Odeda Oko Kidnap: Ìyá ọmọ tó sọnù ní ajínigbé ni òun kò gbọdọ̀ sọ iyé owó ìtúsílẹ̀ tí wọn gbà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọ́n ti ri ọmọkùnrin, ẹni ọdún mẹtàlá ti ìròyìn rẹ jáde pé àwọn ajínigbé ji lọ́jọ́ Sátide, lásìkò tí òun àti ìyá rẹ̀ fẹ́ wọle ní ǹkan bi aago mẹ́sàn alẹ́ lagbègbè Obada ni ìpínlẹ̀ Ogun.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ̀nu wò ti BBC ṣe pẹ̀lú ẹbi ọmọde yìí, iya rẹ́ ta fi orukọ bo ni asiri sàlàyé pé, gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí àwọn bẹ̀ àwọn ajínigbé láti gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta Náírà, pàbó ló já sí.
Ọkan nínú àwọn ẹbi ọmọ náà ṣàlàyé pé, gbogbo ọ̀nà ni àwọn ti wá owó jáde láti rí ṣàjọ, ti àwọn ajínígbé náà sì kìlọ pé, tí owó òn kò bá pé, àwọn yóò gba ẹmi ọmọ wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀ẹ̀mẹrin ni ọ̀dá owó já mi kulẹ̀ lásìkò tí mo fẹ́ wọ Fáṣítì - Biola Adebayo
- Gani Adams yarí pé èdè Yorùbá gbọdọ̀ di ọ̀rànyàn nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀
- Báwo ní Nàíjíríà ṣe ná $30m fún ààbò akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yin ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ Chibok?
- Òjòóró ló wáyé lásìkò ìbò PDP l‘Osogbo - Fayose
- ''Ẹ gbà mí o, ọkọ mí ti lé mi nílé torí mo ya ‘tatoo’ Tinubu sára''
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
Ìyá ọmọ náà pẹ̀lú sàlàyé pé, nínú àlàyé tí ọmọ òun ṣe nígbà tó délé, ló tí sọ fún àwọn pé, àwọn ajinigbé náà fi ye òun pé, tí àwọn obi òun bá kọ làti gbé owó wá, àwọn yóò máa mú òun lọ, tí àwọn yóò sì kọ ọ bi yóò se máa yìnbọn.
Ó ní ọmọ náà ṣàlàyé pé, wọ́n fún òun lónjẹ lásìkò tó tọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kọ̀ láti jẹ òunjẹ náà, sùgbọ́n gbogbo ǹnkan tí ó n ṣẹlẹ nínú ilé ni òun ń rí ni ibi ti òun wà lọ́dọ̀ àwọn ajínigbe naa.
Àwọn ẹbi ọmọ náà ni ìmọ̀ràn ọlọ́pàá lásìkò tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn kò gbọ̀dọ̀ san owó kankan, pé wọ́n yóò gbé ọmọ náà sílẹ̀.
Sùgbọ́n o ni nígbà ti àwọn ri bi ọ̀rọ̀ náà ṣe n lọ, ni àwọn fí lọ wa owó naa.
"Wọ́n ni àwọn ri gbogbo bi a ṣe n bá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ àti iroyin gbogbo, wipe kí a múra sí bóyá a kò fẹ́ rí ọmọ wa mọ́, ìgbà tó dí àná ni wọ́n pada fí ọmọ naa sílẹ̀ pẹlú owó ìtúsílẹ̀".
Wọ́n túbọ̀ kìlọ̀ fún wá pé a kò gbọdọ̀ sọ iye owó ìtúsílẹ̀ tí a san."
Ìyá ọmọ náà ni àti sọ́ọ̀bù ni àwọn ti dé lálẹ́ ọjọ́ Sátide, ti òun sì ni kí ọmọ náà bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ láti lọ ṣí géètì fún òun láti wọlé.
Amọ o ni àwọn agbébọ̀n náà, ti wọn sin awọn dele ti mú ọmọ, ọjọ́ kejì ni wọ́n tó pé láti bèèrè fún owó ìtúsílẹ̀ tii se àádọ́ta míliọ̀nù Nàírà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀, wọ́n já owó naa wá sílẹ̀.
Títí dí àsìkò yìí, kò sí ẹni ti a funra sí pé ó le ṣe irú ǹnkan náà, nítòrí míníra àti omi tutu ni mó n tà, tẹ̀kún-tẹkun ni mo fi ń bẹ̀ wọ́n sùgbọ́n wọn kò gbọ́ ẹbẹ, a fi ìgbà tí a san owó.
Ọmọ náà sọ pé méjì nínú àwọn ajinigbe naa ló gbọ́ èdè Yorùbá sùgbọ́n Fulani ni wọ́n, àti pé, gbogbo àwọn tó n wá sí ilé ni òun ń ri lọ́dọ̀ wọ́n lọ́hun, sùgbọ́n òun kò lè sọ̀rọ̀.
"Ọmọ náà ni àsìkò tí àwọ́n wà nínú igbó, kí màmá òun tó gbé owó de ni àwọn ajínígbén yìí ti ṣètò ìbn wọ́n kálẹ̀, tí àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú sì jẹ́rìí si pé, ìbọ̀n tó lágbaára ló wà lọ́wọ́ àwọn ọ̀daran náà.
Lẹ́yìn ò rẹ̀yin tí a gbé owó sílẹ̀ ni wọ́n fi ọmọ náà sílẹ̀.



















