Ayo Adebanjo: Màá túbọ̀ parí aáwọ̀ Obasanjo àti Gani Adams torí ilẹ̀ Yorùbá kò gbọdọ̀ bàjẹ́

Oloye Olusegun Obasanjo ati Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Etim Baba Grace Okon/Facebook

Eekan inu ẹgbẹ Afenifere, Alagba Ayo Adebanjo ti fi aidunnu rẹ han lori aawọ to wa laarin aarẹ ana, Oloye Olusegun Obasanjo ati Aarẹ Ọna Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams.

Laipẹ yii ni Oloye Adebanjo pẹtu si ija to wa laarin awọn mejeeji nile rẹ ti Obasanjo ati Adams si sọ ohun to n dun wọn nibi ipade ọhun.

Adebanjo ni "Obasanjo fún ra rẹ lo mu ọjọ toun ati Gani yoo wa lati wa pari aawọ to wa laarin wọn, awọn mejeeji si wa lati yanju ọrọ naa"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ṣugbọn inu mi ko dun rara lẹyin ti mo gbọ pe wọn tun ti n tahun si ara wọn, paapaa julọ Obasanjo," Adebanjo lo sọ bẹẹ.

Oloye Olusegun Obasanjo ati Gani Adams pẹlu Ayo Adebanjo atawọn eeyan miran

Oríṣun àwòrán, Ayo Ademokoya/Facebook

Eekan Afenifere fikun ọrọ pe, Obasanjo tun ṣe awada pẹlu Gani pe o gbọdọ fún oun lowo oye to jẹ lẹyin ti oun yanju ọrọ naa tan.

Pa Adebanjo ni 'emi lawọn mejeeji tẹ papaa julọ Obasanjo pẹlu bi wọn ṣe tun n sọrọ si ara wọn."

"Ohun ti mo n ṣe ni pe ki ilẹ Yoruba maa bajẹ, amọ a n jekuru ko tan lawo, wọn tun gbọn ọwọ sabọ ni ọrọ yii o," baba Adebanjo lo wí bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Eekan Afenifere naa sọ pe ti ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ kii tan leekanna, o ni oun ṣetan lati pe awọn mejeeji pada lati yanju ọrọ naa.

Adebanjo ni oun yoo sa gbogbo agbara oun lati wa ojutu si aawọ naa nitori "ilẹ Yoruba ko gbọdọ bajẹ."