Banditry in Nigeria: Lai Muhammed ní torí pé agbébọn ń gbowó ilẹ̀ ní Ariwa, kò túmọ̀ pé wọn ti gba àkóso

An janduku agbebọn

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Minisita ọrọ iroyin ati aṣa ni Naijiria, Lai Mohammed ti sọ pe awọn janduku agbebọn to n gba owo lọwọ araalu lapa Ariwa, ko tumọ si pe wọn ti gba ijọba.

Mohammed sọrọ yii nigba to fesi si iroyin kan ti iwe iroyin Economist Magazine kọ niluu London pe ''Afaimọ kawọn agbesunmọmi, awọn to n pe fun iyapa atawọn agbebọn ma doju Naijiria bolẹ."

Minisita ni o ṣe ilodi bi iwe iroyin Economist ṣe sọ pe awọn agbesunmọmi ti ṣe agbekalẹ ijọba wọn lapa ila oorun ariwa Naijiria.

"N jẹ ẹ mọ pe apa ariwa Naijiria nikan kọ ni gbigba owo ilẹ ti n ṣẹlẹ?

Wọn wa lapa guusu Naijiria naa, koda ọmọ ita tabi agbero tawọn oloyinbo n pe ni ''area boys'' ni ọpọ mọ wọn si.

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Iyẹn ko dẹ tumọ si pe awọn agbebọn tabi agbesunmọmi n ṣọṣẹ nibẹ.

Mi o kan fẹ darukọ ni, awọn agbero ni ibudo wọn lawọn ilu nla ni Naijiria nibi ti wọn ti n gbowo ilẹ.

Eleyii ko tumọ si pe wọn ti gba ijọba tabi wọn da ijọba ti wọn ni lawọn ilu ti wọn wa,'' Mohamed ṣalaye.

Minisita eto iroyin ati ọrọ aṣa rọ awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria pe ki wọn ye maa gbe iroyin ti tawọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere gbe jade lai ṣe ayẹwo rẹ.

O sọ siwaju pe ẹka iwe iroyin Ecomist Magazine tii ṣe The Economist Intelligence Unit sọ pe Atiku Abubakar ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo wọle ibo aarẹ lọdun 2015.

Amọ ko ri bẹẹ nitrori Aarẹ Muhammadu Buhari lo wọle ẹlẹẹkeji pẹlu ibo to le ni miliọnu mẹta.

Ọgbẹni Mohamed ni eleyii fihan pe iwe iroyin Economist Magazine le ṣe aṣiṣe.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Minisita ni ko boju mu bi awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria ṣe n bẹ mọ iroyin to jade ninu iwe iroyin ilẹ okeere lai ṣe ayẹwo fini fini ohun ti iroyin naa da le lori.

Mohamed ni kii ṣe asiko tawọn Boko Haram n jọwọ ara wọn pe awọn ko ja mọ lo yẹ ki iwe iroyin Economist maa sọ pe awọn agbesunmọmi ti ni ijọba ti ara wọn lapa ariwa Naijiria.