World Aniti-Corruption day: Awolowo, Azikwe, Abacha àtàwọn olórí ìjọba tí aje ìwà ìjẹkújẹ ti ṣí mọ́ lórí rí ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, others
Èyí ni àwọn aṣíwájú ìjọba táje ìwà ìjẹkújẹ ti ṣí mọ́ lórí láàrin ọdún 1960 sí àsìkò yí
Ọrọ iwa ijẹkujẹ kii ṣe ajeji lorilẹede Naijiri. Koda ọpọ ti rii gẹgẹ bii baraku pẹlu isejọba, oṣelu ati igbe aye awọn ọmọ Naijiria lapapọ.
Bẹrẹ lati igba ti orilẹede Naijiria ko tii gba ominira ati lẹyin igbominira rẹ.
Eyi ni agbeyẹwo awọn eekan ti wọn ti fi ẹsun iwa ijẹkujẹ kan ti wọn si ti jẹbi.
Nnamdi Azikiwe:
Ni ọdun 1956, igbimọ oluwadii kan ti a da pe ni Foster-Sutton Tribunal of Inquiry se iwadii olootu ijọba ẹkun ila oorun ọjọhun,
Ọmọwe Nnamdi Azikiwe, lori ẹsun pe o n lo ipo rẹ lati fi ṣe akoso banki African Continental Bank (ACB) nigba naa.
Iwe ofin to de ihuwasi awọn to di ipo oṣelu mu ( The code of conduct) yannana rẹ pe ẹnikẹni to ba di ipo ilu mu gbọdọ fi ipo yoowu to ba dimu ni ileeṣẹ aladani gbogbo silẹ ni kete to ba ti de ori oye.
Igbimọ oluwadii Foster-Sutton Tribunal kẹfin pe Ọmọwe Azikiwe ko ja okun to so oun ati banki naa pọ lẹyin to jẹ olooyu ijoba ẹkun ila oorun Naijiria.
Igbimọ naa ṣalaye pe Azikiwe ṣi lo agbara ati ipo rẹ lati maa fi fa ire lọ sọdọ banki naa (Report of the Foster-Sutton Tribunal of Inquiry, 1956: 42; Sklar, 2004: 185).
Bẹẹ si ree Azikiwe, ileeṣẹ Azikiwe at'awọnẹbi rẹ ni wọn ni ipin idokoowo to pọ julọ ni banki naa nigba naa.
Abajade: ko si ẹni lee sọ ni pato idi ti awọn alaṣẹ nigba naa ko fi fi Azikwe jofin.
Oloye Ọbafẹmi Awolowo:
Ni ọdun 1962, oloye Obafemi Awolọwọ to jẹ olotu akọkọ fun ijọba iwọ oorun Naijiria nigba naa pẹlu koju ẹsun ikowojẹ. Igbimọ oluwadii Coker Commission of Inquiry lo ṣewasii rẹ, wọn si ni o jẹbi ẹsun naa.
Ni ọdun 1954, ajọ ontaja ẹkun iwọ oorun Naijiria, Western Region Marketing Board ni owo to to miliọnu mefa ati ẹgbẹrun lọna igba pọun (£6.2 milion) ninu aṣuwọn rẹ.
Amọṣa, nigba ti yoo fi di ọdun 1962, owooya to le ni miliọnu meji abọ pọun (£2.5 million) lo wa lọrun ajọ naa lẹyin ti wọn ni ọpọ owooya lawọn ileeṣẹ ijọba kan gba ti wọn ko san pada.
Igbimo Coker Commission of Inquiry ni Oloye Awolowo jẹbi lori isubu ajo naa nitori ko tẹlẹ ilana to tọ fun ẹni to ba di ipo ilu mu lati tẹle (Coker Commission, 1962; Magid, 1976: 73).
Ni ọdun 1994 igbimọ oluwadii Okigbo panel ti wọn gbe kalẹ fun atunto banki apapọ Naijiria na ika ọwọ rẹ ko mọ si aarẹ ologun nigba naa, Ọgagun agba Ibrahim Babangida.
Koda, ọrọ naa kan ọgagun agba Sani Abacha ati gomina Banki apapọ nigba naa, Alhaji Abdulkadir Ahmed.
Wọn ni pe wọn lọwọ si bi wọn ṣe ṣe owo to le ni biliọnu mejila dola ( $12.4 billion) owo ere ori epo laarin ọdun 1988 si 1994.
