Buhari Trip to London: Ǹkan mẹ́rin tó ṣẹ̀lẹ̀ nígbà tí Buhari rín ìrìnàjò lọ London

Oríṣun àwòrán, Buhari Sallau
Ní ọ̀gbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹta ọdún 2021 ni ilé ṣẹ́ ààrẹ kéde pé ààrẹ Muhammadu Buhari yóò rìn ìrìnàjò lọ sókè òkùn láti lọ sínmi.
Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló n fàpa jánú pé láti ìgbà tí ààrẹ Muhammadu Buhari ti gori oye, lo ti n rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèrè láti lọ gba ìtọ́jú.
Amọ lasiko ti aarẹ Buhari fi lọ gba itọju nilu London naa, ọpọ isẹlẹ lo waye ni Naijiria, marun ninu wọn ree:
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bolanle Ninalowo sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tó fi kúrò nínú Islam di Krístẹ́nì
- Èèmọ̀ wọ̀lú, Ajínigbé fo ògiri wọnú ààfin, wọ́n jí oríadé gbé l'Ekiti
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Ebi ń pa ajínigbé nínú igbó, wọn ń bèèrè èròjà oúnjẹ́ pẹ̀lú owó ìdáǹdè
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń ta Nàíjíríà lọ́pọ́, ojú yín ti ja lórí iléeṣẹ́ Twitter tó lọ Ghana - Lai Muhammed
- Ẹ̀yin tẹ̀ ń fẹ́ Oduduwa Nation, ẹ yé tẹ òfin lójú, orílẹ̀èdè Nàíjíríà la ṣì wà - Olajide
- Èèyàn 10 kú, 400 dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n mu ẹlẹ́rindòdò
- Sheikh Muideen Bello, wáàsí rẹ̀, owó ló bá dé - PDP fèsì
- Buhari padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ìsinmi ráńpẹ́ ní London
Ǹkan márùn-ùn tó ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà lásìkò tí Buhari kò sí nílé
Ẹgbẹ dokita onisegun oyinbo gunle iyansẹlodi

Oríṣun àwòrán, NMA
Ní kété tí àarẹ Buhari rìnrìnàjò ni àwọn dókítà ni Nàìjíríà gùnlé ìyànṣẹ́lódì nítorí ìjọba kọ̀ láti san owó oṣù wọn.
Àwọn ǹkan míràn tí wọ́n tún pè fún ni pé kí ìjọba san gbogbo owó tí wọ́n ti jẹ àwọn sẹ́yìn.
Èyí nìkàn kọ́, àwọn owó ààbò nítorí ewu tó bá de bá wọn lẹ́nu iṣẹ́ ni wọn tun n beere fun pẹlu.
Ẹgbẹ́ awọn dókítà náà sàlàyé pé, àwọn tun fẹ ki ijọba san awọn ajẹsilẹ owó àjẹmọ́nú fàwọn dókítà tó ṣiṣẹ́ lásìkò igbele arun Convid-19, pàápàá jùlọ, àwọn ilé ìwòsàn tí ìjọba ìpínlẹ̀.
Agbebọn kọlu ileesẹ ọlọpaa ati ọgba ẹwọn ni Imo, ẹlẹwọn bii ẹgbẹrun meji sa lọ

Ní ọjọ́ keje oṣù kẹrin ọdún 2021, ọjọ́ kẹjọ tí ààrẹ Buhari ti wà ni ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, ni àwọn agbébọ̀n lọ ṣe ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ni Imo.
Ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọ̀daràn toto ojilelẹgbẹsan ati mẹrin (1,844) ló sá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Àwọn tó ṣe ìkọlu sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n yìí bákan náà ló tún ṣe ìkọlu sí àgọ́ ọlọ́pàá, lẹ́yin èyí ni gómìnà fi ìpè kóníléògbélé síta láti aago mẹ́wàá alẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí.
Ààrẹ Muhammadu Buhari fi ohùn ránṣẹ́ sílé pé kí gbogbo àwọn ẹ̀sọ́ elétò ààbò ní ìpínlẹ̀ Imo àti gbogbo ẹ̀sọ elétò ààbò ni ẹkùn náà lépa àwọn ọdaràn tó kọlu ọgbà ẹwọ̀n àti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ọhun.
Baba Alkali di ọga agba ọlọpaa tuntun

Oríṣun àwòrán, PoliceNG
Lásìkò tí ààrẹ Buhari rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì bákan náà, ló yan ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tuntun, Baba Alkali, tó sí gbé iṣẹ́ túntun le lọ́wọ́ láti fójú àwọn ọdaran hàn.
Èyí tún mú kí àwọn ènìyàn máa kọ hàà nítórí sáájú ni ààrẹ Buhari ti fí oṣù mẹ́tà kún àsìkò ti ọga ọlọpa to wa nipo nigba naa, Adamu.
Amọ nigba ti Buhari de ilu oyinbo lo tun pasẹ pe ki wọn yan ẹlomiran rọpo Adamu lẹsẹsẹkẹ.
Ìyàlẹ́nú ló jẹ́ pé, ibi àbẹ̀wò iṣẹ̀lẹ̀ ikọ̀lù sí ọgbà ẹ̀wọn àti àgọ ọlọ́pàá ni Adamu wa, nígbà tí ààrẹ Muhammadu Buhari yọ níṣẹ́.
Awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria se agbekalẹ ikọ alaabo Ebube Agu

Lẹ́yìn tí ààrẹ Buhari lọ ìrìn àjò ni àwọn gómìnà ẹkùn South-East ṣe àgbékalẹ̀ Ebube Agu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sọ alaabò fun ẹkùn wọ́n
Àwọn gómiǹà náà tó péjọ láti ṣe ifilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ náà ni Gómínà ti Abia, Okezuo Ikpeazu ati ti Anambra, Willie Obiano.
Awọn gomina yoku ni ti Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi; Ebonyi, Dave Umahi àti Hope Uzodimma tó gbàlejò wọ́n ni Imo.

















