Kiriji war (1877-1893), Ibadan, Ekiti, Ijesa: Ìkónilẹ́rú ilẹ̀ Yorùbá ló parí Ogun Kiriji

Awọn to jagun Kiriji

Oríṣun àwòrán, Old Naija

Yoruba bọ, wọn ni ti ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba nitori arọba gan an ni baba itan.

Eyi lo difa fun itan bi ogun Kiriji ṣe waye, ohun to ṣe okunfa rẹ, iye ọdun ti wọn fi ja ogun naa ati bi o ṣe pari.

Ogun Kiriji ti ọpọ tun mọ si ogun Ekiti parapọ jẹ ogun to waye laarin ilu Ibadan ati Ekiti pẹlu Ijesha.

Gẹgẹ bí Latosa ṣe ṣalaye, ogun Kiriji lo kẹyin gbogbo ogun nilẹ Yoruba, ati pe ogun naa lo pẹ julọ ninu gbogbo ogun to ṣẹlẹ nilẹ Yoruba.

Ki lo ṣe okunfa ogun Kiriji?

Ṣe ẹ mọ pe ti ko ba nidi, obinrin kii jẹ ikumolu.

Ogun Kiriji bẹ silẹ nitori awọn ofin ati ilana didari awọn eeyan ti Ibadan gbe kalẹ nitori ipa to ko ninu ogun ilu Osogbo ọdun 1840 ati iṣẹgun rẹ ninu ogun Ijaye.

Iṣẹgun yii lo pokiki Ibadan gẹgẹ bí ilu akin ti yoo rọpo ijọba abaṣẹ wa Oyo Ile to wo lulẹ.

Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

Ibadan ti fi idi ijọba rẹ mulẹ kaakiri ilẹ Yoruba to fi de Ekiti ati Ijesha.Ṣugbọn Ekiti ati Ijesha tako igbesẹ yii nitori wọn ko ri Ibadan gẹgẹ bi ilu alagbara ilẹ Yoruba.

Ohun to ṣe okunfa ogun Kiriji gan an ni bi awọn aṣoju ilu Ibadan ṣe n huwa ọdaran lawọn ilu.

Itan sọ pe niiṣe ni wọn n dunkoko mọ awọn ọdọ, koda wọn tun n fi ipa bawọn obinrin lopọ.

Eleyi lo mu ki awọn eeyan Ekiti ati Ijesha ṣekupa ọpọ ninu wọn ti wọn si doju ija kọ Ibadan.

Bayii lawọn ilu mii nilẹ Yoruba naa da si ogun ọhún.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Ewo ni wọ́n n pè ní ogun Jalumi to waye lọd\un 1878?

Egba ati Ijebu ṣegbe lẹyin Ekiti ati Ijesha.

Wọn si doju ija ko Ibadan lati Guusu.

Nigba ti awon ọmoogun Ekiti ati Ijesha pẹlu atilẹyin awọn Fulani gbogun ti Ibadan lati apa Ariwa.Lọna marun un ọtọọtọ ni Ibadan nikan ti jagun.

Lọjọ kinni, oṣu kọkanla, ọdun 1878 ni Ibadan kọlu awọn ọmọogun Ekiti, Ijesha at'awọn Fulani Ilorin lapa Ariwa ibi to di ipinle Osun lonii.

Ibadan si ṣẹgun gbogbo wọn.

Eyi ni wọn n pe ni ogun Jalumi ọdun 1878 tabi Ogun Ikirun.

Jagunjagun Ogedengbe

Oríṣun àwòrán, Old Naija

Kini o kọkọ fa ija laarin Modakeke ati Ile Ife?

Ogun Kiriji naa lo ta epo si aawọ to wa laarin Ife at'awọn ara Oyo to wa niluu Modakeke ti wọn ṣe atilẹyin fun Ibadan.

Modakeke pada bori Ifẹ pẹlu iranlọwọ Ibadan.

Àkọlé fídíò, Ìtanijí lórí BBC Yorùbá: Odú Iwori Obara bá wa sọ̀rọ̀ lórí ìfaradà tó pọ̀

Kini idi ti wọn fi sọ ogun naa ni ogun Kiriji?

O ṣe pataki lati mọ pe oruko Kiriji ti wọn n pe ogun naa niṣe pẹlu bi ohun ija oloro ti wọn fi jaa.

Bi ohun ija ti awọn ọmọogun Ekiti ati Ijesha n lo labẹ alaṣẹ ọgagun wọn, Ogedengbe ṣe n dun bi àrá nigba naa lo faa.

Awọn ohun ija oloro yii lo ran Ekiti ati Ijesha lọwọ ninu ogun Kiriji.

Ba wo ni ogun Kiriji ṣe pari?

Ogun Kiriji tẹsiwaju fun ọpọ ọdun ki Gomina Carter lati ilu oyinbo to gbiyanju lati pẹtu sija náà lọdun 1886.

Ṣugbọn ogun naa ko pari to fi di ọdun 1892 nigba ti ilẹ Gẹẹsi de si Ijebu pẹlu ibọn to lagbara.

Lọdun 1893 ni Gomina Carter fi ipa pari ija ọhún.

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife

Itan sọ pe gomina f'ẹsẹ rin lati ilu Eko lọ si ibudo awọn ọmọogun Ibadan ati Ekiti pẹlu Ijesha ni Igbajo ati Okemesi.

Nibẹ lo si ti sọ fawọn ọmoogun naa pe ki wọn pada sile.

Lẹyin naa ni wọn jọ buwọlu iwe adehun kan eleyii to sọ ilẹ alagbara ilẹ Yoruba di ọkan lara awọn ẹkun ti ijọba ilẹ Gẹẹsi ko lẹru lapa Iwọ-oorun ilẹ Afirika.