Fulani Herdsmen Crisis: Gani Adams ní Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ngozi Onadeko gbọ́dọ̀ fí ipò sílẹ̀

Darandaran

Oríṣun àwòrán, Google

Aarẹ ọnakakanfọ ilẹ Yoruba, Gani Adams ti ni ki wọn gbe Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko kuro nitori apa rẹ ko ka iṣekupani to n waye ni ipinlẹ Oyo lojoojumọ.

Gani Adams sọ ọrọ yii lasiko ti awọn agbẹ ni ilu Ibarapa wa ṣe ipade pẹlu rẹ ni ile re ni ilu Eko.

Adams kesi Adele Ọga Ọlọpaa, Usman Alkali Baba lati ri pe wọn gbe e kuro ni ipinlẹ Oyo ni waranṣesa nitori eto aabo to dẹnukọlẹ nipinlẹ naa.

Eyi ko sẹyin iroyin bii awọn afurasi Fulani darandaran ṣe n ji awọn agbẹ gbe, ti wọn si n pa awọn miran ninu wọn.

Laipẹ yii ni Baalẹ Agbẹ nilu Igangan, Oloye Oyedepo Oludele ni ko si aabo kankan fun ẹnikẹni ni Ibarapa bi o tilẹ jẹ pe awọn agbofinro n gbiyanju lati se iwọnba ti agbara wọn ka.

Awọn agbẹ naa ni awọn Fulani darandaran ti gba gbogbo agbegbe naa tan, ti wọn si n hu iwa ọdaran nibẹ.

Nibi ipade naa ni Aarẹ ọna kakanfọ ti ni ko si ohun to yipada lati igba ti kọmisọnna ọlọpaa naa ti wa nibẹ.

''Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti fi panpẹ mu Wakili Iskilu ti wọn fẹsun kan pe oun ni olori awọn ajinigbe nibẹ, amọ ijinigbe si n peleke si ni.''

''Nibayii awọn agbẹ ni ilu Ibarapa ko le e lọ si oko wọn mọ nitori awọn ọdaran darandaran to ti gba ibẹ mọ wọn lọwọ''

''Bẹẹ si ni atijẹ ati atimu ti di iṣoro fun awọn eniyan ilu Ibarapa nitori iṣẹ oko ni gbogbo wọn n gbojule, amọ ibẹru iṣekupani ti mu ki onikaluku joko si ile wọn''

Aarẹ ọnakakanfọ nilẹ Yoruba, Gani Adams wa rọ ọga ọlọpaa naa lati saanu awọn eniyan ilu Ibarapa, ki awọn eniyan to bẹrẹ si ni ṣe eto aabo fun ara wọn.

Ẹ gbà wá, ọ̀daràn darandaran tún ṣá àgbẹ̀ míì pa, ọ̀rọ̀ yìí yóò di wàhálà láìpẹ́ - Baálẹ̀ Àgbẹ̀ Tapa

Fulaniu darandaran

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọdaran to n paniyan tun ti soro lẹẹkan si nilu Ayete, ti wọn si ti da ẹmi kunrin agbẹ miran legbodo.

Arakunrin agbẹ naa, tii se ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, ni wọn ba oku rẹ ni orita mẹta agbegbe Igangan nibi ti awọn afurasi darandaran ti gba ẹmi rẹ.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Baalẹ Agbẹ nilu Igangan, Oloye Oyedepo Oludele salaye bi agbẹ naa ṣe ku ati ohun gan an to ṣẹlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oloye Oludele ni aago marun irole Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye, ti arakunrin Mufutau Babarinde to jẹ agbẹ n ti oko rẹ bọ, nibi to ti lọ ka elubọ ni ilu kereje ti ko jina si Ayete.

O ni n se ni Mufutau lo ge amala fun awọn oṣiṣẹ ni o ba ri iku he lọwọ awọn afurasi darandaran.

Àkọlé fídíò, Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

''O ku diẹ ko de abule rẹ ni Mufutau pade awọn darandaran ni orita mẹta, ti wọn si ṣu bo o ni ori ọkada to wa.''

