Goodluck Jonathan: Irọ́ ní o, a kò buwọ́lu Goodluck Jonathan fún ipò ààrẹ 2023

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Goodluck Jonathan

Ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria ti ni ko si otitọ ninu ọrọ pe awọn fẹ fi orukọ aarẹ orilẹede tẹlẹri, Goodluck Jonathan lede gẹgẹ bi olusije sipo aarẹ ni ọdun 2023.

Ọsẹ to kọja ni awọn gomina kan labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni ariwa orilẹede Naijiria sọ wi pe Jonathan laṣẹ lati di dije dupo lẹẹkẹji, nitori igba kan lo tii ṣe ipo aarẹ ni Naijiria.

Amọ, ẹgbẹ oṣẹlu naa ni awọn kan ni wọn gbe iroyin ẹlẹjẹ naa.

Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ni ko si ohun to kan Jonathan ninu ọrọ to wa nilẹ yii, amọ o ṣeeṣe ki awọn to n gbe iroyin naa ni ibẹru ni ọkan wọn nipa idibo gbogboogbo ti ọdun 2023.

Buni ni biotilẹjẹpẹ awọn lo kii fun ayajọ ọjọ ibi rẹ, ko niiṣe pẹlu ọrọ oṣelu, awọn lo ṣe abẹwo si gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri ni.

'' Se Goodluck Jonathan ni oun fẹ ṣe aarẹ ni ọdun 2023 ni, awọn eniyan kan n gbe irọ lasan.''

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Bakan naa ni akọwe ẹgbẹ oṣelu APC ti fi atẹjade sita ni ọjọ Ẹti wi pe ko si otitọ ninu iroyin to n ja ranyinranyin naa.

Nibayii, awọn eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹrẹ si ni sa ipa wọn saaju idibo gbogboogbo lorilẹede Naijiria ti yoo waye ni ọdun mẹta si isinyii.

Awọn onimọ sọ wi pe ariyanriyan yoo pọ ni ẹgbẹ oṣelu APC lori ẹni ti yoo dije dupo aarẹ ni ẹgbẹ naa ti asiko ba de.

Awọn eniyan ni ero wi pe ki aarẹ Buhari gbe ijọba wa si guusu orilẹede Naijiria lẹyin ti oun ti ṣe aarẹ to wa lati ariwa orilẹede Naijiria fun ọdun mẹjọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Amọ, awọn miran ni ẹgbẹ oṣelu APC ko gba ọrọ yii gẹgẹ bi eleyii to dara, nitori wọn gbagbọ wi pe ẹni to ba kunjuwọn ni ko dije dupo aarẹ lai si ẹlẹyamẹya ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