Oyo Prison Break: Nàkan ìtìjú gbàá ni bí wọ́n ṣe já ọgbà ẹ̀wọn l'Oyo-Iba Gani Adams

Adams dá àwọn elétò ààbò ni ìpínlẹ̀ Oyo lẹ́bi pé n ko sí aabo tó péye ni agbegbe ọgbà ẹ̀wọ̀n náà láti ẹ̀yìn wá.

Oríṣun àwòrán, Iba gani

Ààrẹ Ọ̀nàkakanfo gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams ti bẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó wáyé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo nílùú Oyo pé, ìkọlu náà na ìka ìdọ̀tí sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà.

Àwọn afurasí jàndukú kan lo yabo ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo tí wọ́n sì tú ẹlẹ́wọ̀n 823 sílẹ̀.

Lásìkò tí ń sọ̀rọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tí olùranlọ́wọ́ pàtàkì fún lórí ìròyìn, Kehind Aderemi fọwọ́sí ṣàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàfihàn bi ètò àbò ṣe mẹ́hẹ tó ni Nàìjíríà.

Bákan náà ló fi ẹ̀dùn ọ̀kan rẹ̀ hàn pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti pẹ́ tó tí wáye ni ilú Oyo ati gbogbo ìhà ìwọ-oorùn- Gúúsù Nàìjira, ó ni irú èyí ti ṣẹlẹ̀ ni Kabbani ìpínlẹ̀ Kogi ni ọdun díẹ̀ sẹyín.

O ní Oyo ko tíì ni àkọsílẹ̀ irú nǹkan báyìí láti àsìkò tó ti pẹ́, sùgbọ́n ó jẹ́ nǹkan tí o bani nínú jẹ́ pé, ètò ààbò tó mẹ́hẹ ni Nàìjíríà fa irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Adams dá àwọn elétò ààbò ni ìpínlẹ̀ Oyo lẹ́bi pé kò sí aabo tó péye ni agbegbe ọgbà ẹ̀wọ̀n náà láti ẹ̀yìn wá.

" Pẹ̀lú bi àwọn jàndùkú ṣe kọlu ọkọ̀ ojú-irin tó nlọ Abuja ti wọ́n tún kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Oyo, ó túmọ̀ sí pé, ó ni nǹkan ti wọ́n ń gbìyànjú láti ṣe, tí yóò sì nípa lórí gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè yìí"

"Ó jẹ́ nǹkan tí o bani nínú jẹ́ láti gbọ́ irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ láti ilú iṣẹmbaye bi ti Oyo. Ẹ̀wẹ̀, mo fẹ́ fi èrò ọkàn mi hàn si kábíyèsí, Ọba Lamidi Adeyemi àti ìjọba ìpińlẹ̀ Oyo"

"Bákan náà ni mò n lo àǹfàní yìí láti rọ ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà láti mójú tó ètò àbò ni ìpínlẹ̀ Oyo kí ó si gbé ìgbésẹ̀ lọ́na tí ó tọ́, ẹ̀yin lójú ni ìpínlẹ̀ Oyo jẹ́ sí iwọ-oorun-Gúúsù Nàìjíríà, nítorí náà àwọn ènìyàn ko le máá gbé nínú ìbẹ̀rù bojo."

Adams wá pé fún ìṣèjọba àwaarawa tó sì jẹ́ ẹlẹkùnjẹkun, àti pé, èyí ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó le mu ojúútu sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀, nínú ètò yìí, ẹẹkùn kọ̀ọ̀kan ni yó maa dari ọ̀rọ̀ àbò.

" Orílẹ̀de tó ni èèyàn tó lé ni mílíọ̀nu lọ́nà igba àti ẹyàmẹyà tó lé ni ọ̀ọ̀dúrún kò le ṣe àṣe yọrí nípa lílo àgbáríjọ ìdari kan.