Abduction in Ngeria: Ajínigbé ń bèèrè àpò ìrẹsì, búrẹ́dì àti páálí sùgá fún ìtúsílẹ̀ ẹni tí wọn jí gbé

Oríṣun àwòrán, NigerianArmyHQ
Iwadii kan ti fi han pe, kii ṣe awọn eeyan ilu nikan ni eto ọrọ aje Naijiria to mẹhẹ n pa lara bayii, ṣugbọn ọrọ naa ti kan awọn ọdaran ninu igbo pẹlu.
Ni bayii, awọn ajinigbe atawọn janduku ti n beere fun awọn ounjẹ bii apo irẹsi, pali noodles, burẹdi atawọn ounjẹ miran, gẹgẹ bi owo itusilẹ lọwọ ẹbi awọn ti wọn n ji gbe.
Iwadii kan sọ pe iwa ọdaran to n peleke si ko ṣẹyin eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ni Naijiria nitori bii ounjẹ ṣe wọn gogo to si tun nira fun ọpọ ọmọ Naijiria lati gbe igbe aye irọrun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bolanle Ninalowo sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tó fi kúrò nínú Islam di Krístẹ́nì
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń ta Nàíjíríà lọ́pọ́, ojú yín ti ja lórí iléeṣẹ́ Twitter tó lọ Ghana - Lai Muhammed
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń fẹ́ Oduduwa Nation, ẹ yé tẹ òfin lójú, orílẹ̀èdè Nàíjíríà la ṣì wà - Olajide
- Èèyàn 10 kú, 400 dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n mu ẹlẹ́rindòdò
- Sheikh Muideen Bello, wáàsí rẹ̀, owó ló bá dé - PDP fèsì
- Buhari padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ìsinmi ráńpẹ́ ní London
Fun apẹẹrẹ, awọn to ji awọn eeyan kan gbe lagbegbe Kiyi ati Anguwar Hausawa niluu Abuja, sọ fun awọn ẹbi wọn pe ki wọn fi ounjẹ kun owo itusilẹ, ti wọn n gbe bọ lati doola ẹbi wọn.

Lara awọn nnkan ti wọn beere fun ni apo irẹsi, pali noodles, spaghetti ati maggi.
Ọkan lara awọn ẹbi awọn eeyan naa, ti wọn pe ni Joshua, sọ fun awọn akọroyin pe, wọn ko awọn ounjẹ ọhun pẹlu miliọnu kan abọ naira lọ fun awọn ajinigbe naa, ki wọn to tu ẹbi oun silẹ.
Iwadii tun fi han pe, awọn mọlẹbi awọn eeyan mẹjọ ti wọn ji gbe ni Kiyi pẹlu pasitọ ijọ RCCG, ra ounjẹ fun awọn to ji wọn gbe ki wọn to gba itusilẹ.
Joshua ṣalaye pe "awọn ẹbi miran naa ṣe ohun kan naa, ki wọn to tu awọn eeyan wọn silẹ."
"Ti ẹ ba ko owo nikan fun wọn lai fi ounjẹ si, wọn maa gba owo naa, ṣugbọn wọn ko ni tu awọn ẹbi yin ti wọn ji gbe silẹ titi ti ẹ o fi gbe ounjẹ fun wọn."
Lọdun to kọja, awọn ajinigbe kan lagbegbe Ushafa niluu Abuja, beere fun burẹdi ọgbọn, pali siga ogoji, atawọn nnkan miran, yatọ si owo itusilẹ ti wọn beere fun ṣaaju.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ lori awọn iṣẹlẹ ijinigbe naa, ti wọn si sọ pe ikuna ijọba lati pese fun awọn ọdọ lo jẹ ki ijinigbe di tọrọ fọn kalẹ.
Ijinigbe naa si ni wọn lo ti fa ọwọn gogo ounjẹ nitori ibẹru awọn agbẹ lati lọ oko wọn.
Olugbe ilu Kaduna kan nibi ti ijinigbe ti pọ, Ijanebu Odeh, sọ fun awọn akọroyin pe "awọn ajinigbe to n beere fun ounjẹ, ebi lo n pa wọn, wọn si ni lati bọ awọn ẹbi wọn."
"Ko ṣeeṣe fun ẹni to ni iṣẹ gidi lọwọ, tabi oniṣowo to rọwọ họri, lati maa ji eeyan gbe nitori wọn lagbara lati pese fun awọn ẹbi wọn."
- Ẹ gbà wá, ọ̀daràn darandaran tún ṣá àgbẹ̀ míì pa, ọ̀rọ̀ yìí yóò di wàhálà láìpẹ́ - Baálẹ̀ Àgbẹ̀ Tapa
- Ẹ wo ọ̀nà táwọn gómìnà Yorùbá yóò gbà láti bọ́ lọ́wọ́ ọ̀dá owó, bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń lọgun pé ńǹkan le
- Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tó bá fààyè gba ìpolongo Oduduwa Nation, a fà á lé DSS lọ́wọ́ ni - Ìjọba Osun
- Ẹ wo àwọn àdúgbò mẹ́wàá tó gbajúmọ̀ jùlọ ní ìlú Eko
- Àjọ̀dún òkú rèé níbi tí alààyè ti ń tọrọ owó, ọmọ àti ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ ẹ̀mí àìrí
O pari ọrọ rẹ pe ijọba ni lati wa ojutu si ọrọ awọn awọn ọdọ ti ko ni iṣẹ lọwọ ati iṣoro ijinigbe ki ọrọ naa to kọja oju ẹ.

