APC Oyo Primaries: Àwọn aṣaájú ké gbàjaré pé ìbò abẹ́nú APC Oyo tó kọjá mẹ́hẹ

Ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo waye ni ọjọ Satide, tawọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ tuntun si fi oju han.
Amọ sibẹ, ọrọ si ku lori abọ ipade idibo abẹnu naa nitori awọn igun kan ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti n fi apa janu, ti wọn si kọ esi idibo ọhun.
Alaga ẹgbẹ oṣelu naa to n fi ipo silẹ, Oloye Akin Ọkẹ ṣalaye pe itọsẹ lo lọyọ, o ye ki wọn ṣe ohun gbogbo bo ṣe tọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
- Oyinlola kí Arapaja kú orííre bó ṣe borí ìbò igbákejì alága PDP fún ẹkùn Gúúsù
- Kí ló mú Lizzy Anjorin ṣe àyẹ̀wò DNA ọmọ rẹ̀?
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ohun tó gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari lọ́jọ́ Àìkú rèé - Tinubu
- Ọwọ́ tẹ èèyàn mẹ́ta tó gbé òògùn olóró sínú ọṣẹ dúdú
- Agbébọn kọlu ṣọ́ọ́ṣì, èèyàn méjì kú, wọ́n kó ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn lọ
Oloye Ọkẹ ni aifẹ tẹle ilana tawọn babanla ẹgbẹ naa fi lelẹ ni ipilẹ ẹgbẹ oṣelu naa, lo n fa gbogbo dukuu laarin ẹgbẹ naa.
O ni ohun to ku diẹ kaato ni lati rii pe awọn eeyan kan lẹgbẹ oṣelu APC gbimọ pọ lati mu ayederu orukọ wọ inu iwe orukọ awọn aṣoju idibo to yẹ ko farahan nibi ipade idibo yan adari, congress, to waye ni ipinlẹ Ọyọ.
O ni gbogbo awọn to wa gẹgẹ bi ọmọ igbimọ kokari eto idibo naa ni wọn fọwọsi pe ki wọn ṣe ohun gbogbo bo ṣe tọ.
O fi kun pe ibẹru awọn eekan ẹgbẹ naa gbogbo ṣaaju eto idibo naa ni pe, awọn eeyan kan ti tọwọ bọ iwe orukọ awọn aṣojudibo l'Eko ati l'Abuja.
O ni bo tilẹ jẹ pe awọn awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa ko gba eyi gbọ nigba naa, eleyi to mu ki wọn beere fun iwe orukọ ti wọn yoo lo fun idibo naa lọjọ Ẹti.
Amọṣa, iyalẹnu lo jẹ lati rii pe ọpọ asawọ lo ti wọ inu iwe orukọ naa, gẹgẹ bi Oloye Akin Ọkẹ ṣe sọ fun BBC News Yoruba.
Awọn eeyan perete to se mọkaruru lo fẹ tu ẹ́gbẹ́ ka - Sunday Dare
Ẹwẹ, minisita fun ere idaraya, Sunday Dare ti oun pẹlu ti fi ẹhonu han lori igbesẹ naa ni awọn eeyan perete kan ni wọn fẹ fi tipatipa ja ẹgbẹ oṣelu naa gba mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lọwọ ni ipinlẹ Ọyọ.
Ninu atẹjade kan to n lọ kaakiri awọn iwe iroyin abẹle ni Naijiria, Sunday Dare ṣalaye pe awọn to wa nidi eto naa n wa ọna lati tu ẹgbẹ naa ka ni.
Igbesẹ awọn iwọnba perete lati ja ẹgbẹ oṣelu yii gba ko ni jọ. Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lo duro lori idagbasoke rẹ.
Lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa to n tako eto naa bayii ni alaga ajọ feto ibaraẹnisọrọ (NCC), Ọjọgbọn Adeolu Akande ati oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nigba kan ri, Oloye Olasunkanmi Tegbe.
Awọn yoku ni oludije gomina to kọja nipinlẹ Ọyọ, Oloye Adebayo Adelabu; Olagunju Ojo; Fatai Ibikunle ati Ọmọọba Ayodeji Abass-Aleshinloye.
Awọn yoku ni Oloye Sarafadeen Alli, to figbakan ri jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Oyo atawọn eekan ẹgbẹ APC miran.
A n reti igbesẹ ti igbimọ apapọ ẹgbẹ APC yoo gbe - Olaoya
Amọṣa, nigba ti BBC News Yoruba kan si awọn ọmọ igbimọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan naa, Ọgbẹni Mojeed Ọlaọya, ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii alaga fun ẹkun idibo gusu ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe ko si kalọkabọ kankan lori ọrọ yii.
O ni ohun ti awọn n fẹ ni pe ki igbimọ apapọ ẹgbẹ naa da si aawọ naa lọ, igbesẹ wọn si lawọn n reti lọwọ.
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
Amọṣa, alaga to n fipo silẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Oloye Akin Ọkẹ rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ lati ṣe suuru, ki wọn fi wa ojuutu si ọrọ ọhun.
Bakan naa lo ke si Ọgbẹni Ọmọdewu ti wọn ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu naa, lati ṣe pẹlẹ ko si duro naa "nitori nigba ti alaafia ba wa leyan lee sọ pe oun n ṣe alaga."

