Kano NYSC Orientation; Ìpayà ní Kano lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ Àjọ NYSC kú lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, NYSC/TWITTER
Inu ifoya ati ipaya ni awọn oṣiṣẹ Ajọ Agunbanirọ lorilẹede Naijiria, NYSC wa lẹyin ti oṣiṣẹ fosanlẹ ku nitori aarun Coronavirus.
Ile Iroyin Punch fi lede pe laipẹ yii ni ọga lẹnu iṣẹ naa lọ si ipagọ NYSC ọun ni Kano, ko to di pe o bẹrẹ si ni ṣe aisan to si ku ni Ọjọ Iṣẹgun.
Lẹyin iku rẹ, awọn oṣiṣẹ ati agunbanirọ wa ninu ipaya.
Amọ Alukoro ikọ NYSC, Emeka Mgbemena ni lootọ ni arakunrin naa ti papoda, amọ kii se ninu ipagọ Ajọ NYSC.
O ni arakunrin naa lọ ṣoju ọga agba ajọ NYSC ni ipinlẹ Kano ni, ati wi pe ita ipagọ nibi ti arakunrin naa ti n gba itọju lo dakẹ si.
Ni Oṣu Kẹfa, ọdun to kọja ni Ajọ Economic Sustainability Commitee rọ ijọba apapọ pe ki wọn gbegile ipagọ Ajọ NYSC fun ọdun meji nitori arun Coronavirus.
Amọ, o ṣeni laanu pe ijọba ko tilẹ ko ibi ara si ọrọ ti wọn sọ oun, ti wọn si tẹsiwaju lati ṣi awọn ojuko ipagọ Ajọ NYSC.
Lati Osu Kini, ọdun 2021 bayii, ọpọlọpọ agunbanirọ ni wọn ti ni aarun Coronavirus, ti agunbanirọ mẹtala si lugbadi aarun naa i Cross Rivers.
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Ilẹ̀ Amerika ń wá olùkọ́ èdè Yorùbá, wo bí o ti lè forúkọ sílẹ̀ níbí
- Ènìyàn 1634 tún ti lùgbàdì ààrùn Covid-19 ní Nàijíríà
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
Ni Ọjọ Iṣẹgun nikan ṣoṣo, Ajọ to n gbogun ti aarun lorile-ede Naijiria, NCDC ti ni pe eeyan 1634 tuntun mii lo tun lugbadi aarun yii.
Nigba ti apapọ eeyan 133,552 ni akọsilẹ Ajọ NCDC fihan pe wọn ti larun covid-19 ni Naijiria.





















