Oníṣòwò ni mí, n ò kìí ṣe agbésùnmọ̀mí, Sunday Igboho ti dá Abubakar Malami àti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà lési ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí wọ́n fi kàn án

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/ instagram
Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti da ijọba apapọ orilẹede Naijiria loun lori ẹsun didaṣẹpọ pẹlawọn agbodegba igbesumọmi Bokoharam ti wọn fi kan an.
Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro fun oloye Sunday Igboho, Amofin agba Yọmi Alliyu SAN fi sita, wọn ni atamọ-atamọ ni minisita feto idajọ mallam Abubakar Malami SAN n wa lati ṣe lọna ati lee so Sunday Igboho pọ mọ awọn agbodegba igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
- Sunday Igboho ní òun tí gbúró olóṣèlú kan tó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ gbokùn lọ́dọ̀ ààrẹ, òkò ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ síi nìyí
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
- Òṣèré Tíátà ṣèèṣì yìnbọn lórí ìtàgé, arábìnrin kan ti forí la ikú, òmìí farapa
- Àwọn aṣòfin ti fòǹtẹ̀ lu ṣíṣẹ́ oyún tí kò í pé oṣù mẹ́ta ní ìlú yìí
Wọn fi kun pe miliọnu mejila o le naira (N12.7 million) ti ijsba apapọ n gbiyanmju ati so mọ eto igbesumọmi ko lẹsẹ nlẹ rara. O ni ninu atẹjade ti wọn ka faraye, ko si gbajumọ oniṣowo bii Sunday Igboho ti kii da owo pọ pẹlawọn ti n ṣe paṣiparọ owo ilẹ okeere ati pe owo ti wọn n sọ yii Igboho lo fi ranṣẹ si ileeṣẹ Abbal Bako ti o jẹ ti Abdullahi Umar gẹgẹ bi wọn ṣe sọ. O ni to ba jẹ pe awọn eeyan wọnyi lo n ṣe agbodegba fun Sunday Igboho, kii ṣe igboho lo yẹ ko maa fi owo ranṣẹ si wọn, awọn gan ti wọn n fi ẹsun kan pe wọn n ṣe agbodegba fun iwa igbesumọmi lo yẹ ki wọn maa fi owo ranṣẹ sii.
"Oniṣowo ọkọ ni oloye Sunday Adeyẹmọ labẹ ileeṣẹ Adesun International Concept lt. Ṣe o wa tums si pe gbogbo awọn to ba n ra ọkọ lọwọ rẹ tabi awọn to n ta ọkọ fun ni agbesunmọmi?"
"Oloye Sunday Adeyẹmọ ti inagijẹ rẹ n jẹ Igboho Ooṣa ko bẹrẹ ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ṣaaju ọdun to kọja. Nitorina bi eeyan ba ri owo ti apapọ rẹ jẹ ọrinlelugba o din meje miliọnu naira (N273m) laarin oṣu kẹwaa ọdun 2013 si oṣu kẹsan ọdun 2020, o fihan pe Igboho kii ṣe akurẹtẹ oju o rọlari ẹda ni. biliọnu meji naira ni owo ori ile rẹ ti awọn ẹṣọ DSS kọlu ni ọjọ kini oṣu keje."
Wọn wa ke si ijsba apapọ pe ko darukọ aṣofin to fi owo ranṣẹ si oloye Sunday Igboho fun iwa igbesunmọmi bi wọn ko ba ni wọ gbese ẹsun ibanilorukọjẹ.
Amofin Alliyu tun jẹ ko di mims pe titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ijsba apapọ ko tiiroju ọjọ fi pe Sunday Igboho lẹjọ iwa ọdaran kanakan, yala igbesunmọmi.











