Oyo Jail Break: Wọ́n rí ẹlẹ́wọ̀n 262 padà, 575 sálọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo

Ajọ to n ṣe akoso ọgba ẹwọn ni Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ti ṣe alaye wi pe awọn ẹlẹwọn ẹgbẹrin ati metadinlogoji, 837 to n reti igbẹjọ ni ọgba ẹwọn Abolongo to n bẹ nilu Ọyọ lo salọ.
Awọn ẹlẹwọn naa lo raye salọ lasiko ti awọn afurasi agbebọn yawọ ọgba ẹwọn naa ni alẹ ọjọ Ẹti.
Alukoro ajọ naa, Olanrewaju Anjọrin lo sọ ọrọ naa di mimọ ninu atẹjade kan ti o to awọn oniroyin lọwọ nilu Ibadan lọjọ Abamẹta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo oníbárà méje tó lówó jùlọ ní àgbáyé
- Ajínigbé jí ọmọ ìyá méjì gbè lákàtà ìyá wọn nílùú Akure
- Kìí ṣe nǹkan ìtìjú pé èmi ni mò ń gbọ́ bùkátà ẹbí mi - Nkechi Blessing
- Sunday Igboho ní òun tí gbúró olóṣèlú kan tó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ gbokùn lọ́dọ̀ ààrẹ, òkò ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ síi nìyí
- Gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná láàrín Oluwo àtàwọn ìgbìmọ̀ Ìmáàmù àti Àlfáà ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní Oluwo ń kọjá àyè rẹ̀
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
Anjọrin ni awọn agbebọn naa ko ba awọn iyara ti wọn ko awọn ẹlẹwọn naa si jẹ, ki wọn to tu gbogbo wọn silẹ.
O ni apapọ ọtalerugba o le meji 262 ninu awọn ẹlẹwọn to sa lọ naa ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ bayii, nigbati awọn ẹlẹwọn ọrinlelẹẹdẹgbẹta o din marun, 575 si ti na papa bora.
O tẹsiwaju pe ado oloro ni awọn agbebọn naa fi fọ ogiri ọgba ẹwọn lẹyin ti wọn doju ibọn kọ awọn ẹṣọ aabo to n ṣọ ibẹ.
Anjọrin fi kun ọrọ rẹ pe ọga agba ajọ naa, Haliru Nababa lo paa laṣẹ pe ki wọn lepa awọn ẹlẹwọn to salọ, ti wọn si ri mu lara wọn.
Ọgba ẹwọn naa ti wọn da silẹ lọdun 2007 lo ni aye fun ọgọfa ẹlẹwọn pere, ṣugbọn alukoro ajọ naa fi idi ẹ mulẹ pe. awọn eeyan ẹẹdẹgbẹrun o le meje, 907 lo wa ninu ọgba naa lasiko ti ikọlu yii waye.
O ni ninu onka awọn eeyan wọnyii, ida mejilelaadọrun ninu wọn lo n reti igbẹjọ nigbati ida mẹrinlegọta ti jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
A padanu Amotekun kan ati Sọja kan - Gomina Seyi Makinde
Wayi o, gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sisọ loju rẹ pe osisẹ Amotekun kan ati Sọja kan to n sisẹ pẹlu Operation Burst lo sọ ẹmi wọn nu lasiko ti wọn ja ọgba ẹwọn Abolongo naa.
Gomina Makinde sisọ loju ọrọ yii lasiko to n se ikede nipa ọgba ẹwọn ti awọ agbebọn kan ja nilu Oyo to si ni orukọ osisẹ Amotekun to ku naa ni Tijani Babatunde
O tun salaye pe obinrin osisẹ Amotekun kan, Shukura Omoba wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nile iwosan nitori ọgbẹ to ni lati ipasẹ isẹlẹ naa nibi ti ọpọlọpọ eeyan miran ti fara pa.
Makinde ni oun ti de ile iwosan lati lọ wo obinrin naa, ti pun si n lo gbogbo ohun ti ijọba ni lati ri daju pe ko ku, bẹẹ lo tun n tọrọ adura araalu fun ẹmi obinrin naa.

Àwọn agbébọn ya wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Oyo, wọ́n tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Google
Ni alẹ ọjọ Ẹti ni awọn agbebọn kan yawọ ọgba ẹwọn Abolongo to n bẹ niluu Ọyọ ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn silẹ lẹyin ti wọn doju ibọn kọ awọn oṣiṣẹ alaabo to n mojuto ọgba ẹwọn naa.
Ọkan lara awọn ọga agba to jẹ alamojuto ọgba ẹwọn naa to ba wa sọrọ labẹ aṣọ fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ pẹlu alaye wi pe ni nnkan bi i aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye.
O ni awọn ẹṣọ aabo to n ṣọ ọgba ẹwọn naa ati awọn agbebọn naa jọ doju ibọn kọ arawọn ki wọn to lanfani lati wọle ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn kan silẹ, ti awọn mii si fi ara pa.
Iroyin ti a gbọ ni pe ijọba ti fi awọn ẹṣọ aabo mii ranṣẹ si agbegbe naa bayii, wọn si ti ri mu lara awọn ẹlẹwọn to salọ.
Ẹkunrere iroyin n bọ lọna...
- Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà
- Ọ́ọ́físà tó lu Clement awakọ̀ Uber níbi EndSARS gba ìwé máa lọ ilé ná
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
- Sunday Igboho ní òun tí gbúró olóṣèlú kan tó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ gbokùn lọ́dọ̀ ààrẹ, òkò ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ síi nìyí
- Òṣèré Tíátà ṣèèṣì yìnbọn lórí ìtàgé, arábìnrin kan ti forí la ikú, òmìí farapa


