Ọlọ́pàá yìnbọn lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nílùú Eko, wàhálà dé

Oríṣun àwòrán, @NigeriaPolice
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gba iṣẹ lọwọ oṣiṣẹ rẹ kan, Eze Aiwansoba, to wa ni Special Protection Unit, Base 16, ni Ikeja.
Isẹ bọ lọwọ ọlọpaa naa lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o yinbọn lu ọrẹbinrin rẹ, Joy Ndubueze pẹlu erongba lati gbẹmi rẹ.
Wọn tun sọ pe, afurasi naa yoo kawọ pọn rojọ niwaju adajọ lori iṣẹlẹ ọhun to waye lọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni opopona Salvation to wa ni Opebi, ni Ikeja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Arapaja jáwé olúborí nínú ìdìbò alága ẹgbẹ́ ìwọ òòrùn gúúsù
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ lágbo tíátà Yoruba, àgbà òṣèré míì tún jáde láyé
- Makinde fàgbà han Fayose, Arapaja fi ẹyin alátako janlẹ̀ láti dì alága PDP ní SW
- Ọmọ yẹrí ẹ, èpè ń bọ̀! Kí ló dé tí Foluke Daramola bu èpè jólẹ̀ lórí ayélujára?
- N kò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Boko Haram àti Al-Qaeda, ẹbu ìròyìn ló jáde síta - Mínísítà
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ nipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejobi fi ṣọwọ si BBC Yoruba lo ti kede bẹẹ.
Ṣaaju ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Hakeem Odumosu ti kọkọ paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ati pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ rẹ ti aje ọrọ ọhun ba si mọ afurasi naa lori.
Lẹyin ti wọn ja iwe lọ gbe le ẹ fun tan, ni wọn gbe lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ọdaran, CID, lọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun ti a wa yii.
Lẹyin naa ni wọn gbe ọ sile ẹjọ lati jẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, eyii ti wọn ni o lodi si ofin ipinlẹ Eko to rọ mọ ẹsun ipaniyan, abala 230, ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015.
Ni bayii, afurasi naa ti n kawọ pọn ro ẹjọ niwaju adajọ majistrati to wa ni Yaba niluu Eko, lori igbiyanju rẹ lati pe ọrẹbinrin rẹ ọhun, Joy Ndubueze.
Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti wa ṣeleri fun awọn eeyan ipinlẹ naa pe idajọ ododo ni yoo tẹle igbẹjọ ọhun.
Ati pe gbogbo ọlọpaa to ba tẹ ofin loju mọlẹ ko ni lọ lai jẹ iya to tọ labẹ ofin.

