Kidnapping: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú

Àkọlé fídíò, Ijinigbe: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú

Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria lo ti ń kan sáárá sí ẹ̀ka ilééṣẹ́ ọlọpaa to n koju ijinigbe ni Naijiria (IRT) ati oludari rẹ Abba Kyari.

Wọn n gboriyin fun wọn nitori iṣe ribiribi wọn, sugbọn wọn ko mọ iru ewu ti wọn n doju kọ lojoojumọ.

Ninu iwadii yii, ikọ BBC Africa Eye tẹle ikọ naa wọnu igbo lati ri bi ogun ti wọn n gbe ti ijinigbe naa ṣe ri.

Abba Kyari, oludari IRT

Oríṣun àwòrán, Olakunle Arthur Falayi

Awọn iròyìn mìíran tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Awọn agbofinro gan ni o ṣeni laanu pe awọn ko ni irufẹ ohun eelo ija ti awọn ajinigbe n lo ni Naijiria.

Eka Intelligence Response Team to n risi ọrọ ijinigbe ni Naijiria ti ṣe awọn aritọkasi aṣeyọri kọọkan lati doola awọn ti wọn jigbe.

Ọpọ lo san ọpọlọpọ miliọnu Naira lati fi ri ẹbi wọn gba pada ṣugbọn to tun ja si pabo.

Ninu iwadii BBC Africa Eye ni a ti rii pe ọpọ n fẹsun kan awọn oṣiṣẹ eleto aabo IRT pe wọn n fiya jẹ awọn eniyan lọna aitọ.

Nigba ti BBC kan si oludari IRT, Abba Kyari, o ni irọ ni gbogbo ẹsun na a.

Abba Kyari ni ko si ẹni to maa n fẹ ki ọwọja ofin gba oun mu pẹlu ijiya to tọ ni ọrọ ẹsun naa.

Kyari ṣalaye fun BBC pe iwadii miran maa n gba to oṣu mẹta si mẹfa ki ọwọ IRT to tẹ awọn ọdaran naa.