Nigeria Inheritance way: Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin dá pín ogun bàbá wa, wan ní obìnrin ni mí- Onyinye

Kini iyatọ laarin ọmọ ọkunrin ati ọmọ obinrin?
Se o yẹ ki a pin ogun ọtọọtọ fun wọn nigba ti a ba re ibi agba n re ni?
Tohun ti idajọ ile ẹjọ to gaju lọ ni Naijiria nise lawọn eeyan yọwọ awọn obinrin lawo ninu ogun pinpin, paapa lagbegbe Ila oorun guusu Naijiria.
- Wo ìdí tí orílẹ̀-èdè America ṣe tako ìyànsípò Okonjo-Iweala gẹ́gẹ́ bi olórí ajọ WTO
- Ọmọ Naijiria di asofin agba ni Italy
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìnì fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'
Ki a sọ nipa arabinrin kan ti iru nkan bayi ti sẹlẹ si ni eyi ti a le fi mọ bi nkan ti se ri ni agbegbe kọọkan bẹẹ.
Onyinye Igwe padanu baba rẹ ni nkan bi ọdun meji sẹyin sugbọn lati igba naa ni nkan ko ti rọgbọ fun un.
Baba rẹ ti a n sọ yi fi ọpọ dukia silẹ bii owo ni banki ati ile pupọ.
Kii se talaka rara nigba ti yoo fi faye silẹ.
Ọmọ ọkunrin nikan lo ni ogun ninu aṣa agbegbe wa:
Baba Onyinye Igwe se ise ti ọpọ awọn baba maa n se lagbegbe wa yi.
Ko fi akọsilẹ ogun kalẹ ki ọlọjọ to de nitori naa awọn ọmọ naa ni wọn seto ogun pinpin funra wọn lẹyin iku rẹ.

Kayeefi ibẹ ni pe arabinrin Igwe to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ati awọn aburo rẹ obinrin marun un ko ri sisi gba ninu ogun baba wọn.
Awọn ọmọ ọkunrin mẹta gẹgẹ bi asa ilẹ Igbo, lo gba gbogbo ogun baba wọn ti wọn si pin in laarin ara wọn.
Asa to fẹsẹ mulẹ laarin awọn Igbo ni pe obinrin ko lẹtọ lati jogun ilẹ nitori wọn ko ni wa laarin awọn eeyan wọn bi wọn ba ti lọkọ tan.
Awọn ọkunrin ti yoo si maa gbe orukọ mọlẹbi ga gẹgẹ bi ero wọn nikan lo lẹtọ lati jẹ ogun.
Bakan naa ni wọn lero pe ọkọ ọmọ obinrin ni yoo jẹ anfaani ilẹ yi tabi ko gba gbogbo ogun awọn ti o ba fi le bọ si ọwọ iyawo rẹ.
Lati igba iwasẹ lawọn Igbo ti gbagbọ pe awọn ọmọkunrin lo lẹtọ si ile mọlẹbi ti a n pe ni ''Family House''.
Asa yi kosẹyin bi awọn baba ti se maa n da gbe lọtọ laaye ti wọn n pe ni ''obi'' ninu agboole wọn.
Bi baba ba ku tan, awọn nkan manigbagbe tabi nkan agbara to ba ni to si wa ninu obi yi, wọn yoo faa le ọmọ ọkunrin akọbi lọwọ.
Nibi ti ko ba ti si ọmọkunrin ni mọlẹbi naa wọn yoo gbe fawọn ibatan arakunrin to ku sugbọn wọn ko nigbe fun iyawo rẹ tabi awọn ọmọ rẹ lobinrin.

Oríṣun àwòrán, Magnum Photos
Asa yi ti pẹ sugbọn kii se gbogbo awọn obinrin lo faramọ mọ lode oni.
Ninu ẹjọ kan to lamilaka ti wọn fa fun ogun ọdun, arabinrin kan wọ awọn mọlẹbi rẹ lọ siwaju adajọ.
Nigba ti wọn yoo fi pari ẹjọ naa ni 2014, ile ẹjọ giga julọ pasẹ pe ko lẹtọ lati yọwọ awọn ọmọ obinrin kuro ninu ogun pinpin bo ti le wu ki o jẹ ati pe asa ilẹ Igbo yi ti kii pin ogun fawọn obinrin tako ofin.
Pẹlu idajọ to wa nilẹ yi, ko fẹ ẹ siyatọ pẹlu bawọn eeyan ko ti se sinmi lati maa yọ awọn obinrin kuro ninu ogun pinpin.
- Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ mú àgùnbánirọ̀ di èrò iléẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kogi
- Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun
Egodi Igwe ti ko tan mọ Onyinye Igwe ti a darukọ ni ibẹrẹ itan yi, jẹ ẹni to da ajọ ẹlẹyinju aanu silẹ (Women Aid Collective,Wacol), lati maa pese eto iranwọ ọfẹ fawọn obinrin to ba fẹ sẹjọ lori bi wọn ko se pin ogun kan wọn.
Aimọye ẹjọ ni wọn maa n gbe wa si ọdọ wọn lọdọọdun
Egodi ni "Awọn asa ati isẹse to n ko ipalara bawa si wa lawujọ wa daadaa''
"Bi o ba n sọ fun ọmọ obinrin pe ko lẹtọ lati jẹ ninu ogun baba rẹ, a jẹ pe n sọfun pe ko lẹtọ lati wa laye
''Awọn obinrin ni lati gbe igbesẹ''

Awọn obinrin ti wọn ko jẹ ki wọn jẹ ogun ni anfaani lati gbaile ẹjọ lọ sugbọn nitori wahala ati asiko ti ẹjọ naa yoo lo, pupọ a maa tọ awọn ọkunrin to jẹ agbagba ile lọ lati yanju ọrọ naa nitubi n nu bi eyi ti kii so eso rere.
"O soro ki ayipada waye lagbegbe yi lopin igba to ba se pe awọn ọkunrin naa lo n jọba lori idajọ''
Egodi Igwe tẹsiwaju pe "ki iyipada to le waye, awọn obinrin gbọdọ wa lara awọn ti yoo maa joko jiroro lori ọrọ ogun pinpin taa n sọ yi.''

