Sudan Coup: Mọ̀ si nípa ọ̀gágun Abdel Fattah al-Burhan tó darí ìdìtẹ̀gbàjọba ní Sudan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọgagun agba lorilẹede Sudan, Abdel Fattah al-Burhan ti ni awọn ologun gbajọba ki ogun abẹle ma ṣe waye ni Sudan.
Ọgagun al-Burhan to dari ifipa gbajọba naa ni oun yọ Olotu Ijọba, Abdalla Hamdok kuro ni ọọfisi rẹ lọ si ile fun anfaani ara rẹ ni, amọ o ti pada si ile bayii.
Awọn to fi ipa gbajọba naa gba agbegbe Khartoum, ti wọn si tun igbimọ ti awọn ologun gbe kalẹ lati pin agbara pẹlu wọn, ki ijọba tiwantiwa le pada si orilẹede naa.
- Olórí ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ tó ga jù ní Sudan, Ọ̀gágun Burhan ti kéde ìlú ò fararọ
- Àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò kọlu àwọn tó n ṣe ìwọ́de ní Sudan
- Sudan bẹ Ààrẹ Trump pé kó yọ ọ́ kúrò nínú àwọn orílẹ́-èdè agbésùnmọ̀mí
- Oun tí ẹ lè má mọ̀ nípa Omar al-Bashir, olórí Sudan ti wọ́n yọ nípò
- Àwọn ológun dojú ìjà kọ ara wọn ní Khartoum
Amọ ni bayii, ko ye ẹnikẹni bi ijọba tiwantiwa yoo ṣe gboro lorilẹede Sudan, lẹyin ifipagbajọba yii.
Ọgagun al-Burhan lo ti n ṣe adari igbimọ alakoso ologun ''Sovereign council'' ati adari ikọ ọmọogun ibẹ, ko to di pe o wa gba ijọba patapata ni Ọjọ Aje.
Ọgagun naa da igbimọ ijọba tiwantiwa ru, o fi panpẹ ọba mu Olotu Ijọba, Abdalla Hamdok ati awọn eekan ni ijọba ti awọn ologun ti gba lati pin ijọba pẹlu.
Ta ni Ọgagun General Abdel Fattah al-Burhan to gba ijọba ni Sudan:
Al-Burhan kii ṣe ẹni ti awọn eniyan mọ ki iditẹ gbajọba to yọ Aarẹ Omar Hassan al-Bassar kuro ni ipo to waye ni ọdun 2019.
Nigba naa lọun, oun ni ẹni kẹta to dagba ju ni ikọ ologun lẹyin Ọga agba awọn ologun.
Lẹyin iditẹ gbajọba naa ni minisita fun eto aabo fi ipo silẹ to si darukọ al-Burhan gẹgẹ bi ẹni ti yoo di igbimọ ologun ti yoo gbe ijọba ologun kalẹ fun ijọba tiwantiwa mu.

Oríṣun àwòrán, AFP
Oṣu Kẹjọ, ọdun 2019 ni wọn fi si ipo adari ikọ ''Sovereign council'' lorilẹede Sudan.
Bakan naa lo jẹ adari fun ikọ ologun Sudan to ja ninu ogun orilẹede Yemen ni ọdun 2015.
Lẹyin ti wọn gbajọba lọwọ Bahir ni Burhan ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ilẹ United Arab Emirate, Saudi Arabia ati Egypt.
Ni Oṣu Kẹta, ọdun yii lo gbalejo Aarẹ orilẹede Egypt, Abdel Fattah ai-Sisi ni Khartoum, lọna ati ṣiṣẹ pẹlu Sudan fun ibaṣepọ pẹlu Israel.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Wo ohun tí Yinka Alaseyori sọ nipa Tope Alabi ní àyájọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Darandaran kan rí ẹ̀wọ̀n gbéré he ní Ekiti
- Nǹkan yan! Pásítọ̀ dáwọn ọmọ ijọ̀ dùbúlẹ̀ lórí pẹ̀pẹ́, ó ń nà wọ́n pẹ̀lú bẹ́lítì
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tó lù ará rẹ ní gbanjo ₦20m ní Kano
- Bí ìgbẹ́jọ́ Naira Marley ṣe lọ lọ́jọ́ Iṣẹ́gun rèé
Ni Oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni Burhan ati Abdalla Hamdok to yọ ni ipo ni Ọjọ Aje ṣe ipade pọ pẹlu Olotu Ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ati Aarẹ orilẹede Amerika tẹlẹri, Donald Trump ti wọn jọ jiroro lori ọna ati jọ ṣiṣẹ papọ.
Bakan naa ni minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni ilẹ Amerika, Mike Pompeo dupẹ lọwọ rẹ nigba naa fun igbiyanju lati dọrẹ papọ pẹlu orilẹede Israel.
Ko tan sibẹ, Burhan jẹjẹ fun ileẹjọ to n gbẹjọ iwa ọdaran lagbaye, ICC pe oun yoo jọwọ al-Bashir fun wọn lati foju wina ofin, lori ẹsun ifiyajẹni ati iwa ọdaran ni agbagbe Darfur.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ, eto idajọ fun awọn eniyan agbegbe Darfur lo fa gbọnmi si omi o to laaarin awọn araalu ati ikọ ọmọogun.















