PDP 2021 Convention: Seyi Makinde ní kìí ṣe àtìlẹ́yìn òun nìkan ló gbé Arapaja wọlé

Gomina ipinlẹ, Seyi Makinde ti sọ pe kii ṣe atilẹyin oun nikan lo gbe Taofik Arapaja wọle gẹgẹ bii igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni iha Guusu Naijiria.
Agbenusọ gomina ọhun, Taiwo Adisa lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, yatọ si Makinde, nnkan bii ẹgbẹrun meji ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo kin Arapaja lẹyin lati de ipo igbakeji alaga naa.
O ni "Kii ṣe gomina nikan lo ṣagbatẹru Arapaja, gẹgẹ bii ẹyin naa ṣe ri pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣe agbatẹru rẹ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ọ̀pọ̀ ajìjàgbara Yorùbá Nation ló ń tan aráàlú jẹ láì sọ òtítọ́ - Seyi Makinde
- Kí ló mú Lizzy Anjorin ṣe àyẹ̀wò DNA ọmọ rẹ̀?
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ohun tó gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari lọ́jọ́ Àìkú rèé - Tinubu
- Ọwọ́ tẹ èèyàn mẹ́ta tó gbé òògùn olóró sínú ọṣẹ dúdú
- Agbébọn kọlu ṣọ́ọ́ṣì, èèyàn méjì kú, wọ́n kó ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn lọ
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
"Ti ẹ ba wo iye ibo ipinlẹ Oyo ninu eyii to gbe Arapaja wọle, ko ju bii igba lọ, nigba to jẹ pe ibo to le ni ẹgbẹrun meji lo gbe Arapaja wọle, awọn oloṣelu lati iha Ariwa, to fi mọ Guusu Naijiria lo ṣatilẹyin fun."
Adisa tẹsiwaju pe inu gomina ipinlẹ Oyo dun lori esi ibo naa, paapaa nitori ko si ija laarin awọn oludibo, gbogbo ọmọ ẹgḅẹ lo si faramọ esi ibo ọhun.
Ni ti họwu-họwu to n waye ninu ẹgḅẹ naa ni ipinlẹ Oyo, Adisa sọ pe ko si ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ PDP l'Oyo.
O ni "Ti ẹ ba sọ pe ọrọ ẹgbẹ oṣelu PDP ko gun rege ni ipinlẹ Oyo, ko fẹ ẹ jẹ ootọ lọ titi nitori pe ẹgbẹ PDP ni Oyo gun rege."
"Kii sẹ gbogbo igba ni ẹnu awọn eeyan yoo ko ninu ẹgbẹ ti ọpọ ero ba wa, ṣugbọn ohun to ṣe pataki ni pe ẹnu gbogbo wa kò ninu ẹgbẹ lori ọrọ itẹsiwaju."
Adisa sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti ṣetan lati gbajọba lọdun 2023, ẹgbẹ naa yoo si tun Naijiria ṣe yatọ si bi nnkan ṣe dẹnu kọlẹ lasiko ijọba ẹgbe APC to wa lode.
O pari ọrọ rẹ pe ko si atunṣe kankan ti ẹgbẹ oṣelu APC mu ba Naijiria, kaka ki ilọsiwaju waye, ni ṣe ni ara n ni awọn araalu lasiko ijọba naa, ẹgbẹ awọn si ni ọna si awọn iṣoro ti Naijiria n dojukọ.
Ẹwẹ, alatako Arapaja ninu eto idibo naa, to tun jẹ gomina ipinlẹ Osun nigba kan ri, Olagunsoye Oyinlola ti ki awọn adari tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ninu ẹgbẹ naa ku oriire.
Ninu atẹjade kan to fi lede niluu Osogbo, Oyinlola sọ pe oun ti fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si Arapaja lori ipo tuntun naa ati lati fun ni atilẹyin to jọju.
Ọgbọn ọjọ ati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii eto idibo ẹgbẹ naa waye ni gbagede Eagles Squre niluu Abuja.

Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku

Oríṣun àwòrán, Instagram/aatiku
Igbakeji aarẹ tẹlẹri ni Naijiria Atiku Abubakar, ti bẹnu atẹ lu ẹgbẹ to wa lori aga akosoAPC, pe wọn ko ṣetan lati ṣakoso ilẹ yii lọdun 2015 ti agbara bọ si wọn lọwọ.
Atiku ni ẹgbẹ toun jẹ ọkan lara wọn nisinyi, PDP nikan lo le da ogo Naijiria pada ati pe aṣeyọri PDP, aṣeyọri gbogbo Naijiria ni.
Lasiko ti wọn ṣe ipade idibo abẹnu lati yan awọn oludari ẹgbẹ Peoples Demoicratic Party lAbuja lo sọ bẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
- Iyorchia Ayu dí Alágá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn ọmọ ìgbimọ̀ tó kù rè é
- Òjò owó àti ẹbùn ń rọ fún Iyabo Ojo fún ayẹyẹ ọdún kan ikú ìyà rẹ
- Ayẹyẹ ìwúyè Grand Mufti wáyé ní Iwo, ọ̀pọ̀ adarí ẹ̀sìn Islam péjú
- Ìdìbò abẹ́nú APC Oyo pàpà wáyé lẹ́yìn tí jàǹdùkú mú alága ìbò abẹ́nú nígbèkùn
- Agbébọn ṣe ń gba owò ilẹ̀ ní Ariwa, agbèrò ń gbà ní gúúsù, kò sí ìyàtọ̀ - Lai Muhammed
- Ìjíròrò tó wáyé láàrín Bola Tinubu àti Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo, ohun tí a rí gbọ́ nípa rẹ̀ nìyí
- Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun?
- Wo ọ̀nà tí o lè gbà borí àìsàn rọpá-rọṣẹ̀ tó ń pa ọ̀gọ̀rọ̀ lágbáyé
Lọdun 2015 ti Atiku n sọ yii, o jẹ ọkan lara awọn to dije dupo lati ṣoju ẹgbẹ PDP ninu idibo aarẹ ṣugbọn o pade ijakulẹ sọwọ Muhammadu Buhari.
Amọ bayi to ti pada si ẹgbẹ ipilẹ rẹ, tii ṣe PDP, Atiku ni orita koyemimọ ni Naijiria wa bayi to si kesi gbogbo awọn oloṣelu lati pawọ pọ ṣagbega rẹ.
O ni ''APC ti fi han pe awọn ko kajuẹ lati ṣakoso Naijiria. Wọn ti fojuhan pe awọn lo kun fun iwa ajẹbanu julọ''
O tẹsiwaju pe ''APC ni ẹgbẹ ẹlẹyamẹya to wa lati tubọ mu ipinya ba Naijiria. Wọn ko ṣetan lati tukọ orilẹede yii rara''
Atiku ko ṣẹṣẹ maa sọ iru ọrọ yii paapa nipa awọn ijọba to baa n gbero lati yẹ aga nidi wọn.
Bi o ba kopa ninu eto idibo ọdun 2023 to n bọ, yoo ni lati kọkọ gba iyọnda awọn ọmọ ẹgbẹ PDP gẹgẹ bi oludije ipo aarẹ.
Awọn ti yoo dijọ figa gbaga fun ipo naa ko joko lai ṣe pe awọn naa n gbiyanju lati ri ẹyọnu ọmọ ẹgbẹ, paapa lasiko yii ti ija n ṣẹlẹ laarin igun orisi ninu ẹgbẹ PDP naa.





















