fẹsun jibiti lilu kan wa ni ọgba ẹwọn Abolongo niluu Oyo ni tirẹ.
Anjorin ṣalaye pe ọkunrin naa ko salọ sibi kan nigba tawọn agbebọn kọlu ọgba ẹwọn l'Oyo.
O ni Ọgbẹni Amos si wa ni ọgba ẹwọn naa titi di akoko yii.
Ẹwẹ, minisita ọrọ abẹle, Ogbeni Rauf Aregbesola, ti sọ pe gbogbo awọn ẹlẹwọn to salọ ni ileeṣẹ ọgba ẹwọn yoo mu pada.

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Interior
Ogbeni Aregbesola sọrọ yii nigba to ṣabẹwo si ọgba ẹwọn Abolongo nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
''Ikọlu si awọn ọgba ẹwọn wa ni Naijiria ti n pọju, o si n kọ wa lominu.
Amọ, o to gẹẹ bayii, a gbọdọ wa nkan ṣe si ọrọ naa, ṣugbọn mo fi n da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn to wa nidi ikọlu yii atawọn ẹlẹwọn to salọ lọwọ ofin yoo ba.
Mo gboṣuba fawọn ẹṣọ eleto abo wa fun iṣẹ ribi ribi ti wọn ṣe lati doju ija kọ awọn afurasi agbebọn to ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn Abolongo.
A ti mu awọn kan ninu awọn ẹlẹwọn to salọ, o dami loju pe a o mu awọn to ku naa,'' Ogbeni Aregbesola lo sọ bẹẹ.















