Oba Abdul-Rauf Olayiwola Adedeji II : Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Akirun ti Ìlú Ìkìrun tó wàjà

Akirun ilu Ikirun, Oba AbdulRauf Olawale Adedeji

Oríṣun àwòrán, Tkbeshi Online

Ijọba ipinlẹ Osun lo kede loju opo Twitter rẹ pe Akirun ilu Ikirun, Oba AbdulRauf Olawale Adedeji waja lalẹ Ọjọru

Ijọba Osun ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe ni bii ago mọkanla alẹ Ọjọru ti Oba Adedeji dagbere faye.

Ko si ẹni to le sọ pato ohun to ṣekupa Akirun ilu Ikirun lẹni ọdun mejidinlọgọrin.

Ohun ti a gbọ ni pe Akirun ṣe aisan diẹ ki Ẹlẹmi to gba a lalẹ Ọjọru.

Bi ọgbọn ọdun sẹyin ni Oba Adedeji gori itẹ baba rẹ nilu Ikirun.

Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

Ọpọ eeyan lo ṣapejuwe Oba Adedeji to jẹ oṣiṣẹ banki tẹlẹ ki o to jọba pe musulumi ododo ni.

Ogunna gbongbo ẹgbẹ musulumi nii ṣe nilu Ikirun ati ni ipinlẹ Osun lapapọ nigba aye rẹ.

Ọdun 2002 ni Oba Adedeji lọ si ilẹ mimọ ni ilu Mecca.

Oba Ikirun

Oríṣun àwòrán, Google

Oun ni baba iṣalẹ ẹgbẹ musulumi Ibadu-Rahman Society ati Anwar-Ul-Islam niluu Ibadan nigba aye rẹ.

Oba Adedeji lo ọrọ rẹ Eledua yọnda fun un lati ṣe iranwọn fawọn ti ko rọwọ họri lawujọ.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Ìròyìn Yàjóyàjó -'Akirun ti Ìlú Ìkìrun,Oba Abdul-Rauf Olayiwola Adedeji II ti wàjà

Ọba Akirun ti Ikirun, Oba Abdul-Rauf Olayiwola Adedeji II ti jade laye.

Eni ọdun mejidinlọgọrin ni ọba ni ipinlẹ Osun naa ki wọn to jade laye.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo