Police brutality: Tola ní inú òun kò bá dùn tí wọ́n bá le fi àwọn ọlọ́pàá tó lù òun jófin yàtọ̀ sí 5m tí wọ́n fẹ́ fún òun

Oríṣun àwòrán, Twitter/Abiodun Sonaike
Ileẹjọ giga niluu Osogbo ti dajọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa san miliọnu marun naira fun ọmọbinrin kan, Tola Azeez lẹyin ti awọn ọlọpaa fiya jẹ ẹ lasiko kole-o-gbele arun coronavirus.
Azeez niwaju ile rẹ lawọn ọlọpaa kan ṣadeedee ri, ti wọn si lu u lalu bami lai ṣẹṣẹ kan.
Fidio bi wọn ṣe lu u nilu bara gba ori ayelujara kan lọdun to lọ.
- Bàbá mi Ooni, ẹ foríjìn mí, ẹnu mi ò gbàá láti bú yín- Sunday Igboho tọrọ àforíjìn
- Ọkọ̀ agbépo bẹ́ntiról kankan kò gbọdọ̀ gun afárá nípínlẹ Ogun mọ́ - Gomina Dapo Abiodun
- Àwọn ọmọ onílẹ̀ lọ ṣe àmúṣẹ àṣẹ iléẹjọ́ ní Soka, làwọn ‘Jàǹdùkú’ fi dá wọn lọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ọyọ
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
Tola ni oun ni lati fi ilu ti oun n gbe nigba naa silẹ lati lọ tọju ara oun niluu ibo mii.
O ṣalaye pe ṣaaju iṣẹlẹ naa, oun jẹ ẹnikan ti kii fẹ kawọn eeyan ṣaaba mọ nipa oun to n ṣẹlẹ si oun.
Ṣugbọn o ni inu oun dun pe ileẹjọ ni ki wọn fun oun ni miliọnu marun un.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Amọ o ni inu oun ko ba dun si ti wọn ba le fi ọlọpaa to fiya jẹ oun jofin ko lo jẹ arikọgbọn fawọn mii to ba hu iru iwa bẹẹ.



