Ìdìbò abẹ́nú APC Oyo pàpà wáyé lẹ́yìn tí jàǹdùkú mú alága ìbò abẹ́nú nígbèkùn

Ipade idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo waye ni ọjọ Satide, tawọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ tuntun si fi oju han.
Amọ sibẹ, ọrọ si ku lori abọ ipade idibo abẹnu naa nitori awọn igun kan ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti n fi apa janu, ti wọn si kọ esi idibo ọhun.
Ipade idibo naa, ti Gambo Lawan se alaga fun lo waye ni papa Liberty nilu Ibadan, ti iroyin si ni awọn janduku kan tilẹkun mọ alaga naa lati aago meje aarọ, ti ko si le peju sibi ti ipade ọhun ti waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun?
- Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tí a rí gbọ́ nípa rẹ̀ nìyí
- Wo ọ̀nà tí o lè gbà borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa ọ̀gọ̀rọ̀ lágbáyé
- Omi ìdọ̀tí atí ''biscuit'' la jẹ fún ọjọ́ méje - Àwọn àgùnbánírọ̀ sọ ìrírí wọ́n lọ́wọ́ ajínígbé
- Wo bí àwọn agbófinró ṣe ya bo ilé Onídájọ́ Mary Odili pẹ̀lú àwọn ohun tuntun tó súyọ
- Iléẹ̀kọ́ fásitì OAU ṣí padà lẹ́yìn ikú akẹ́kọ̀ọ́, Aishat Adesina tó fa ìfẹ̀hónúhàn
- A kò ní gbà kí Buhari yá $700m fi pèsè omi fún aráàlú - Ilé Aṣòfin
Awọn janduku naa si lo sọ fun Gambo pe ko ni ri ọna lọ ayafi to ba kede pe oun ti wọgile idibo abẹnu naa, ti ko si ni waye mọ.
Koda, ni ibẹrẹ eto naa ni awọn igun kan ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo ti ni ki wọn wọgile idibo abẹnu naa nitori oniruuru orukọ awọn oludibo to jẹ ayederu lo ti jade sita.
Igba keji si ree ti wọn yoo sun eto idibo naa siwaju, ti wahala si tun fẹ bẹ silẹ ni igba kẹta.
Awọn igun to n fi apa janu naa, ti wọn tilẹkun mọ Gambo lati jẹ ko ri ọna de ibi ipade naa ni ko mọ pe akọwe igbimọ to n se kokari ibo ọhun, atawọn ọmọ igbimọ naa kan, ti de ibudo ti idibo naa yoo ti waye.
Awọn agbofin tu Gambo silẹ ni ahamọ ni aago meje alẹ:
Nigba to n fi idi isẹlẹ yii mulẹ lori eto ori redio kan nilu Ibadan, Gambo ni o ya oun lẹnu pe awọn eekan kan ninu ẹgbẹ oselu naa le ran awọn janduku lati wa fa ọwọ aago ibo naa sẹyin.
A gbọ pe gbogbo aayan gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Adebayo Alao Akala lati yọ Gambo ninu ahamọ tipa ti wọn fi si naa lo ja si pabo.
Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa, Civil Defence ati DSS lo jẹ ki Gambo gba idande ni aago meje alẹ lẹyin ti idibo ti pari tan.
Isaac Omodewu di alaga ẹgbẹ APC ni Oyo:
Amọ lẹyin abọ idibo to waye lasiko ipade apapọ ẹgbẹ APC naa, Isaac Omodewu, tii se Kọmisana tẹlẹ labẹ ijọba Ajimobi ni wọn kede pe o jawe olubori bii alaga ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo.
Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Omodewu rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa lati gba alafia laaye, ki wọn fi ọwọ wọnu, ki wọn si pa imọ pọ lati mu ki ẹgbẹ naa de ibi giga.
O wa dupẹ lọwọ awọn asaaju ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo fun atilẹyin wọn, to si fi ọwọ gbaya pe oun yoo pari ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to n fi apa janu.

Awọn igun kan n ki alaga tuntun ku oriire:
Awọn igun ti Unity Forum, Ajimobi Legacy, Zenity Labour Party ati Oloye Adeniyi Akintola si lo ti ki alaga tuntun fun ẹgbẹ naa ku oriire.
Atẹjade kan ti Sẹnatọ Ayoade Adeseun, Oloye Sarafa Alli, Amofin Ayo Ojeniyi ati Asofin Tolu Sadipe dijọ fi ọwọ si wa kan saara si awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun bi wọn se se ojuse wọn nilana isejọba awa ara wa.
Bakan naa ni wọn yonbo wọn fun bi wsn ko se gba ki alaga ipade idibo abẹnu naa dari idibo mọkaruru, eyi to mu mẹrin ninu awọn ọmọ igbimọ alako ipade naa kọwe fipo silẹ.
Wayi o, awọn igun ẹgbẹ oselu APC ti inu n bi ti n fi apa janu lori esi idibo abẹnu naa nibi ti Isaac Omodewu ti jawe olubori bii alaga ẹgbẹ.






















