Secret Cults in Nigeria: Ìyá àti ọmọ tó wà nínú Márúwá bá ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn lọ

Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria

Ko din ni ogun eeyan to dagbere faye nigba ti ọpọ miran fi ara gbọgbẹ lorisirisi lasiko tawọn tawọn ẹgbẹ okunkun fija pẹẹta nilu Ijebu Ode.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti sọ, ọsẹ meji sẹyin ni ija naa ti bẹrẹ, ti apapọ iye eeyan to si ti ba rin ti le ni ogun.

Iroyin naa ni ẹgbẹ okunkun Eiye ati Aiye ni wọn n doju ija kọ ara wọn, eyi to mu ki ohun gbogbo poluku musu lawọn agbegbe kan nilu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn adugbo ta gbọ pe ọrọ naa kan ni Gareeji Epe, Ejinrin Road, Adefisan, Gareeji Ibadan, Onirugba, Tatina ati oju ọna Benin si Ondo.

Koda wọn ni iya kan ati ọmọbinrin rẹ, ti wọn wa ninu kẹkẹ Maruwa ni ọta ibọn seesi ba, ti wọn si jẹ Ọlọrun nipe.

Aworan eto igbani wọle sẹgbẹ okunkun
Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi ọna ni eto igbani wọle maa n gba ninu awọn ẹgbẹ okunkun

Ọpọ eeyan niroyin naa lo ku iku aimọdi lati ipasẹ wahala naa ni gareeji Epe, Road, Adefisan, Gareeji Ibadan, Onirugba, Tatina ati oju ọna Benin si Ondo.

Bẹẹ si ni ọpọ awọn eeyan lo n sa asala fun ẹmi wọn lasiko rogbodiyan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa.

Ọ̀rẹ́bìnrin míì dáná sí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ lára lẹ́yìn tó kọ̀ láti fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya

Ile ọrẹkunrin ti ọrẹbinrin rẹ sọ ina si

Oríṣun àwòrán, verifiedNG

Lẹyin bi ọsẹ meji ti ọdọbinrin kan danu sun ile ọrẹkunrin rẹ nibi ti ina ti mu ololufẹ rẹ to wa nile, ọdọbinrin mii tun ti dana si ọrẹkunrin rẹ lara ni ijọba ibilẹ Gboko nipinlẹ Benue.

Iroyin ti a gbọ ni pe ọdọbinrin naa gbe igbesẹ yii lẹyin ti ololufẹ rẹ lati ṣe igbeyawo pẹlu rẹ.

Ohun tawọn to mọ nipa iṣẹlẹ naa sọ ni pe ọdọbinrin yii sọna si ile ololufẹ rẹ lẹyin ọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Jude atawọn ti sun tan.

Ni deedee aago kan aabọ oru ni a gbọ pe obinrin yii lọ ṣiṣẹ laabi ọhun.

Ṣugbọn ori ko awọn to wa ninu ile yọ bo tilẹ ina mu Jude eyi to mu ki ara rẹ bo yanayana.

Apa ina ko pọju lara mama rẹ ati aburo rẹ ọkunrin ti wọn jọ wa nile lasiko iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ojú mi ti rí lọ́pọ̀ lọpọ̀, àmọ́ mo dúpẹ́ pé mo ti pé ọdún márùn ún lórí oyé- Ooni

Awọn mẹtẹẹta ti wa ni ile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju fun ara wọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue, DSP Catherine Anene fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Anene ṣalaye pe lootọọ nile iṣẹ ọlọpaa gba ipe pe ọdọbinrin kan tu epo si ile ọrẹkunrin rẹ ti o si tun fi ina sii.

Amọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa awọn ko tii ri ọdọbinrin naa mu.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