Buhari: Buhari padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ìsinmi ráńpẹ́ ní London

buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ Muhammadu Buhari ti balẹ bagẹ sí Naijiria lẹyin isinmi ranpẹ niluu London nilẹ Gẹẹsi.

Ọgbọnjọ oṣu kẹta ni Buhari rinrin ajọ lọ si ilẹ Gẹẹsi fun ayẹwo ara rẹ.

Olori awon oṣiṣẹ ni ileeṣẹ aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari lo ṣaaju awọn oṣiṣẹ ijọba mii lati ki Aarẹ Buhari kaabọ si Naijiria ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe niluu Abuja.

Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ Buhari n gbera lọ si ilu London fun isinmi ni awọn dokita gunle iyanṣẹlodi kaakiri oriilẹede Naijiria lori ẹsun aisan owo osu wọn ati ajẹmọnu wọn.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo si fariga pe kii ṣe asiko yii lo yẹ ki aarẹ Buhari tẹ ọkọ leti lọ si oke okun.

Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Igba kẹfa ni yii ti aarẹ Buhari ti n lọ si ilu London fun isinmi ilera ara rẹ lati igba to ti di aarẹ Naijiria ni ọdun 2015.