Ki asa yi to le dopin, ayafi kawọn lọbalọba ilẹ Igbo pa ọkan pọ lati kasẹ rẹ nilẹ.
O seni laanu pe ọpọ wọn sọ pe asa yi kii se ohun to se yi pada.
Igwe Chiwendu Onuoha, oriade ilu Eke ni ipinlẹ Enugu loun ko ro pe asa yi n dẹyẹsi awọn obinrin rara.
lati ma se jogun lẹyin iku baba wọn.
"Awọn ọkunrin lopo to mu asa ati ise wa ro" lọrọ to n sọ.
O fikun pe awọn a maa pin ilẹ ajumọni ilu fawọn ọkunrin nikan.
''Awọn ọkunrin wọn yi lo n tọju ilu.Nigba ti ija ba bẹ silẹ, awọn ni wọn maa n kopa.Bi ede aiyede kankan to ni se pẹlu asa wa ba waye, awọn ọkunrin lo maa n da si ọrọ yi.''
Lakotan o ni : "Ninu asa wa, kii se idẹyẹsi, Asa awujọ wa ni, mi o ri nkankan to jọ mọ pe a n da ori apa kan si, Bakan la se da awọn ọkunrin ati obinrin''.

Bo tilẹ jẹ pe asa yi gbilẹ lawọn awujọ kọọkan, awọn miran ti wọgile. Igwe Godwin Ecko jẹ ọkan lara awọn oriade to ti wọgile asa yi ni ilu tiẹ tii se ilu Ihe to wa ni Enugugu yi kan naa.
"A ni igbagbọ pe bakan laa se sẹda ọkunrin ati obinrin.Ki eeyan wa sọ pe oun ko ni fun awọn obinrin lẹtọ wọn ko bojumu.''
Ọba yi sọ pe" Ni ilu temi, awọn obinrin a maa jẹ ogun koda wọn a maa jẹ ọgbọn pẹlu.A kii fayegba ki mọlẹbi gbẹsẹle ogun awọn obinrin ti wọn ko ba bimọ ọkunrin''
Sugbọn saaju ki o to di ọba lọdun 1993, ọrọ ko ri bẹ.Nigba to de ori oye lo ni boun yoo ti se se toun ni yẹn ti ọrọ yi si jẹ iyalẹnu fun ọpọ araalu.
''Awọn eeyan sọ pe wahala ni mo n wa pẹlu bi mo ti se n yi asa wa pada, sugbọn ko si ohun to tẹyin rẹ bọ''
'Mi o le maa ba awọn ọmọ iya mi lọkunrin fa wahala'.
Awọn ajafẹtọmoniyan sọ pe aijẹki obinrin jẹ ninu ogun jẹ ọna kan gbogi ti wọn fi n dẹyẹsi wọn to fi mọ ki wọn ni ki wọn fa ori opo, kikọla idi fun awọn obinrin ati aijẹki wọn bawọn nipin ninu ilẹ ilu.
Ile ati ilẹ jẹ nkan ọrọ ti wọn ko jẹ kawọn obinrin ni ipin ninu rẹ eyi to n ko ipalara ba wọn nipa ọrọ aje.
Yatọ si ofin, awọn onimọ gbagbọ pe awọn ọkunrin ni ipa ribiribi lati ko lati u ayipada ba asa yi.
Egodi Igwe sọ pe''pẹlu gbogbo nkan to n waye lori aijogun awọn ọmọ obinrin, mo lerope o yẹ kawọn ọkunrin bẹrẹ si maa wa ọna ki awọn mọlẹbi wọn ma farakasa iru nkan bayi ti wọn ba ku tan''
O ni oun gbagbọ pe nibi ki awọn obi maa kọ akọsilẹ nipa ogun pinpin lọna abayọ wa.
Tabi ki awọn baba si maa fi to awọn mọlẹbi wọn leti bi wọn yoo ti se pin ogun wọn ti iku ba de.
Tọkantọkan ni Onyinye Igwe fi faramọ aba yi.
O ni oun ko binu sawọn ọmọ iya rẹ lọkunrin bẹẹ si ni oun ko lero lati pe wọn lẹjọ lori ọrọ ogun yi.
"Ti baba mi ba pin ogun rẹ kalẹ ni, nkan ki ba maa ri bayi''
"Mi o le maa ba awọn ọmọ iya mi ja nitori ogun, ẹjẹ mi si ni wọn n se''
- Ìpayà ní Kano lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ Àjọ NYSC kú lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn Coronavirus
- Ọlọ́pàá fòfin de lílo "siren" àti "tinted glass" lọ́nà àìtọ́
- Àwọn dókítà Ondo bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ
- Ilẹ̀ Amerika ń wá olùkọ́ èdè Yorùbá, wo bí o ti lè forúkọ sílẹ̀ níbí
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun
















