Bawo ni orisun omi ile Adulawo lọ́jọ́ ọla se peye to ni ilu ati orilẹ̀-ede rẹ?

Bi iye awon eniyan to wa lagbaaye se n pọ̀ sii naa ni wọ́n nilo omi to mọ́ gaara, to se e lo, ti owo re ko pọ̀ju ni eyi to n fa isoro si orisun omi to wa nill bayii ni eyi ti a pe ni "ipenija ọ̀wọngogo omi lilo"

To ba maa fi di odun 2025, ilaji awon eeyan to wa lagbaye maa ni ipenija omi lilo gege bi oro WHO

Orisun omi to se e lo ko to iwọ́n iye eeyan to n pọ̀ sii lagbaye . Bẹe si ni orisun omi lilo naa ko kari ni eyi to n je ko nira lati ri pọn, ko tun wọ́n lati gbe lati ibi kan si ibi keji fun awọn eeyan mii.

Diẹ́ lara ohun to n fa ọ̀wọ̀n gogo omi ni iye awọn eeyan to n pọ sii, ayipada oju ọjọ ati awọn to n ko lọ si igboro to pọ sii lai yọ iṣoro aisi omi to to fun iye eeyan .

Ti a ba fi ilẹ̀ Afrika ṣe afojusun wa

Ajọ Organisation for Economic Co-operation and Development (OECD) ni iye eeyan to wa nilẹ Afrika a di ilọpo meji ati aabọ biliọnu lọgbọn ọdun si akoko yii

Ilaji awọn olugbe ilẹ̀ Afrika ti n gbe ni igboro, bẹ́ẹ̀ o le ni ilaji wọn ti wọn n gbe ninu agbegbe ti ko bojumu tó

Awọn akọsẹmọṣẹ kilọ pe lai si pe wọn gbe igbesẹ to yẹ , o le ni miliọnu ọgọrun un eeyan ni Igboro ti wọn yoo ni idojukọ ọwọngogo omi

Pinpin ayipada oju ọjọ agbaye

Maapu to fi aworan pinpin iye ayipada oju ọjọ agbaye han

Orisun:: Koppen-Geiger climate distribution

Ilẹ̀ Afrika jẹ ọkan lara awọn ilẹ ti ọgbẹlẹ pọ si julọ ni agbaye, o to ida meji ninu mẹta ilẹ wọn ti ko gba omi

Ati pipin ayipada oju ọjọ

Maapu to n fi bi omi ṣe n gbe pẹlu pinpin ayipada oju ọjọ han

Orisun:: Koppen-Geiger climate distribution

Enikan ninu eeyan mẹta nilẹ Adulawo olooru lo n gbe ni agbegbe ti ọwọngogo omi wa

odiwọn iye ọwọngogo omi lilo pẹlu orilẹ-ede kọọkan (2019)

Maapu to n fi aworan odiwọn ọwọngogo omi lati orilẹde Afrika kọọkan (2019)

Orisun: OECD 2021

Orilẹ-ede Eritrea ati Botswana wa lara awọn orilé-ede Afirca ti ọwọngogo omi n ba finra julọ

Awọn koko to n fa ọwọngogo ipese omi

Ayipada oju ọjọ maa n jẹ ki iṣẹlẹ airotẹlẹ ṣẹlẹbii omiyale, ọgbẹlẹ. Odiwọn bi omi to dara ni inu ilẹ ti din ku

A n padanu ọpọlọpọ ọjọ iṣẹ ati imọ lọdọọdun nipasẹ aisan ti ọpọ n ni latara aisi omi tabi omi to mọ́ gaara

Awọn ara igboro to ni omi to mọ́ gaara fun lilo

Lati bi ogun ọdun bayii, ilẹ̀ Afrika ti n goke agba sii nipa ipese omi to mọ́ gaara pẹlu owo ti ko ga ju ara lọ bayii

Sibẹsibẹ, ipenija nla ṣi

Ajo WHo ati UNICEF sọ pe: Omi to mọ gaara, to ṣe e lo, ti ko ni idọti wa fun lilo. Odiwon iye awọn to ni omi to mọ gaara ti ko dẹ wọn ju ara lọ nilẹ Adulawo je ida mẹsan an ninu ọgọrun un ni Liberia si ida mọkandinlọgọrun un ni South Africa

SDG 6: Ipenija nini omi to mọ gaara ati imọtoto fun gbogbo eeyan

Ni 2015, ajọ agbaye United Nations fi ara rẹ jin lati rii pe ipese omi to mọ gaara wa fun gbogbo eeyan pẹlu imọtoto gẹgẹ bii ọkan lara awọn erongba o di dandan lati ṣe mẹtadinlogun ti wọn ni

Erongba yii ni wọn pe ni SDG 6

Diẹ lara awọn orilẹ-ede ti wọn ni o ṣeeṣe lati ni idojukọ nla lori ọwọngogo omi ni Djibouti, Morocco, Namibia ati Egypt

Sugbọn gbogbo orilẹ-ede Afrika lo ni idojukọ lati mu erongba SDG 6 ṣe ni orilẹ-ede koowa wọn.

Atunyẹwo erongb ayii ni 2019 fihan pe awọn orilẹ-ede kan n ṣe daadaa ṣugbọn ilaji ṣi wa loju kan naa

Nini omi to mọ gaara ati imọtoto SDG 6 ati ibi ọrọ de duro lori wọn (2019)

Idojuko to tobi ṣi wa sibẹ
O n san diẹdiẹ
Loju kan naa
O wa nibamu bo ṣe yẹ
Maapu to ṣafihan ipo ti omi to mọ gaara ati imọtoto wa ni SDG 6 lawọn orilẹ-ede Afrika (2019)
Bo ṣe bagbamu lasiko yii
Maapu to safihan ipo ti omi to mọ gaara ati imọtoto SDG 6 wa bayii nilẹ Afrika (2019)
Ipo ti ohun gbogbo wa

Koko mẹta ti wọn fi n ṣetọju omi lilo ati atunlo omi ni afojusun wọn fun omi to dọti. Lilo omi idọti lati fi kun ire oko ninu eto ógbin ati idokowo ninu iṣe imọ ẹrọ paapaa awọn ti won pe ni 'Green Infrastructure'to ni i ṣe pẹlu ohun ọgbin ati ibayedọgba