''Gbogbo igbiyanju rẹ lati jajabọ lo ja si pabo nitori awọn Fulani darandaran naa to mẹjọ ti wọn bo o lori ọkada to wa''

''Nigba to n tiraka lati jajabọ lori ọkada, ni wọn ge ọwọ rẹ to fi di ọkada mu lati jajabọ.''

''Lẹyin naa wọn ge ẹsẹ rẹ to fi di ''ijanu ọkada rẹ mu'', wọn si ge e ni ẹgbẹẹ̀gbẹ ti ẹjẹ ti bọ ọ mọlẹ''

''Eleyii si mu ki o ku si inu agbara ẹjẹ rẹ nitori ko le e dide mọ nilẹ nbẹ''

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu Gani Adams lori ọrọ Sunday Igboho

Baalẹ Agbẹ ni ilu Igangan, Oloyẹ Oyedepo Oludele fikun pe, "nigba ti awọn mọlẹbi rẹ reti rẹ titi ti wọn ko ri, ni wọn bẹrẹ si ni tọ ipaṣẹ rẹ titi ti wọn fi de orita nibi to ti ku si."

Oloye Oludele ni aago kan oru ni wọn gbe oku rẹ de agọ ọlọpaa, amọ nitori ẹlẹsin Musulumi ni, wọn tete sin lẹyin ti wọn sọ gbogbo bi o ṣe ṣẹlẹ tan fun awọn ọlọpaa.

Lori ibeere wipe ki lo tun fa iṣekupani to tun bẹrẹ si ni ṣẹṣẹ waye ọhun, Oloye Oludele ni awn afurasi darandaran naa n gbẹsan ni.

"Bi o tilẹ jepe awọn ko le e sọ wi pe ko si ija laarin awọn Fulani darandaran ati agbẹ ni agbegbe naa, amọ gbogbo aye lo mọ pe ko si ibaṣepọ to gun rege laarin awọn mejeeji.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

''Kedere ni awọn Fulani darandaran sọ wi pe awọn yoo gba ẹsan lori bi wọn ṣe le awọn kuro ni igboro lọ si inu igbo pẹlu awọn maluu wọn''

''Igba akọkọ kọ niyii ti wọn yoo pa agbẹ ni agbegbe naa, nitori ọkan lara awọn agbẹ wa ni ileewosan lọwọ to n gba itọju lẹyin ti wọn kọlu ninu ọkọ rẹ.

Awọn Fulani naa ti ko maalu wọn lọ si ọna jinjin, ti wọn si sọ si mi leti pe awọn yoo lọ lootọ amọ awọn yoo gbẹsan. Gbogbo Yoruba tawọn ba ri, awn yoo maa pa ni, eti mi bayii ni wọn ti sọ."

Nitori iṣẹ agbẹ ni iṣẹ wa, awọn Fulani darandaran yii si ti kuro ni inu ilu lọ si awọn abẹ igbo wọnyii, ti wọn si n ṣọṣẹ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Igboho Ultimatum to Fulani: Ẹni bá mọ Sunday Igboho kó bá wa bẹ̀ẹ́ o,

"Igbo pọ lọdọ wa, awọn Fulani yii si pọ, ti wọn sa wọ inu igbo lọ, ẹnikẹni to ba si ni oun yoo wa wọn wọ inu igbo lọ, yoo padanu ẹmi rẹ ni."

Nigba to n dahun lori ọna tawọn ara agbegbe naa yoo gba daabo bo ara wọn, Baale Agbẹ ni ko si aabo kankan fun ẹnikẹni bi o tilẹ jẹ pe awọn agbofinro n gbiyanju lati se iwọn ba ti agbara wọn ka.

"Ko si aabo lọwọ ẹnikẹni, amọ nigba to ba ya, ọrọ yii yoo di wahala ati rogbodiyan ti yoo lagbara nitori a ko lee maa woran, ki wọn maa pa wa bayii."

Àkọlé fídíò, Cattle Ranching: Ẹ wo Fulani darandaran to tako àṣà dída màálù kiri lójú pópó

Ọpọlọpọ igba ni ija laarin awọn Fulani darandaran ati agbẹ ti da rogbodiyan silẹ ni ipinlẹ Oyo, ti awọn agbẹ si n fi ẹsun kan awọn Fulani darandaran wipe wọn n pa awọn agbe ti wọn si n jiwọn gbe.