2019 Elections: Ṣoyinka ní irú kan náà ni Buhari àti Atiku

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ọkan ko gbe kan bi owu jango ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati oludije aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar, bẹẹ ni ko si ẹni to yẹ fun aarẹ orilẹede Naijira ninu idibo to n bọ", Ọjọgbọn Wole Ṣoyinka lo sọ bẹẹ.
Ọpọ lo kọkọ ro pe Aarẹ Buhari ni Ọjọgbọn Ṣoyinka n ṣe atilẹyin fun nigba ti o bu ẹnu atẹ lu bi aarẹ ana Oluṣegun Obasanjo ti kede atilẹyin rẹ loṣu to lọ fun Atiku.
Ṣugbọn Ọjọgbọn naa ya ọpọ eeyan lẹnu nigba ti o sọ oju abẹ niko l'Ọjọru nilu Eko nibi to ti fidi rẹ mulẹ pe asiko ti to fawọn ọmọ Naijiria lati wa olori miiran yatọ si Buhari ati Atiku.
Ṣoyinka ṣalaye pe oun gẹgẹ bi ẹnikan, ko ni dibo fun Buhari ati Atiku ninu ibo to n bọ nitori kosi ẹni to yẹ lati dibo fun ninu awọn mejeeji.
Ọjọgbọn naa oun ṣetan lati dibo bi oludije miiran to yatọ si awọn mejeeji ba yọju, bakan naa ni o ṣalaye pe ipade n lọ nilu Eko ati Abuja lori bi oludije miiran yoo ṣe jade.
Ṣoyinka fi kun ọrọ rẹ pe asiko ti to fawọn ọmọ Naijiria lati yọ ara wọn loko ẹru awọn oloṣelu to ti pẹ.









