Oyo PDP: Ẹgbẹ́ alábùradà pín sí méjì, igun kan ta kété sí Seyi Makinde

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Instagram/seyi_amakinde

O dabi ẹni pe ipilẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ọyọ ti n mì bayii, to si ṣe e ṣe ki ẹgbẹ naa o tuka, pin kelekele.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn agbaagba ẹgbẹ kan ṣe kede pe, awọn ti da ẹgbẹ osẹlu naa si meji, abala kan fun Gomina Seyi Makinde, ati abala keji fun awọn to fẹ ilọsiwaju ẹgbẹ.

Nibi ipade kan ti wọn ṣe ni ilu Ibadan ni wọn ti kede pe inu awọn ko dun si bi Makinde ṣe n ṣe akoso ẹgbẹ naa.

Oriṣiriṣi awọn ẹsun ati aṣemaṣe si ni wọn fi ka si gomina lẹsẹ.

Lasiko to ba BBC sọrọ lori igbesẹ wọn, ọkan lara awọn agba ẹgbẹ naa to yapa, Alhaji Nureni Adebayo Akanbi sọ pe aṣiyan patapata ni gomina Seyi Makinde jẹ fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

Kinni wọn sọ pe Gomina Makinde ṣe?

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si gomina lẹsẹ ni pe:

  • Ko ṣe ojuṣe rẹ to lori eto aabo ni ipinlẹ Ọyọ
  • Wọn ni awọn ti kii sẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ni Makinde n yan si ipo ninu ijọba rẹ, tako awọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu naa to fi ara ṣiṣẹ ki PDP to pada si iṣakoso ni ipinlẹ Ọyọ lẹyin ọdun mẹjọ
  • Wọn ni gomina fi ipo alaga ijọba ibilẹ mẹrin, ati kanselọ mejidinlaadọta ta awọn ọrẹ rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC lọrẹ, lasiko idibo ijọba ibilẹ to waye laipẹ yii.
  • Makinde ko tun bọwọ tabi naani ẹni ti wọn yan ni igbakeji rẹ. Alagba Akanbi sọ pe igbakeji gomina Makinde, Rauf Olaniyan, kan wa nibẹ bi ẹṣin inu iwe ni.
  • Ati pe gomina kii fun ni ohunkohun gẹgẹ bi ẹtọ, bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ẹgbẹ Makinde.
  • O ni lati ọjọ ti awọn ti gba ijọba le lọwọ, ni Makinde ti bẹrẹ iwa afojudi.
  • Bakan naa lo sọ pe lootọ ni adehun wa laarin ẹgbẹ PDP ati Makinde ṣaaju idibo, amọ o ni ko si adehun to mu ṣẹ.

A gba ẹgbẹ PDP Oyo lọwọ Makinde, yoo mọ pe ẹgbẹ lo ni ijọba - Akanbi

Nigba ti a beere pe iru ibawi wo ni ẹgbẹ la kalẹ fun gomina ti ko ba ṣe nkan ti ẹgbẹ n fẹ, Alhaji Akanbi sọ pe ko si ẹnikẹni ti gomina bẹru ninu ẹgbẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ṣugbọn, nigba ti a ba gba ẹgbẹ lọwọ rẹ, yoo mọ pe ẹgbẹ lo ni ijọba, ati pe ayalegbe ni ti ko si le gba ile mọ onile lọwọ.

Lara nkan ti wọn tun fi kan Makinde gẹgẹ bi ẹsun ni pe, o ni oun ko ni baba isalẹ kankan, eyi ti wọn lo tumọ si pe ko ni onibawii tabi ẹni ti wọn le fi ẹjọ rẹ sun.

O fikun pe aimọye igba ni awọn agbaagba ẹgbẹ naa ni Naijiria ti pe Makinde si akiyesi, amọ tinu rẹ lo n ṣe.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Kini awọn ọmọ ẹgbẹ to faramọ Gomina Makinde n sọ?

Yoruba sọ pe ko ni i buru titi ko ma ku ẹnikan mọ ni, amọ ẹni ti yoo ku lao mọ.

Ẹni to jẹ Akọwe ipolongo fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Akeem Olatunji sọ fun BBC pe ko si nkan to jọ iyapa ninu ẹgbẹ naa.

O ni awọn kan lo kan ko ara wọn jọ lati sọ nkan to wu wọn, amọ ti kii se nkan ti ẹgbẹ fẹ.

"Lootọ ni ko si ẹni to pé, ṣugbọn Seyi Makinde n ṣe nkan ti ẹgbẹ n fẹ."

Tako nkan ti Alhaji Nureni Akanbi sọ pe gomina fi ipo alaga ijọba ibilẹ tọrẹ fun awọn ọrẹ rẹ lasiko idibo to kọja, Ọgbẹni Olatunji sọ pe ko si nkan to jọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Alakuko/Elega Schools: Aráàlú ní olùkọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ti sá ní kíláàsì tí kò dára

Ati pe kii se ẹgbẹ oṣelu PDP nikan ni ipo tọ si. O ni "bi awọn ẹgbẹ miran ṣe rọwọ mu ninu eto idibo naa fihan pe, ijọba Ọyọ n ṣe eto osẹlu bo se yẹ.

Bakan naa lo ṣalaye pe, awọn to n sọ pe awọn ti pin ẹgbẹ si meji ni erongba ati eto to tako ti ẹgbẹ ni, to si jẹ pe ilana ẹgbẹ ni Makinde n tẹle, nitori pe ifẹ araalu lo jẹ ẹgbẹ PDP logun julọ.

Lati ọdun 2019 ni ede aiyede ti n waye laarin Gomina Seyi Makinde ati awọ̀n kan ninu ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Oyo.