Abortion law: Àwọn aṣòfin ti fòǹtẹ̀ lu ṣíṣẹ́ oyún tí kò í pé oṣù mẹ́ta ní ìlú yìí

Ṣiṣẹ oyun wa ni ibamu pẹlu ofin ni awọn orilẹede Afirika kọọkan eyi naa ni awọn aṣofin orilẹede Benin Republic naa n ja fun.
Awọn aṣofin ọhun ti dibo lati jẹ ki ofin faye gba ṣiṣẹ oyun pẹlu bi wọn ṣe lo apẹrẹ awọn asiko to ha ti wọn ko ribi tii si ti wọn si faaye gbaa.
Nibayii awọn obirin lee ba oyun ara wọn jẹ laarin oṣu mẹta lawọn iṣẹlẹ to ba nii ṣe pẹlu eyi to lee "da wahala silẹ ni ti ohun ini, ẹkọ, ikọṣẹmọṣẹ tabi idamu ọkan yala si obinrin naa tabi fun ọmọ inu rẹ".
Ṣaaju asiko yii, ibi ti ofin ti faaye gba ṣiṣẹ oyun ni awọn ti wọn ba fipa balopọ tabi ti ẹmi iya ọmọ ba wa ninu ewu nikan.
Bakan naa wọn faaye gbaa ti bo ba ṣe pe ifipabanilopọ tabi ibalopọ to jẹ laarin ọmọ iya kan naa tabi obi si ọmọ ni.
Ofin tuntun yiiti wọn fọwọ si nile aṣofin Benin lỌjọru ọsẹ lẹyin ọpọlọpọ itakurọsọ to gbona janjan amọ wọn ni o ṣi nilo ifọwọsi ile ẹjọ ko to di ohun.
Minisita eto ilera ti gboriyin fun ofin naa pe yoo mu irọrun ba ọpọlọpọ obinrin ti ko fẹ iru oyun ti wọn ni to si n fi ẹmi wọn wewu.













