EndSars 2021: Ọ́ọ́físà tó lu awakọ̀ Uber níbi ìwọ́de EndSARS gba ìwé máa lọ ilé ná

Ọọfisa LNSC, Clement Adedotun ti wọn fiya jẹ

Oríṣun àwòrán, LNSC

Awọn alaṣẹ ajọ agbofinro adugbo nipinlẹ Eko, Lagos State Neighbourhood Safety Agency ti da oṣiṣẹ wọn meji to huwa aitọ si ọkunrin awakọ kan nibi iwọde iranti EndSARS to waye ni Lekki Toll Gate ni Ogunj oṣu Kẹwa.

Adari agba ajọ naa, Ọmọba Ọmọwe Ifalade Oyekan lo ṣipaya eyi ni olu ileeṣẹ ajọ naa to wa ni agbegbe Safety Arena, Bolade Oshodi.

Wọn jẹ ko di mimọ pe iwa ti awọn ọọfisa naa hu tabuku ihuwasi eeyan to yẹ ko jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ yii.

Ni kete ti fidio bi wọn ṣe fiya jẹ Clement gba gbogbo ori ayelujara kan lawọn eeyan bẹrẹ si ni ja fun un pe idajọ ododo gbudọ waye tori ko ni ẹṣẹ kankan.

Akọroyin BBC to wa nibi iwọde iranti EndSARS fihan ninu fidio bi awọn ọọfisa ṣe n gbe ọkunrin naa digba digba lati muu ni dandan wọ inu ọkọ wọn amọ ti oun naa n kọjalẹ pe oun ko ni wọ ibẹ rara tori oun kii ṣe ọdaran.

Àkọlé fídíò, Wo ìyà tó jẹ Adedotun Clement níbi ìwọ́de EndSARS ní Lekki Toll Gate àtohun táwọn tó sọ̀rọ̀ ń bèrè fún

Nigba ti gbogbo iwọde ọhun tun pari, awọn ọmọ Naijiria bọ sori ayelujara lati tun maa pe fun ki idajọ ododo waye fun Clement. Koda agbẹjọro kan ti baa ṣe ipade to si ni oun yoo ja fun ẹtọ rẹ.

Oyekan ṣalaye pe atawọn ọọfisa mejeji ati ọga alamojuto wọn lo ti foju wina ofin niwaju igbimọ afiyajni fun ẹsun pe wọn ṣe araalu baṣubaṣu.

"Iwa ti wọn hu yii lee da omi alafia ilu ru to si lodi si ofin inu iwe ofin ajọ agbofinro adugbo ti ipinlẹ Eko paapaa ni ẹka ikeji, ikẹta, ikẹrin, ikarun ati ikẹfa eyi to sọ nipa bi ihuwasi ọọfisa si araalu ṣe yẹ ko ri".

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Oyekan ni bo tilẹ jẹ pe iwadii n tẹsiwaju lati mọ awọn ijiya mii to tọ si wọn gẹgẹ bi arufin, awọn ti baba yọ wọn lẹnu iṣẹ naa fun igba diẹ.

Nigba to n fi igbaradi ajọ naa han lati moju to abo araalu ati dukia, Oyekan ba awọn oṣiṣẹ wọn sọrọ pe ki wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ nigba ti wọn ba n ṣe iṣẹ wọ.

O tun wa tọrọ aforijin lọwọ arakunrin ti wọn ṣe ni jamba pe ko fi ọwọ wọ inu. O ni ijọba Eko ni erongba gidi fun irẹpọ wọn pẹlu awọn araalu tori awọn ni alabaṣiṣẹpọ awọn agbofinro ati pe iru iṣẹlẹ aidaa yii ko ni waye mọ.