Sudan: Àwọn olórí Sudan bẹ Amẹrika pé kó yọ ọ́ kúrò nínú àwọn orílẹ́-èdè agbésùnmọ̀mí

Omar al-Bashir
Àkọlé àwòrán, Àwọn olórí Sudan bẹ Amẹrika pé kó yọ ọ́ kúrò nínú àwọn orílẹ́-èdè agbésùnmọ̀mí

Awọn olori ilẹ Sudan ti kepe Aarẹ Donald Trump ilẹ Amẹrika pe wi pe ko yọ orukọ orilẹ-ede naa kuro ninu awọn orilẹ-ede to n ṣatilẹyin fun igbesunmọmi.

Awọn eeyan ọhun ti oloṣelu, awọn olukọ ile iwe giga atawọn ajafẹtọ wa lara wọn sọ ninu iwe ti wọn kọ si Aarẹ Trump pe ko bojumu ki gbogbo eeyan orilẹ-ede Sudan maa jiya ẹṣẹ ti aarẹ ana ilẹ naa, Omar Al-Bashir ṣẹ.

Ninu ọdun 2019 yii naa ni wọn gba ijọba lọwọ Al-Bashir lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ nitori ifẹhonu to waye kaakiri orilẹ-ede naa.

Lọdun 1993 ni ilẹ Amẹrika fi orukọ Sudan si ara awọn orilẹ-ede to n gbaruku ti igbesunmọmi lori ẹsun pe orilẹ-ede Sudan n ṣatilẹyin fun awọn alakatakiti ẹsin.

Àkọlé fídíò, Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí kọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́ka fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas

Olori ẹgbẹ Al-Qa'eda to ti di oloogbe bayii, Osama Bin Laden atawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ wa lorilẹ-ede Sudan lasiko naa.

Awọn to fọwọ siwe naa ni ki America fiye denu nitori pe gbogbo ọmọ Sudan kọ ni alakatakiti ẹsin Islam.

Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo, Sara Abdigalil, to jẹ ọkan lara eeyan mọkandinlọgọrin to buwọ luwe ti wọn fi ṣọwọ si aarẹ Amẹrika, ṣalaye fun BBC pe ote ti ilẹ Amẹrika fi le Sudan n ṣakoba fun ọrọ aje orilẹ-ede ọhun.

Abdigalil ni nnkan ti yatọ si ti tẹlẹ lorilẹ-ede Sudan bayii lẹyin ti ijọba Al-Bashir ti wo.