Ooni on Sunday Igboho: Ọpọlọ ló yẹ kí Sunday Igboho fi jìjà ìlú, kìí ṣe ariwo lásán -
Ooni tilu Ile-Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja Keji ti salaye pe ọpọlọ lo yẹ ki Sunday Igboho fi ja ija ilu, kii se nipa ariwo.
Ooni salaye bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ninu akanse eto ifọrọwanilẹnuwo kan to fi sami ọjọ ibi rẹ.
Ọba Ogunwusi ni oun ti ba aarẹ Buhari sọrọ pupọ nipa Sunday Igboho tẹlẹ, ti wọn si ni ki oun lọ sọ fun pe ko dakẹ ijijagbara to n se amọ ko gbọ.
- A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa - Ooni Ife
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
- Sunday Igboho fún Abubakar Malami àti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà lési ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí wọ́n fi kàn án
- Nnkan ìtìjú gbàá ni bí wọ́n ṣe já ọgbà ẹ̀wọ̀n l'Oyo - Iba Gani Adams
- Amotekun àti Sọ́jà kú lásìkò tí wọn já ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo l‘Oyo - Makinde
O ni eebu lo n bu oun, ti ọpọ awọn ọmọ Yoruba to n gba nimọran si ti pọ ju lai mọ pe maa jo lọ, mo n wo ẹyin rẹ ni wọn n se fun.
Ooni ni sibẹ ọmọ ẹni kii se idi bẹbẹrẹ, ka fi ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomiran, sibẹ ọmọ oun si ni Sunday Igboho ati pe ẹya rẹ lo n ja fun.
Oriade naa ni ko seese ki eeyan kan soso maa ba ijọba ja nigba ti onitọun ko ni ohun ijagun ninu ile.
O ni ọpọ awọn eeyan to n ti Igboho lẹyin lo wa loke okun, ti ipo ti orilẹede Naijiria si wa n ka wọn lara nitori ọpọ wọn lo fẹ wa sile pada.
Ọba alaye naa wa ni suuru ni awọn yoo fi yanju gbogbo rẹ, ti Ọlọrun Olodumare yoo si gba fun wa ni Naijiria.