Seyi Makinde: Àtúntò Nàíjíríà nìkan lọ̀nà àbáyọ, kìí ṣe ìpè fún ìyapa
Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti woye pe ko yẹ ki awọn eeyan to n ja fun iyapa Naijiria ati agbekalẹ orilẹede Yoruba Nation maa tapa si ofin ilẹ wa.
Gomina Makinde woye ọrọ yii lasiko to kopa lori akanse ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba.
Makinde ni ọpọ awọn eeyan to n pe fun Yoruba Nation, eyi ti Oloye Sunday Igboho ko sodi, ni wọn ko ri ogun ri.
- Gani Adams àti Seyi Makinde ṣèpàdé, àbọ̀ wọn rèé
- Àṣìgbé ọmọ wọ́ọ̀dù ni Seyi Makinde - Àgbààgbà PDP l‘Oyo ka ẹ̀sùn sí gómìnà l'ẹ́sẹ̀
- Mo gbádùn bí wọ́n ṣe ń pè mí ní ''audio governor''- Seyi Makinde
- Seyi Makinde pe olóyè PDP lẹ́jọ̀ fún ìbanilórúkọ jẹ́ lórí Facebook
- 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìnì fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'
- Mo gbádùn bí wọ́n ṣe ń pè mí ní ''audio governor''- Seyi Makinde
"A ko le tapa si ofin Naijiria nitori pe a fẹ fi ẹhonu han, awọn ofin wa ta gbọdọ tẹle lori awọn igbesẹ wa.
Ọpọ awọn eeyan yii, to n pe fun iyapa Naijiria ni ogun ko se oju wọn ri, o si yẹ ko ye wọn pe wọn kan le mọ ibẹrẹ ogun, wọn le ma mọ igbẹyin rẹ.
Awọn baba nla wa to se idasilẹ Naijiria mọ ohun ti wọn fi sun, ori bibẹ si kọ ni oogun fun ori fifọ."
Gomina Makinde ni ọpọ awọn ajijagbara yii lo ti tan awọn eeyan jẹ to pọ nipa idi ti wọn se n pe fun iyapa Naijiria, ti ọpọ eeyan ko si mọ otitọ to wa nidi igbesẹ wọn.
O wa fi ọwọ gbaya pe ilana atunto ni a nilo lorilẹede Naijiria, nibi ti gbogbo wa yoo ti joko sọrọ nipa ọjọ ọla ati atunse ilẹ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
- Ẹ wò àsọtẹlẹ tí Odumakin sọ nípa ìbejì tí ìyàwó rẹ̀ bí loṣù mẹ́fà tó jáde láyé
- Ohun tó gbé mi lọ sọ́dọ̀ Buhari lọ́jọ́ Àìkú rèé - Tinubu
- Ọwọ́ tẹ èèyàn mẹ́ta tó gbé òògùn olóró sínú ọṣẹ dúdú
- Agbébọn kọlu ṣọ́ọ́ṣì, èèyàn méjì kú, wọ́n kó ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn lọ
- Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
- Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
- Ó ṣèèsì bọ́ sí wọ́n lọ́wọ́ ní, APC kò ṣetán láti ṣe àkóso ìjọba ní 2015 - Atiku
- Má ṣé wàhálà wàásù fún mi, mo ti yọ ìdájọ́ ọ̀run kúrò lọ́rọ̀ mi - Bobrisky
"Anfaani wa fun gbogbo wa pe ka dijọ joko sọrọ papọ, ka le mọ ibi ti wahala wa ti bẹrẹ ati ọna abayọ."
Nigba to n sọrọ lori awọn igbesẹ to n gbe ti aabo to peye yoo fi wa nipinlẹ Oyo, Makinde ni oun ti fi owo to lookọ si ẹka eto aabo, to si n so eso rere.
Bakan naa lo ni ni saa isejọba oun ni oun se agbekalẹ ikọ alaabo Amotekun eyi to n sisẹ takuntakun lati pese eto aabo to mọyan lori yika ipinlẹ Oyo.
"O yẹ ka maa dupẹ fun ipo ti eto aabo wa nipinlẹ Oyo ni, ta ba fi we bi eto aabo se mẹhẹ lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.
Lootọ ni ipo ti ko dara ti eto aabo wa ni Naijiria n kọ ọpọ eeyan lominu amọ mo ti na owo nla lati pese eto aabo to peye yika ipinlẹ Oyo.
Mo ra ọpọ ọkọ isẹ fawọn ileesẹ agbofinro lorisi lorisi lati maa fi paraaro kaakiri ipinlẹ yii, ti ifọwọsowọpọ si wa laarin awọn ileesẹ agbofinro naa."
Gomina Seyi Makinde tun wa sọrọ nipa aayan to ti se lori eto ẹkọ, atunse oju popo yika ipinlẹ Oyo ati ipese eto ilera to yanranti fawọn eeyan ipinlẹ naa.






















