OAU Aishat Adesina : Àwọn aláṣẹ fásitì OAU ṣí iléèwé náà padà lẹ́yìn ikú akẹ́kọ̀ọ́, Aishat Adesina tó fa ìfẹ̀hónúhàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ ileẹkọ fasiti ile iwe giga Obafemi Awolowo, Ile-Ife, ti kede pe awọn ti ṣi ileewe pada lẹyin ọjọ mejidinlọgbọn ti wọn ti i pa.
Eyi ko ṣẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ lẹyin ifẹhonuhan ti awọn akẹkọọ gunle ni Ọjọ Kini, Osu Kẹwaa, ọdun 2021.
Ohun to fa ifẹhonuhan naa ni pe akẹkọọ jade ni fasiti ọhun ni ẹka imọ Ede ilẹ okeere, Aishat Adesina lo papoda lẹyin to ṣe aisan ti awọn akẹkọọ si ni ileewosan ileẹkọ naa ko naa ni ilera awọn eniyan.
- Iléẹ̀kọ́ fásitì OAU dí títì pa lórí akẹ́kọ̀ọ́ tó gbẹ́mìí mì ní iléwòsàn fásitì
- ‘Lóòótọ́ ni ọ̀jọ̀gbọ́n fẹ́ bá mi lòpọ̀’
- Afurasí Sọ́jà kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ TASUED, ìwọ́de gbòde l'Ọ́jọ́bọ̀
- A kò ní gbà kí Buhari yá $700m fi pèsè omi fún aráàlú - Ilé Aṣòfin
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó fẹ́ da ìdánwò rú
- Ilé ẹjọ́ ṣẹ́ eegun ẹ̀yìn Oluwo lórí yíyan Grand Mufti Yorùbá, àmọ́ Oluwo ní òun yóo fi oyè náà jẹ dandan
Awọn akẹkọọ naa n mura fun idanwo lasiko ti ifẹhonuhan naa bẹrẹ, eleyii to mu ki idanwo naa ni ifaṣẹyin.

Oríṣun àwòrán, OFFICIALOAU
Ninu atẹjade ti alukoro ileẹkọ naa gbe jade, Abiodun Olanrewaju ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn adari ileẹkọ naa ṣepade ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Kẹwaa, ọdun 2021.
Olanrewaju ni awn akẹkọọ yoo pade si ileewe naa ni Ọjọ Karun un, Osu Kọkanla, ọdun 2021 lati tẹsiwaju ninu idanwo naa ti yoo bẹrẹ pada ni Ọjọ Kẹfa, Osu Kẹfa, ọdun 2021.

Bakan naa ni wọn kesi awọn obi lati fi to awn ọmọ wọn leti ki wọn wa pari idanwo wọn.
Amọ awọn ti o ba ti pari idanwo ko nilo lati wa si ileẹkọ naa, ki wọn wa fa rogbodiyan ni ileẹkọ naa.













