Lagos Airport: Ẹ wo bí ọwọ́ ṣe tẹ àwọn mẹ́ta tó gbé òògùn olóró sínú ọṣẹ dúdú ní pápákò òfúrufú Eko

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ to n gbogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA, ti ni oun ti gba oogun oloro ti awọn eniyan kan n gbe lọ si ilu London lati papakọ ofurufu ni ipinlẹ Eko.
Adari ẹka eto iroyin fajọ NDLEA, Femi Babafemi lo fi iroyin naa lede fun awọn akọroyin ni ilu Abuja .
Ajọ osisẹ ajọ NDLEA ni awọn ri awọn oogun oloro yii lasiko ti awọn n ṣe ayẹwo papakọ ofurufu ati awọn ẹru ti wọn n ko lọ silẹ okeere, ni awọn sawari awọn oogun oloro ti wọn ko si inu oṣẹ dudu naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ohun tó gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari lọ́jọ́ Àìkú rèé - Tinubu
- Agbébọn kọlu ṣọ́ọ́ṣì, èèyàn méjì kú, wọ́n kó ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn lọ
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
- Iyorchia Ayu dí Alágá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn ọmọ ìgbimọ̀ tó kù rè é
- Òjò owó àti ẹbùn ń rọ fún Iyabo Ojo fún ayẹyẹ ọdún kan ikú ìyà rẹ
O ni awọn oogun oloro ti wọn ri naa ni oogun oloro cocaine, heroin, methamphetamine ati Indian hemp pẹlu awọn oogun oloro ti wọn ri.
Babafemi ni oogun oloro cocaine naa ni wọn gbe sinu paali ike ọṣẹ dudu, ti awọn ri nigba ti wọn n gbe awọn ẹru sinu ọkọ.
Bakan naa ni heroin ati Methamphetamine ni wọn di pamọ si inu paali ọṣẹ dudu mẹtalelogun, ti paali mọkandinlogoji miran si wa ninu paali Dudu-Osun ti wọn ko wọn pamọ si.

Oríṣun àwòrán, Others
Babafemi ni awọn ri cargo miran to gbe oogun oloro indian hemp ti wọn gbe si inu paali Dudu Osun naa ni, awọn ri ni ibi ti wọn di wọn pamọ si.
Ajọ NDLEA ni o kere tan, awọn ti mu afurasi mẹta to nii se pẹlu iṣẹlẹ naa, ti iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Laipẹ yii ni ọwọ tẹ abiyamọ kan to n tọ ọmọ lọwọ to si ni oun wa ni fasiti Benin, Mariam Dirisu to gbe oogun oloro Skunk ati Molly.
Ajọ NDLEA ni wọn ṣẹṣẹ fi obinrin naa silẹ lẹyin to gbe oogun oloro si inu fufu ti wọn n pe ni ''akpu'', to si fẹ lọ gbe fun afurasi onibara rẹ to wa ni panpẹ ajọ NDLEA.

















