2023 Nigeria: Atiku sọ pé òun leè ṣé àtúnṣe Nàìjíríà, báwo ló tí ṣe fẹ́ gbée gbà?

Aworan Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Facebook/Atiku.org

Igbakeji aarẹ tẹlẹri ni Naijiria, Atiku Abubakar ti sọ pe orileede naa nilo olori ti yoo ṣe atunto ọrọ aje ti yoo si mu ki oun gbogbo wa ni ṣẹpẹ.

Ẹni to si ni o kaju osunwọn iṣẹ yi ni oun.

O fi ọrọ yi lede nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ati ifiwelọlẹ alaga ileeṣẹ iroyin DAAR Communications,Raymond Dokpesi.

Atiku fi kun pe Naijiria nilo adari ti yoo mu isọkan wa ti yoo ṣe atunto ti yoo si daabo bo araalu.

Nigba ti awọn akọroyin beere lọwọ rẹ pe ṣe o lero pe oun le ṣe o fesi pada pe''Mo ti sọ bẹ tẹlẹ, Mo maa ṣe''

Odu ni Atiku Abukar jẹlagbo oṣelu Naijiria kii ṣe aimọ faraalu.

Bi o ba dije du ipo ninu idibo to n bọ ni 2023,eyi yoo jẹ igba ẹlẹkẹẹfa ti yoo kopa ninu idibo.

Ṣaaju lo ti du ipo aarẹ lọdun 1993, 2007, 2011, 2015 ati 2019.