Ronke Odusanya sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó ní ó ti jẹ bàbá ọmọ rẹ̀, Jago run

Oríṣun àwòrán, Ronke Odusanya/Instagram
Gbajugbaja oṣerebinrin, Ronke Odusanya 'Flakky Ididowo', ti sọ pe didakẹ ti oun dakẹ kii ṣe ti ojo.
O sọ ọrọ yii lẹyin ti iroyin kan jade sori ayelujara pe wahala wa laarin oun ati baba ọmọ rẹ, Olanrewaju saheed 'Jago'.
Ọdun to lọ ni Ronke bi ọmọ rẹ akọbi, Fife.
Asiko to bimọ ọhun si ni ọpọ eeyan to o mọ ẹni ti ololufẹ rẹ jẹ, nitori pe o fi aworan ọkunrin naa ati ọmọ rẹ si ori ayelujara.
BBC Yoruba ko le fidirẹ mulẹ boya igbeyawo waye laarin awọn mejeeji.
- Wo àwọn òṣèré tó bímọ s'Amẹrika lọ́dún 2019 kí Trump tó f'òfin dèé
- Mercy Aigbe bu èpè jó àwọn tó ní gómìnà kan ló ra ilé fún-un
- Wo fọ́tò àrà MC Oluomo, Pasuma àtàwọn òṣèré tíátà míì níbi ìṣílé Iyabo Ojo
- Ọdún mọ́kànlá rèé témi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ láti ilé ẹ̀kọ́ girama - Bukunmi Oluwasina
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
Ninu iroyin to jade bayii, akọroyin naa sọ pe Ronke 'Flakky', gbe Jago lọ sile ẹjọ, lati pẹlu iranlọwọ gbajugbaja agbẹjọro, to tun jẹ Minisita Naijiria keji fun ọrọ awọn oṣiṣẹ, ati igbanisiṣẹ, ki ọmọ le wa lọdọ rẹ.
Iroyin naa tẹsiwaju pe Flakky fẹ ki ile ẹjọ fi ofin de Jago, lati ma ni anfaani si ọmọ naa mọ.
Kini iroyin sọ pe o fa wahala?
Akọroyin Gistloverszone lori Instagram sọ pe Ronke mu ki Jago ta mẹta lara ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin to ni.
O ni Ronke beere fun ọpọlọpọ miliọnu Naira lọwọ Jago, lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kan ọmọ wọn.
Nitori idi eyi si ni Arakunrin Jago ṣe ta ọkọ ayọkẹlẹ kan ti owo rẹ to miliọnu mejila, ṣugbọn to ta ni miliọnu mẹrin Naira.
"O ko owo naa fun Ronke lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọmọ naa, amọ Ronke ko pada ṣe ayẹyẹ kankan."

Oríṣun àwòrán, Screenshot/gistloverszone/instagram
Iroyin naa tẹsiwaju pe wahala bẹrẹ nigba ti Flakky gba Jago ni imọran lati ta ile rẹ, ti owo rẹ to miliọnu lọna aadọrun (90 million) Naira.
"Jago gba lati ṣe bẹ lootọ, ṣugbọn iya rẹ ti iwe ile naa wa lọwọ rẹ kọ lati ko silẹ.
"Iya naa sọ pe gbogbo dukia rẹ lo ti ta tan.
Gbogbo nkan ti mo ni, ni ma a fi dena rẹ pe ko ta ẹyọkan ṣoṣo to ku."
Ẹsun naa ko ti i pari o.
- Àwọn ojú oge Yollywood t'ọ́jà wọ́n ṣì ń tà wàràwàrà
- Ànọ́bì ni màá tẹ́lè... Kemi Afolabi joyè ìmọ́lẹ̀ Adinni
- Ìjà Toyin àti Lizzy kìí ṣe àkọ́kọ́, àwọn òṣèré t'ọ́rọ̀ ìjà kàn rí rèé
- Òṣèrébìnrin tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ lọ̀ 'torí ìṣẹ́, kó bọ́ síta láti sọ̀rọ̀ - Kunle Afod
- Jumọkẹ Odetola ṣe ọjọ́ ìbí, Wumi Toriola bímọ, Ṣé ẹ fẹ́ tẹ̀lẹ́ Funkẹ Akindele lọ si Dubai?
Gistloverszone tun sọ pe Ronke ni oun nilo miliọnu marundinlaadọrin (65million) Naira, lati ni awọn irin'ṣẹ fun sinima yiya gẹgẹ bi awọn akẹẹgbẹ oun.
O tun ni Ọgbẹni Jago lo gbọ bukaata bi Ronke ṣe ṣe idi nla, lẹyin ti wọn bẹrẹ si ni fẹ ara wọn.
Ati pe o tun ra ọkọ ayọkẹlẹ fun iya ati arakunrin Ronke, to si tun ya a lowo.
Ṣaaju awọn ẹsun yii, ni Gistlover ti kọkọ kọ iroyin lọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, pe aarin Ronke ati Jago ti daru.
To si bẹ Ronke lati pada lọ.
Kinni Ronke Odusanya 'Flakky Ididowo' sọ?
Ninu ọrọ to kọ si oju opo Instagram rẹ, Ronke sọ pe oun yoo ṣe suuru lori ọrọ naa, nitori pe otitọ yoo pada farahan.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/ronkeodusanya/instagram
O ni "mo le gbeja ara mi, ṣugbọn mi o fẹ ki ọmọ mi dagba tan, ko ma a ka iru iroyin radarada, ti ko ni ootọ kankan ninu.
"Ranti pe, iwọ kọ lo sọ mi di eeyan, nitori naa o o le ba temi jẹ."
O ṣalaye pe akọsilẹ ni banki le ṣafihan ẹni to n gba owo lọwọ ara wọn, ati nkan to fi ṣe.
Kinni Jago sọ lori ọrọ naa?
A ko ri arigbamu ohunkohun lori ayelujara Instagram rẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/instagram/jago000007
Ṣugbọn, o n fi owe sọ awọn ọrọ kan pe: O ṣoro lati gbagbe ẹdun ọkan yii, ṣugbọn ohun to nira ju ni iranti adun.
Eyi waye lẹyin ti iroyin naa jade sita.
"A ko ni àpá lati fi idunnu han, ẹkọ diẹ lasi ri kọ lara alaafia."
BBC ko ti i fidi awọn ẹsun yii mulẹ.
Awọn akiyesi ti a si ṣe ni pe Ronke ki Jago ku ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, lọjọ keji, oṣu Kọkanla.
Ọrọ iwuri, ifẹ, ati adura lo fi ki ku ọjọ ibi.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/instagram/ronke odusanya
Koda, o pe e ni 'baba to dara julọ ni agbaye'.
Ninu oṣu Kẹjọ bakan naa, awọn mejeeji jọ ya fọto fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kan ọmọ wọn ni.
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
- Èyí ni àwọn aṣíwájú ìjọba tí ajé ìwà ìjẹkújẹ ti ṣí mọ́ lórí láàrin ọdún 1960 sí àsìkò yí
- Ara mi rẹwà ló jẹ́ kí n máa ṣí ara sílẹ̀- Victoria Kolawole
- Ọ̀rẹ́bìnrin míì dáná sí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ lára lẹ́yìn tó kọ̀ láti fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya
- Èsì ìdìbò tí yóò gbé aàrẹ tuntun wọlẹ́ ní Ghana rèé...










