Osun Govt Curfew: Ìkọlù láàrin àwọn ará ìlú Ilobu àti Erin-Osun, ìjọba kéde òfìin kónílé-ó-gbélé

Oríṣun àwòrán, twitter/Adegbeoyega oyetola
Ijọba ipinlẹ Osun ti kede ofin konileogbele wakati mẹrinlelogun ni ijọba ipinlẹ Irepodun ati Orolu lẹyin ikọlu to waye nibẹ lọjọ Abamẹta.
Awọn ilu meji Ilobu ati Erin Osun la gbọ pe laasigbo ti waye tawọn eeyan si n kọlu ara wọn.
Ninu atẹjade kan ti akọwe agba ijọba ipinlẹ Osun Wole Oyebamiji fi sita, o ni igbesẹ yi di dandan lati dẹwọ wahala to n waye nibẹ.
- Obasanjo àti Gani Adams tẹ́ mi pẹ̀lú bí wọn ṣe tahùn síra wọn - Adebanjo
- Káre Ẹfunroye Tinubu, Ògbóǹtagí oníṣòwò, olówò ẹrú àti afọbajẹ
- Ìdí rèé tí Ibadan ṣe ja ogun Kiriji pẹ̀lú Ekiti àti Ijesha f'ọ́dún mẹ́rìndínlógún
- Àwọn àgbà wo ló fọ́wọ́ ọlá gbá gbajúgbajà òṣèré Jamiu Afeez lójú tó ń wa ẹkún mu lóríi sinimá tó ṣe?
O ṣalaye pe ni nkan bi wakati meloo kan sẹyin ni Gomina Adegboyega Oyetola ti paṣẹ kawọn ọlọpaa pẹlu ọmọ ologun jijọ lọ sibẹ lati fidi alafiaa mulẹ.
Bẹẹ lo ṣalaye pe ijọba ti ni ki awọn agbofinro mu ẹnikẹni to ba tapa si ofin konileogbele yi tabi to n fa wahala lẹsẹ lagbegbe naa.
Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe wahala ilẹ lawọn apa ibikan ni Ayedande lo di ranto laarin awọn eeyan Ilobu ati Erin-Osun.
Ija yi taa gbọ pe o ti wa nilẹ tẹlẹ di fakinfa tawọn ọdọ lati agbegbe mejeeji si bẹrẹ si ni fa nkan ija yọ si ara wọn.
Ka to wi ka to fọ, wọn ni eeyan meji kan faragbọta nibi yiyinbọn to waye lori ija ilẹ yi.
Wahala yii tawọn ọlọpaa gbiyanju lati dẹkun rẹ lati ileeṣẹ ọlọpaa Dugbe ati Ifon la gbọ pe o ṣi n gbona janjan titi di ago mẹsan alẹ ọjọ Abamẹta.