Ẹ rọra ṣe pẹ̀lú àwọn ará ìlú lásìkò yìí nítorí Covid 19- IGP Adamu Mohammed

Oríṣun àwòrán, @NigeriaPolice
Mohammed Adamu ni kawọn ọlọpaa bọwọ fẹtọ araalu pẹlu fifofin de ilana Covid-19.
Bi a ba ran ni ni isẹ ẹru, a gbọdo fi tọmọ jẹ ẹ lọrọ ti ọga ọlọpaa orile-ede Naijriia fi n fa awọn ọlọpaa leti lori fifofin de ilana Covid-19 tuntun ti aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu.
O fi ọrọ yi sita ninu atẹjade to kọ si awọn ọga ọlọpaa ẹkun mẹjeeje to wa ni Naijria.
IGP Mohammed ni ki wọn ma se tẹ ẹtọ araalu mọlẹ lasiko ti wọn baa n fi ofin ti aarẹ sẹsẹ gbe kalẹ yi lelẹ.
- Ìròyìn Yàjóyàjó -'Akirun ti Ìlú Ìkìrun,Oba Abdul-Rauf Olayiwola Adedeji II ti wàjà
- A kò kórira àwọn Fulani, àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ìnú wọ́n ni á kò fẹ́ - Ọba Akintunde ni ẹkùn Yewa, ìpínlẹ̀ Ogun
- Ọkùnrín márùn ún fojúbalé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ijà àti igbó fífà ní gbangba
- Awakọ̀ ojú pópó láti Eko san N26,000 nítorí ó lu òfin tó de ìtànkálẹ̀ ààrùn Covid-19 - FRSC
Labẹ ofin ti aarẹ gbe kalẹ lọtun yi, COVID-19 Health Protection Regulations 2021, awọn ọlọpaa lagbara lati fofin de titẹle ofin paapa lawọn aaye ijọsin ibisẹ, ile ẹkọ ile ifowopamọ,ibudo iwọkọ ile igbe ati awọn aaye miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko da wọn gbe agbara f'ọlọpaa lati ri wi pe awọn eeyan lo ibomu wọn nita ati pe wọn lẹtọ lati fofin de iye eeyan to ba wa lakojọ.
Awọn koko miran to wa ninu ofin Coronavirus Disease (COVID-19) Health Protection Regulations 2021:
*Ni gbogbo apejọ, ijinasiraẹni iwọn mita meji gbọdọ wa.
*Awọn to ba pejọ ko gbọdọ ju aadọta lọ ayafi aaye ijọsin ti wọn ko gbọdọ ju idaji dede iye awọn to ba yẹ ki aaye naa gba lẹkunrẹrẹ.
*Wọn ko ni faye gba ki eeyan kankan wọ ile itaja, ọja, ile igbafẹ, ibudo iwọkọ aaye igbaradi, ile ounjẹ tabi awọn aaye mii lai se pe iru ẹni bẹ lo ibomu to bo imu ati ẹnu rẹ.
*Awọn eeyan gbọdọ fọwọ wọn pẹlu sanitaisa ti ajọ NAFDAC fontẹ jan tabi omi ati ọsẹ.
*Wọn gbọdọ se ayẹwo ara awọn eeyan wo lati mọ ẹni tara rẹ ba gbona kọja bo se yẹ.Bo baa ri bẹ pe ara eeyan gbona kọja 38 degrees Celsius wọn lasẹ lati da pada ko si lọ gba itọju ni kiakia.
*Gbogbo ileesẹ gbọdo pese eto imọtoto bi ọsẹ, omi ifọwọ, ike ati sanitaisa fẹnikẹni to ba fẹ wa bawọn dowo pọ lopin igba ti isẹ baa n lọ lọwọ.

















