Seyi Makinde: Kí ni wọ́n sọ nípa ètò ààbò lójú òpó Whatsapp PDP Oyo tí Gómìnà fí bínú kúrò níbẹ?

Aigbọraẹniye to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Oyotun ti gbọna mii yọ pẹlu bi Gomina Seyt Makinde ṣe fi ibinu kuro loju opo Whatsapp ẹgbẹ naa.
Igbesẹ Gomina yi ko sẹyin bi akọwe ipolongo ẹgbẹ PDP ni Oyo, Akeem Olatunji ṣe pin fọnran fidio kan nibi tawọn kan ti ni ki Gomina wa wọrọkọ fi ṣada nipa eto aabo.
Fọnran yi gẹgẹ bi a ti ṣe gbọ ni Olatunji fi ibeere kin lẹyin to si ni ''gbogbo eeyan lo ti ri fidio yi to si yẹ kawọn alaṣẹ fesi si''

Oríṣun àwòrán, livetimes.ng
Ọrọ yi la gbọ pe o bi Gomina ninu to si mu ko ṣapejuwe awọn to wa nidi fidio naa bi ''omugọ.''
Ninu aworan oju opo Whatsapp(Screenshot) to fi ọrọ ti wọn ni Gomina kọ, niṣe lo ni ''kii ṣe gbogbo ọrọ tawọn omugọ ba sọ lo yẹ ki ijọba fesi si''
Lẹyin ọrọ yi ni Gomina tun beere pe ki lo de ti ọrọ kan to niṣe pẹlu iforukọsilẹ ẹgbẹ APC ṣe wa loju opo PDP.
Ko pẹ ti o beere ọrọ yi ni Gomina ba yọ ara rẹ kuro loju opo Whatsapp ẹgbẹ naa.
Ki lawọn ọmọ ẹgbẹ mii wa sọ?
Iriwisi ọtọọtọ lo tẹle igbesẹ Gomina yi ta si gbọ pe bawọn kan ti se n bẹnu atẹ lu pe ko fẹ gbọ ootọ lawọn mii fibinu kuro lori opo naa lati fi ṣatilẹyin fun un.
Ninu awọn ọmọ ẹgbẹ to fi oju opo Whatsapp lẹ pẹlu Gomina Makinde ni Basa Sarumi, Akeem Olatunji, Bisi Ilaka, Hon Agboworin, Hon Dare Adeleke, Hon. Yinka Adeniyi ati Hon Kehinde Akande.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ileeṣẹ BBC gbiyanju lati pe ago alaga ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Oyo ko fesi sọrọ yi ṣugbọn ko gbe ago rẹ.
Bẹẹ naa la o ri ọrọ gbọ lati ọdọ alukoro ẹgbẹ PDP Akeem Olatunji ti wọn ni o da oju opo Whatsapp yi silẹ.












