Border Closure reoppening: Àarẹ Buhari ní àti dẹ́kun fàyàwọ́ ogun ati ìbọn ló fa títi ẹnubodè pa, ṣùgbọ́n yóò di ṣíṣí padà láìpẹ́

Buhari

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Wo ìgbà tí Ààrẹ Buhari yóò ṣí 'bọ́dà' padà

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ijọba apapọ ti n ronu ṣiṣi awọn ẹnubode orilẹede Naijiria ti wọn ti pa tẹlẹtẹlẹ.

Aarẹ Buhari kede pe ijọba orilẹede Naijiria ko ṣa dede ti awọn ẹnubode naa bikoṣe lati dẹkun awọn fayawọ ohun ija oloro ati ogun nigba naa lẹyin ipade pẹl'awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Ninu atẹjade kan to fi soju opo twitter rẹ ni aarẹ ti ṣalaye lori igbesẹ yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Aarẹ ni oun ti ṣalaye idi ti wọn fi gbe awọn ẹnubode naa ti pa, "bẹẹni nisisiyi to dabi ẹni pe awọn orilẹede to mule ti wa ti mọ pataki ohun ti a fẹ bayiisaid, a ti n wo igbesẹ ati ṣii pada.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Kikelomo Ogunboye tan ìmalẹ̀ sí ìwà olè ọ̀gá ọlọ́pàá

Awọn ohun ti o nilo lati mọ nipa ẹnubode ti ijọba aarẹ Buhari tipa niyi:

Ni oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni ijọba ti awọn ẹnubode lati dẹkun fayawọ ogun, ohun ija oloro, ounjẹ atiohun elo ọgbin wọ orilẹede Naijiria.

* Orilẹede Naijiria kun ara awọn orilẹede to buwọlu adehun ajọṣepọ okoowo ọfẹ laarin awọn orilẹede Afirika, agreed African Continental Free Trade Area (AfCFTA),

Nibi ti ijiroro ti waye lori ṣiṣi awọn ẹnubode naa lati bẹrẹ owo pẹlu awọn orilẹede Afirika yoku.

*Minisita iṣuna ati ato ọrọ aje, Zainab Ahmed ṣalaye loṣu to koja pe igbimọ ti aarẹ gbe kalẹ ti pari iṣẹ rẹ o si ti buwọlu ki wọn ṣi awọn ẹnubode naa pada.

O fi kun un pe laipẹ ni wọn yoo gbe abajade iwadii wọn tọ aarẹ lọ.