Igbimọ naa ni awọn eekan ijoba Babangida nigba naa lẹdi apo pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ banki apapọ Naijiria lati lu owo naa ni ponpo nipa ninaa sori awọn akanṣe iṣẹ ti ko ṣe e tọka si.
(Okigbo Panel Report, 1994).
Ọgagun agba Sani Abacha:
Ṣaaju iku rẹ lọdun 1998, ọgagun agba Sani Abacha ni olori ijọba ologun ni Naijiria.
Lẹyin iku rẹ ni ọpọ iwadii n fihan pe obitibiti owo ni o ko lọ pamọ si oke okun.
Titi di bi a se n sọrọ yii owo ti llori orilẹede yii naa ko pamọ ti Naijiria ko tii gba n lọ biii
Bẹẹ si ni iye owo ti wọn ti gba pada lawọn orilẹede oke okun to ko wọn pamọ si ti to.
Amọṣa, yatọ sawọn asiwaju ijọba wọnyiajọ EFCC ti wọn gbe kalẹ lasiko isejọba Olusẹgun Obasanjọ ti se ọpọ iṣẹ ti wọn si ti gbe ọpọ awọn eekan ati oloselu ju si gbaga fun ẹsun ikowojẹ.
- Èsì ìdìbò tí yóò gbé aàrẹ tuntun wọlẹ́ ní Ghana rèé...
- Àwọn èèyàn tí bẹ̀rẹ̀ sì ní gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ìdènà àrùn Coronavirus ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Lóòtọ́ ni ọkọ mi lù mí bí àṣọ òfì, àmọ́ gómìnà ti bá wa parí ẹ̀, ẹ máa gbàdúrà fún ìdílé mi- Dokita Ifeyinwa
- Èyí ni ìtàn Ọkùnrin tó rí ẹ̀wọ̀n he nítorí àkùkọ aládúgbò rẹ̀ tó pa
Diẹ lara wọn niyi:
Oloye Sunday Micheal Afọlabi.
Oloye Afọlabi ti ọpọ mọ si SM ni minisita f'ọrọabẹle labẹ isejọba Olusẹgun Obasanjọ nipasẹ bẹẹ oun ni alakoso eto kaadi idanimọ orilẹede Naijiria akọkọ nigba naa eyi ti owo agbase rẹ jẹ igba o le mẹrinla miliọn dola ($214million).
Amọsa ọrọ bẹyin yọ nigba ri oorun ijẹkujẹ bẹrẹ si ni run sita labẹ eto naa.
Ọrọ bẹyin yọ pẹlu bi wọn ṣe gbe iṣẹ agbase naa fun ileeṣẹ
SAGEM S.A., lati ilẹ France nigba ti ileeṣẹ itẹwe abo lorilẹede Naijiria (Nigerian Security Printing and Minting Company, NSPMC), naa fifẹ han lati gba iṣẹ naa ni owo to dinwo ju ti ileeṣẹ Faranse naa lọ.
Akosilẹ iwadii fihan pe ika alebu na si Hussaini Akwanga to jẹ minisita fun oro oṣiṣẹ nigba naa, Sunday Michael Afolabi to jẹ minisita fun ọrọ abẹlẹ pẹlu Mahmud Shata to jẹ igbakeji rẹ.
Tafa Balogun:
Ọga ọlọpaa Naijiria ni Tafa lasiko isejọba Oluṣẹgun Ọbasanjọ ki wọn to fi panpẹ ofin gbe lori ẹsun pe o se owo to din diẹ ni biliọnu mẹfa naira baṣubaṣu (N5.7billion).
Wọn fi si ẹwọn oṣu mẹfa lẹyin ti ajo EFCC fi ẹsun aadọrin to ni se pẹlu ikowojẹ kan an.
Lucky Igbinedion:
Gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ, Lucky Igbinedion ni Gomina akọkọ ti yoo ri pipọn oju ofin fun kiko owo ilu jẹ. Ajọ EFCC fi ẹsun kan an pe o ko owo to le ni miliọnu mẹrinlelogun dọla ($24million) jẹ.

Oríṣun àwòrán, others
O ba ajọ naa ṣe dunadura lodun 2008 lati san lara owo to ko jẹ pada ki o si maa.gba ile rẹ.lọ dipo ẹwọn.
Diepreye Alamueyesigha:
Gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ ni, ni ọdun 2007 ni wọn ran an lọ si ẹwọn ọdun meji lloriikowojẹ.
Ọjọ diẹ lo lo ninu rẹ lẹyin to lo bii ọdun meji ninu ahamọ lasiko to n reti igbẹjọ rẹ.

























